4. Mose 7 – HOF & YCB

Hoffnung für Alle

4. Mose 7:1-89

Geschenke zur Einweihung des Heiligtums

1Als das Heiligtum fertiggestellt war, weihte Mose es ein. Er besprengte das Zelt und alles, was darin war, mit Salböl, dann den Altar und die dazugehörigen Gefäße und Werkzeuge. So wurde alles geheiligt und dem Herrn geweiht. 2-3Danach kamen die zwölf führenden Männer Israels mit Geschenken für das Heiligtum. Es waren die Stammesoberhäupter, die Mose bei der Zählung der wehrfähigen Israeliten geholfen hatten. Sie brachten sechs Planwagen zum heiligen Zelt, die von zwölf Rindern gezogen wurden. Jedes Stammesoberhaupt schenkte ein Rind, und je zwei brachten zusammen einen Wagen.

4Der Herr forderte Mose auf: 5»Nimm diese Geschenke an! In den Wagen soll das heilige Zelt transportiert werden. Gib sie jenen Leviten, die sie für ihre Aufgaben brauchen.« 6Mose tat, was der Herr ihm befohlen hatte. 7Den Gerschonitern gab er zwei Wagen und vier Rinder für ihren Dienst. 8Die Merariter unter der Leitung von Itamar, dem Sohn des Priesters Aaron, hatten mehr zu tragen und erhielten deshalb vier Planwagen und acht Rinder. 9Den Kehatitern gab Mose keinen Wagen; sie waren für jene Gegenstände verantwortlich, die nur auf den Schultern getragen werden durften.

10Zur Einweihung des Altars brachten die Stammesoberhäupter Geschenke und Opfertiere vor den Altar. 11Der Herr wies Mose an: »Lass sie ihre Opfer nacheinander darbringen, an jedem Tag soll ein Stammesoberhaupt kommen!«

12Am ersten Tag übergab Nachschon, der Sohn von Amminadab aus dem Stamm Juda, seine Geschenke: 13eine silberne Schüssel, etwa eineinhalb Kilogramm schwer nach dem im Heiligtum gültigen Gewicht, und eine silberne Opferschale von etwa 800 Gramm; beide waren für das Speiseopfer mit feinem Weizenmehl gefüllt, das mit Öl vermengt war; 14weiter brachte Nachschon ein Schälchen aus 120 Gramm Gold voll wohlriechender Weihrauchmischung, 15außerdem einen jungen Stier, einen Schafbock und ein einjähriges Lamm für das Brandopfer, 16einen Ziegenbock für das Sündopfer, 17dazu zwei Rinder, fünf Schafböcke, fünf Ziegenböcke und fünf einjährige Lämmer für das Friedensopfer.

18-23Die anderen Stammesoberhäupter brachten an den nächsten elf Tagen die gleichen Geschenke zum Heiligtum. Auf Nachschon folgte Netanel, der Sohn von Zuar aus dem Stamm Issachar. 24-29Am dritten Tag war Eliab, der Sohn von Helon aus dem Stamm Sebulon, an der Reihe. 30-47Dann kamen Elizur, der Sohn von Schedëur aus dem Stamm Ruben, Schelumiël, der Sohn von Zurischaddai aus dem Stamm Simeon, und Eljasaf, der Sohn von Deguël aus dem Stamm Gad. 48-53Am siebten Tag opferte Elischama, der Sohn von Ammihud aus dem Stamm Ephraim. 54-71Darauf folgten Gamliël, der Sohn von Pedazur aus dem Stamm Manasse, Abidan, der Sohn von Gidoni aus dem Stamm Benjamin, und Ahiëser, der Sohn von Ammischaddai aus dem Stamm Dan. 72-83Am Schluss kamen Pagiël, der Sohn von Ochran aus dem Stamm Asser, und Ahira, der Sohn von Enan aus dem Stamm Naftali.

