2 Kronieken 22 – HTB & YCB

Het Boek

2 Kronieken 22:1-12

Ahazia, koning van Juda

1De inwoners van Jeruzalem kozen toen Ahazia, zijn jongste zoon, als nieuwe koning. Dat kon ook nauwelijks anders, want zijn oudere broers waren door de plunderende Arabieren gedood. 2Ahazia was tweeëntwintig jaar toen hij de troon besteeg en regeerde één jaar vanuit Jeruzalem. Zijn moeder heette Athalia en was een kleindochter van Omri. 3Ook hij bewandelde de goddeloze wegen van Achab, want zijn moeder zette hem aan tot slechte daden. 4Hij was net zo goddeloos als Achab, want na de dood van zijn vader liet hij zich leiden door Achabs familie en die mensen leidden hem naar de ondergang. 5Ahazia volgde hun goddeloze advies op en sloot een bondgenootschap met koning Joram van Israël, een zoon van Achab. Joram was op dat moment in oorlog met koning Hazaël van Syrië. De strijd vond plaats bij Ramot in Gilead en Ahazia leidde zijn leger daar naartoe om deel te nemen aan de strijd. Koning Joram van Israël raakte gewond 6en keerde terug naar Jizreël om te genezen. Daarop ging Ahazia bij hem op ziekenbezoek. 7Door dit bezoek bracht God echter Ahaziaʼs ondergang nabij. Tijdens het bezoek ging Ahazia met Joram naar buiten om Jehu, de zoon van Nimsi, te ontmoeten. Deze Jehu was door de Here aangewezen om een einde te maken aan de familie van Achab. 8Terwijl Jehu de familieleden en vrienden van Achab opspoorde en doodde, ontmoette hij de neven van koning Ahazia en de leiders van Juda en doodde ook hen. 9Daarna gingen de mannen van Jehu op zoek naar Ahazia en vonden hem in de stad Samaria, waar hij zich had verborgen. Zij brachten hem naar Jehu, die hem doodde. Desondanks kreeg Ahazia een normale begrafenis, want hij was tenslotte een kleinzoon van koning Josafat, een man die de Here met toewijding had gediend. Niemand van Ahaziaʼs familie was in staat om het koningschap over te nemen.

10Toen Ahaziaʼs moeder Athalia hoorde dat haar zoon dood was, liet zij alle zonen van het koningshuis van Juda doden. 11Maar Josabath, een dochter van koning Joram en dus een zuster van Ahazia, haalde Ahaziaʼs zoon Joas weg bij de zonen die zouden worden gedood en verstopte hem met een verzorgster in een beddenkamer. Deze Josabath was de vrouw van de priester Jojada. Zo kon Athalia de kleine Joas niet doden. 12Zes jaar lang bleef Joas in de tempel verborgen, terwijl Athalia als koningin regeerde.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 22:1-12

Ahasiah ọba Juda

122.1-6: 2Ọb 8.24-29.Àwọn ènìyàn Jerusalẹmu mú Ahasiah, ọmọ Jehoramu tí ó kéré jùlọ, jẹ ọba ní ipò rẹ̀, láti ìgbà tí àwọn onísùnmọ̀mí, tí ó wá pẹ̀lú àwọn ará Arabia sínú ibùdó, tí wọn sì ti pa àwọn ọmọkùnrin àgbà. Bẹ́ẹ̀ ni Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba.

2Ahasiah jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún kan. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Ataliah, Ọmọ ọmọbìnrin Omri.

3Ó mú ìrìn ní ọ̀nà ilé Ahabu. Nítorí tí ìyá rẹ̀ kì í láyà nínú ṣíṣe búburú. 4Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe, Nítorí lẹ́yìn ikú baba a rẹ̀, wọ́n di olùgbani nímọ̀ràn rẹ̀ sí ṣíṣe rẹ̀. 5Ó tẹ̀lé ìgbìmọ̀ wọn nígbà tí ó lọ pẹ̀lú Joramu ọmọ Ahabu ọba Israẹli láti gbógun ti Hasaeli ọba Aramu ní Ramoti Gileadi. Àwọn ará Aramu ṣá Joramu ní ọgbẹ́; 6Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí Jesreeli láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí wọ́n ti dá sí i lára ní Rama ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Hasaeli ọba Siria.

Nígbà náà, Ahasiah, ọmọ Jehoramu ọba Juda lọ sí Jesreeli láti lọ rí Joramu ọmọ Ahabu nítorí a ti ṣá a lọ́gbẹ́.

722.7-9: 2Ọb 9.1–10.36.Ní gbogbo ìgbà ìbẹ̀wò Ahasiah sí Joramu, Ọlọ́run mú ìṣubú Ahasiah wá. Nígbà tí Ahasiah dé, ó jáde lọ pẹ̀lú Jehoramu láti lọ bá Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí Olúwa ti fi ààmì òróró yàn láti pa ìdílé Ahabu run. 8Nígbà tí Jehu ń ṣe ìdájọ́ lórí ilé Ahabu, ó rí àwọn ọmọbìnrin ọba ti Juda àti àwọn ọmọkùnrin ìbátan Ahasi, tí ó ń tọ́jú Ahasiah, ó sì pa wọ́n. 9Ó lọ láti wá Ahasiah, àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. Àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣẹ́gun rẹ̀ nígbà tí ó sápamọ́ ní Samaria. A gbé e wá sí ọ̀dọ̀ Jehu, a sì pa á. Wọ́n sin ín nítorí wọ́n wí pé “Ọmọkùnrin Jehoṣafati ni, ẹni tí ó wá Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan ní ilé Ahasiah tí ó lágbára láti gbé ìjọba náà dúró.

Ataliah àti Joaṣi

1022.10–23.21: 2Ọb 11.1-20.Nígbà tí Ataliah ìyá Ahasiah rí i wí pé ọmọkùnrin rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀síwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba ti ilẹ̀ Juda run. 11Ṣùgbọ́n Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu mú Joaṣi, ọmọkùnrin Ahasiah ó sì jí gbé lọ kúrò láàrín àwọn ọmọbìnrin ọba, àwọn tí ó kù díẹ̀ kí wọn pa. Wọn gbé òun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù. Nítorí Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu àti ìyàwó àlùfáà Jehoiada jẹ́ arábìnrin Ahasiah. Ó fi ọmọ naà pamọ́ kúrò fún Ataliah, kí ó má ba à pa á. 12Ó wà ní ìpamọ́ pẹ̀lú wọn ni ilé Ọlọ́run fún ọdún mẹ́fà nígbà tí Ataliah ṣàkóso ilẹ̀ náà.