2. Chronik 24 – HOF & YCB

Hoffnung für Alle

2. Chronik 24:1-27

König Joasch lässt den Tempel ausbessern

(2. Könige 12,1‒17)

1Joasch wurde mit 7 Jahren König und regierte 40 Jahre in Jerusalem. Seine Mutter hieß Zibja und stammte aus Beerscheba. 2Solange der Priester Jojada lebte, tat Joasch, was dem Herrn gefiel. 3Jojada suchte zwei Frauen für ihn aus, und Joasch bekam mehrere Söhne und Töchter.

4Nach einiger Zeit beschloss Joasch, den Tempel des Herrn ausbessern zu lassen. 5Er rief die Priester und Leviten zu sich und gab ihnen den Auftrag: »Zieht durch die Städte Judas und sammelt von der ganzen Bevölkerung Geld ein! Damit könnt ihr die Reparaturen bezahlen, die jedes Jahr am Tempel eures Gottes anfallen. Beeilt euch!« Doch die Leviten ließen sich viel Zeit. 6Da stellte Joasch den Hohenpriester Jojada zur Rede: »Warum haben die Leviten immer noch nicht genügend Geld für die Ausbesserungen am Tempel? Warum hast du ihnen nicht befohlen, in Juda und Jerusalem dafür zu sammeln? Hat nicht schon Mose, der Diener des Herrn, von allen Israeliten eine Abgabe für das heilige Zelt verlangt? 7Du weißt, dass Atalja, diese gottlose Frau, den Tempel verfallen ließ. Ihre Anhänger nahmen die Gaben, die für den Herrn bestimmt waren, für ihre Götzen.«

8Auf Befehl des Königs wurde ein Kasten angefertigt und außen beim Tor zum Tempel aufgestellt. 9In ganz Juda und Jerusalem rief man das Volk auf, dem Herrn die Abgaben zu entrichten, die Mose, der Diener Gottes, in der Wüste den Israeliten auferlegt hatte. 10Die führenden Männer und das ganze Volk freuten sich und warfen ihre Gaben in den Kasten, bis er voll war. 11Dann brachten die Leviten, die gerade Dienst hatten, den Kasten in die Kanzlei des Königs. Der Hofsekretär und ein Beauftragter des Hohenpriesters sahen zu, wie sie den Kasten leerten. Dann brachten die Leviten ihn wieder an seinen Platz zurück. So geschah es jeden Tag, und es kam sehr viel Geld zusammen.

12Der König und Jojada händigten das Geld den Bauführern aus, die für die Arbeiten im Tempel verantwortlich waren. Diese wiederum bezahlten damit die Steinhauer, die Zimmerleute, die Eisen- und Bronzegießer. 13Die Arbeit ging zügig voran. Die Handwerker besserten alle Schäden aus, und schließlich war der Tempel wieder in seinem ursprünglichen guten Zustand. 14Als sie fertig waren, brachten die Bauführer das restliche Geld zu König Joasch und zu Jojada. Die beiden ließen davon Gegenstände für den Dienst im Tempel des Herrn herstellen: Schalen, goldene und silberne Gefäße und andere Gegenstände, die man zum Opferdienst brauchte. Solange Jojada lebte, wurden im Tempel des Herrn regelmäßig Brandopfer dargebracht.

15Jojada hatte ein erfülltes Leben und wurde sehr alt. Mit 130 Jahren starb er. 16Er wurde in der »Stadt Davids«, einem Stadtteil von Jerusalem, in den Königsgräbern beigesetzt, denn er hatte für Israel, für Gott und den Tempel viel Gutes getan.

König Joasch wendet sich vom Herrn ab

(2. Könige 12,18‒22)

17Nach Jojadas Tod kamen die führenden Männer Judas zu König Joasch und umschmeichelten ihn. Er ließ sich von ihnen dazu verführen, 18nicht mehr in den Tempel des Herrn, des Gottes seiner Vorfahren, zu gehen. Wie alle anderen verehrte er nun Götzenstatuen und heilige Pfähle, die anderen Göttern geweiht waren. Darum wurde Gott zornig über Juda und Jerusalem. 19Er sandte Propheten unter das Volk. Sie sollten die Menschen warnen und zum Herrn zurückführen. Aber niemand hörte auf sie. 20Da wurde Secharja, der Sohn des Priesters Jojada, von Gottes Geist ergriffen. Er trat vor das Volk und rief ihnen zu: »So spricht Gott, der Herr: Warum übertretet ihr meine Gebote? Von nun an wird euch nichts mehr gelingen! Ihr habt mich verlassen – und jetzt verlasse ich euch!«

21Da rotteten sie sich gegen Secharja zusammen und steinigten ihn im Vorhof des Tempels. König Joasch hatte es befohlen, 22denn ihm war das Gute, das Secharjas Vater Jojada ihm erwiesen hatte, inzwischen völlig gleichgültig. Kurz bevor Secharja starb, rief er noch: »Herr, sieh, was sie tun, und vergelte es ihnen!«

23Am Anfang des nächsten Jahres erklärten die Syrer Joasch den Krieg. Sie marschierten in Juda ein, eroberten Jerusalem und brachten alle führenden Männer des Volkes um. Die Beute ihres Feldzugs sandten sie nach Damaskus zu ihrem König. 24Obwohl die Judäer in der Überzahl waren, ließ der Herr die Syrer siegen, denn Juda hatte den Herrn, den Gott seiner Vorfahren, verlassen. So vollstreckten die Syrer an Joasch das Urteil Gottes; 25sie verwundeten ihn schwer. Kaum waren sie wieder abgezogen, verschworen sich Joaschs Diener gegen ihn. Sie wollten sich dafür rächen, dass er den Sohn des Priesters Jojada ermordet hatte, und brachten den König in seinem Bett um. Er wurde in der »Stadt Davids«, einem Stadtteil von Jerusalem, begraben, jedoch nicht in den Königsgräbern. 26Die beiden Führer der Verschwörung waren Sabad, der Sohn der Ammoniterin Schimat, und Josabad, der Sohn der Moabiterin Schimrit.