84Insgesamt stifteten die Stammesoberhäupter Israels zur Einweihung des Altars zwölf silberne Schüsseln, zwölf silberne Opferschalen und zwölf goldene Schälchen. 85Die Schüsseln wogen je eineinhalb Kilogramm und die Opferschalen je 800 Gramm. Zusammen waren es etwa 28 Kilogramm Silber nach dem Gewicht, das im Heiligtum gilt. 86Die goldenen Schälchen für die Weihrauchmischung wogen je 120 Gramm, zusammen also fast eineinhalb Kilogramm. 87Zum Brandopfer gaben die Stammesoberhäupter insgesamt zwölf Stiere, zwölf Schafböcke und zwölf einjährige Lämmer mit den dazugehörigen Speiseopfern; für das Sündopfer brachten sie zwölf Ziegenböcke 88und für das Friedensopfer 24 Stiere, 60 Schafböcke, 60 Ziegenböcke und 60 einjährige Lämmer. All diese Tiere wurden zur Einweihung des Altars geopfert, nachdem man ihn mit Salböl besprengt hatte.

Der Herr redet im Heiligtum

89Dann ging Mose in das heilige Zelt, um mit dem Herrn zu sprechen. Er hörte die Stimme Gottes – sie kam von der Stelle zwischen den beiden Keruben, die auf der Deckplatte der Bundeslade standen. So redete der Herr zu Mose.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 7:1-89

Ọrẹ níbi ìyàsímímọ́ àgọ́

1Nígbà tí Mose ti parí gbígbé àgọ́ dúró, ó ta òróró sí i, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, Ó tún ta òróró sí pẹpẹ, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀. 2Nígbà náà ni àwọn olórí Israẹli, àwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, àwọn alábojútó àwọn tí a kà náà mú ọrẹ wá. 3Wọ́n mú ọrẹ wọn wá síwájú Olúwa: kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́fà ti abo, àti akọ màlúù kan láti ọ̀dọ̀ olórí kọ̀ọ̀kan àti kẹ̀kẹ́ ẹrù kan láti ọ̀dọ̀ olórí méjì. Wọ́n sì kó wọn wá sí iwájú àgọ́.

4Olúwa sọ fún Mose pé: 5“Gba gbogbo nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn, kí wọ́n ba à lè wúlò fún iṣẹ́ inú àgọ́ ìpàdé. Kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan bá ṣe nílò rẹ̀.”

6Mose sì kó àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù àti akọ màlúù náà fún àwọn ọmọ Lefi. 7Ó fún àwọn ọmọ Gerṣoni ní kẹ̀kẹ́ méjì àti akọ màlúù mẹ́rin, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́. 8Ó fún àwọn ọmọ Merari ní kẹ̀kẹ́ mẹ́rin àti akọ màlúù mẹ́jọ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́. Gbogbo wọn wà lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà. 9Ṣùgbọ́n Mose kò fún àwọn ọmọ Kohati ní nǹkan kan nítorí pé èjìká wọn ni wọn yóò fi ru àwọn ohun mímọ́ èyí tí ó jẹ́ ojúṣe tiwọn.

10Nígbà tí a ta òróró sórí pẹpẹ. Àwọn olórí mú àwọn ọrẹ wọn wá fún ìyàsímímọ́ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá síwájú pẹpẹ. 11Nítorí tí Olúwa ti sọ fún Mose pé, “Olórí kọ̀ọ̀kan ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni yóò máa mú ọrẹ tirẹ̀ wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ.”

12Ẹni tí ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kìn-ín-ní Nahiṣoni ọmọ Amminadabu láti inú ẹ̀yà Juda.

13Ọrẹ rẹ̀ jẹ́:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò ti fàdákà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

14Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

15Ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun,

16Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,

17Akọ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Wọ̀nyí ni ọrẹ Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.

18Ní ọjọ́ kejì ni Netaneli ọmọ Ṣuari olórí àwọn ọmọ Isakari mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

19Ọrẹ tí ó kó wá ní:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

20Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí,

21Ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun;

22Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

23Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Netaneli ọmọ Ṣuari.

