Joel 3 – HOF & YCB

Hoffnung für Alle

Joel 3:1-5

Gott verheißt seinen Geist

1»Wenn dies geschehen ist, will ich, der Herr, alle Menschen mit meinem Geist erfüllen. Eure Söhne und Töchter werden aus göttlicher Eingebung reden, die alten Männer werden bedeutungsvolle Träume haben und die jungen Männer Visionen; 2ja sogar euren Sklaven und Sklavinnen will ich in jenen Tagen meinen Geist geben. 3Am Himmel und auf der Erde werdet ihr Wunderzeichen sehen: Blut, Feuer und dichten Rauch. 4Die Sonne wird sich verfinstern und der Mond blutrot scheinen, bevor der große und schreckliche Tag kommt, an dem ich Gericht halte. 5Wer dann meinen Namen anruft, wird gerettet werden!«

So erfüllt sich die Zusage des Herrn: »Auf dem Berg Zion in Jerusalem findet man Rettung!«3,5 Obadja 17 Alle, die der Herr auserwählt hat, werden mit dem Leben davonkommen.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Joẹli 3:1-21

A dá orílẹ̀-èdè lẹ́jọ́

1“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti ní àkókò náà,

nígbà tí èmi tún mú ìgbèkùn Juda àti Jerusalẹmu padà bọ̀.

2Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ

pẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí Àfonífojì Jehoṣafati.

Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi,

àti nítorí Israẹli ìní mi,

tí wọ́n fọ́nká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè,

wọ́n sì pín ilẹ̀ mi.

3Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi;

wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan,

wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún

ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu.

43.4-8: Isa 23; El 26.1–28.19; Am 1.9-10; Sk 9.3-4; El 28.20-26; Sk 9.2; Isa 14.29-31; Jr 47; El 25.15-17; Am 1.6-8; Sf 2.4-7; Sk 9.5-7.“Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tire àti Sidoni, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Filistia? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹ̀yin ṣe padà sórí ara yín. 5Nítorí tí ẹ̀yin tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere dáradára mi lọ sínú tẹmpili yín. 6Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn.

7“Kíyèsi í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín. 8Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Juda, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Sabeani, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ.

9Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí;

Ẹ dira ogun,

ẹ jí àwọn alágbára,

Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun,

103.10: Isa 2.4; Mt 4.3.Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà,

àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀.

Jẹ́ kí aláìlera wí pé,

“Ara mi le koko.”

11Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká,

kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri.

Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, Olúwa.

12“Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí Àfonífojì

Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí:

nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jókòó láti ṣe

ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri.

13Ẹ tẹ dòjé bọ̀ ọ́,

nítorí ìkórè pọ́n:

ẹ wá, ẹ sọ̀kalẹ̀;

nítorí ìfúntí kún, nítorí àwọn

ọpọ́n kún àkúnwọ́sílẹ̀

nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!”

14Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀

ní àfonífojì ìpinnu,

nítorí ọjọ́ Olúwa kù si dẹ̀dẹ̀

ní àfonífojì ìdájọ́.

15Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn,

àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́.

16Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá,

yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá;

àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì

Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀,

àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.

Ìbùkún fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run

17“Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín,

tí ń gbé Sioni òkè mímọ́ mi.

Ìgbà náà ni Jerusalẹmu yóò jẹ́ mímọ́;

àwọn àjèjì kì yóò sì kó o mọ́.

18“Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀,

àwọn òkè kéékèèkéé yóò máa sàn fún wàrà;

gbogbo odò Juda tí ó gbẹ́ yóò máa sàn fún omi.

Orísun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ilé Olúwa wá,

yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣittimu.

19Ṣùgbọ́n Ejibiti yóò di ahoro,

Edomu yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro,

nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Juda,

ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.

20Ṣùgbọ́n Juda yóò jẹ́ ibùgbé títí láé,

àti Jerusalẹmu láti ìran dé ìran.

21Nítorí èmi yóò wẹ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn nù, tí èmi kò tí ì wẹ̀nù.

Nítorí Olúwa ń gbé Sioni.”