24Eliabu ọmọ Heloni, olórí àwọn ọmọ Sebuluni ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹta.

25Àwọn ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) àti ṣékélì fàdákà, àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì,

26Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

27Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

28Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

29Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn o fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Eliabu ọmọ Heloni.

30Elisuri ọmọ Ṣedeuri olórí àwọn ọmọ Reubeni ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ kẹrin.

31Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

32Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí,

33Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

34Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

35Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Elisuri ọmọ Ṣedeuri.

36Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai, olórí àwọn ọmọ Simeoni ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ karùn-ún.

37Ọrẹ tí ó kó wá ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

38Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

39Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

40Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

41Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.

42Eliasafu ọmọ Deueli olórí àwọn ọmọ Gadi ní ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹfà.

43Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò bí ẹbọ ohun jíjẹ;

44àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

45akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

46akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

47màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Eliasafu ọmọ Deueli.

48Eliṣama ọmọ Ammihudu, olórí àwọn ọmọ Efraimu ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ keje.

49Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

50àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

51akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

52akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

53Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Eliṣama ọmọ Ammihudu.

54Gamalieli ọmọ Pedasuri, olórí àwọn ọmọ Manase ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹjọ.

55Ọrẹ tirẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

56àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

57akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

58akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

59màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Gamalieli ọmọ Pedasuri.

60Abidani ọmọ Gideoni, olórí àwọn ọmọ Benjamini ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹsànán.

61Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

62àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

63akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

64akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

65màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Abidani ọmọ Gideoni.

66Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai, olórí àwọn ọmọ Dani ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹwàá.

67Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo sílífà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

68àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

69akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

70akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

71àti fún ẹbọ ti ẹbọ àlàáfíà, akọ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn márùn-ún ọlọ́dún kan.

Èyí ni ọrẹ ẹbọ tí Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.

72Pagieli ọmọ Okanri, olórí àwọn ọmọ Aṣeri ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kọkànlá.

73Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

74àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

75akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

76akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

77màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Pagieli ọmọ Okanri.

78Ahira ọmọ Enani, olórí àwọn Naftali ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kejìlá.

79Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì, àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

80àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

81akọ ọ̀dọ́ màlúù kan àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

82akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

83màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Ahira ọmọ Enani.

84Wọ̀nyí ni ọrẹ tí àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli mú wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n ta òróró sí i lórí:

àwo fàdákà méjìlá, àwokòtò méjìlá, àwo wúrà méjìlá. 85Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje (130) ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin (70). Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá ṣékélì (2,400) gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. 86Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwo wúrà méjìlá tí tùràrí kún inú wọn ṣékélì mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Àpapọ̀ ìwọ̀n gbogbo àwo wúrà jẹ́ ọgọ́fà ṣékélì (120).

87Àpapọ̀ iye ẹran fún ẹbọ sísun jẹ́ akọ ọ̀dọ́ màlúù méjìlá, àgbò méjìlá, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan méjìlá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ. Akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ méjìlá.

88Àpapọ̀ iye ẹran fún ọrẹ àlàáfíà jẹ́ màlúù mẹ́rìnlélógún (24), ọgọ́ta (60) àgbò, ọgọ́ta (60) akọ ewúrẹ́ àti ọgọ́ta (60) akọ ọ̀dọ́ màlúù ọlọ́dún kan.

Wọ̀nyí ni ọrẹ ìyàsímímọ́ pẹpẹ lẹ́yìn tí a ta òróró sí i.

89Nígbà tí Mose wọ inú àgọ́ ìpàdé láti bá Olúwa sọ̀rọ̀, Olúwa sì sọ̀rọ̀ sí i láti àárín àwọn kérúbù méjì láti orí ìtẹ́ àánú tí ó bo àpótí ẹ̀rí, ohùn náà sì bá Mose sọ̀rọ̀.