27In den Erläuterungen zur Chronik der Könige stehen die Namen von Joaschs Söhnen, die vielen Prophetenworte, die gegen ihn gesprochen wurden, und der Bericht über die Ausbesserungsarbeiten am Tempel Gottes. Joaschs Nachfolger wurde sein Sohn Amazja.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 24:1-27

Joaṣi tún ilé Olúwa ṣe

124.1-14: 2Ọb 11.21–12.14.Joaṣi jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ogójì ọdún. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ṣibia ti Beerṣeba. 2Joaṣi ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa ní gbogbo àkókò Jehoiada àlùfáà. 3Jehoiada yan ìyàwó méjì fún un, ó sì ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.

4Ní àkókò kan, Joaṣi pinnu láti tún ilé Olúwa ṣe. 5Ó pe àwọn Àlùfáà àti àwọn ará Lefi jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Juda, kí ẹ sì gba owó ìtọ́sí láti ọwọ́ gbogbo Israẹli láti fi tún ilé Ọlọ́run ṣe, ṣé nísinsin yìí” Ṣùgbọ́n àwọn ará Lefi kò ṣe é lẹ́ẹ̀kan naà.

6Nítorí náà ọba pa á láṣẹ fún Jehoiada olórí àlùfáà ó sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí o kò béèrè lọ́wọ́ àwọn ará Lefi láti mú wá láti Juda àti Jerusalẹmu, owó orí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi lélẹ̀ àti nípasẹ̀ àpéjọ gbogbo Israẹli fún àgọ́ ẹ̀rí?”

7Nísinsin yìí, àwọn ọmọkùnrin obìnrin búburú ni Ataliah ti fọ́ ilé Ọlọ́run, ó sì ti lo àwọn nǹkan ìyàsọ́tọ̀ fún àwọn Baali.

8Nípasẹ̀ ọba, wọn ṣe àpótí wọ́n sì gbé e sí ìta, ní ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa. 9A ṣe ìkéde ní Juda àti Jerusalẹmu wí pé wọ́n gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa, owó orí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti béèrè lọ́wọ́ Israẹli ní aginjù. 10Gbogbo àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn ènìyàn sì yọ̀, wọ́n sì mún wá, wọ́n ń jù ú sínú àpótí títí tí ó fi kún. 11Nígbàkígbà tí a bá gbé àpótí wọlé láti ọwọ́ àwọn ará Lefi sí ọwọ́ àwọn ìjòyè ọba, tí wọ́n bá sì rí wí pe owó ńlá wà níbẹ̀ àwọn akọ̀wé ọba àti ìjòyè olórí àlùfáà yóò wá láti kó owó rẹ̀ kúrò, wọn yóò sì dá a padà sí ààyè rẹ̀. Wọ́n ṣe èyí déédé, wọ́n sì kó iye owó ńlá. 12Ọba àti Jehoiada fi fún àwọn ọkùnrin náà tí ó sì ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Olúwa. Wọ́n fi owó gba ẹni tí ń fi òkúta mọ ilé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ilé Olúwa padà, àti àwọn òṣìṣẹ́ pẹ̀lú irin àti idẹ láti tún ilé Olúwa ṣe.

13Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ náà, sì lọ síwájú àti síwájú ní ọwọ́ wọn, wọ́n sì tún mú ilé Ọlọ́run dúró sí ipò rẹ̀, wọ́n mún un le. 14Nígbà tí wọ́n sì parí rẹ̀ tán, wọ́n mú owó ìyókù wá sí iwájú ọba àti Jehoiada, a sì fi ohun èlò fún ilé Olúwa, àní ohun èlò fún ìsìn àti fún ẹbọ pẹ̀lú ọpọ́n, àní ohun èlò wúrà àti fàdákà. Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé Olúwa nígbà gbogbo ní gbogbo ọjọ́ Jehoiada.

Ikú Jehoiada

15Ṣùgbọ́n Jehoiada di arúgbó, ó sì kún fún ọjọ́, ó sì kú, ẹni àádóje ọdún ni nígbà tí ó kú. 16Wọ́n sì sin ín ní ìlú Dafidi pẹ̀lú àwọn ọba, nítorí tí ó ṣe rere ní Israẹli, àti sí Ọlọ́run àti sí ilé rẹ̀.

Ìwà búburú Joaṣi

17Lẹ́yìn ikú Jehoiada, àwọn oníṣẹ́ Juda wá láti fi ìforíbalẹ̀ wọn hàn sí ọba. Ó sì fèsì sí wọn. 18Wọ́n pa ilé Olúwa tì, Ọlọ́run baba a wọn. Wọ́n sì ń sin àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yìí, ìbínú Ọlọ́run dé sórí Juda àti Jerusalẹmu. 19Bí ó ti wù kí ó rí, Olúwa rán àwọn wòlíì sí àwọn ènìyàn láti mú wọn padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, wọ́n jẹ́rìí nípa wọn, wọn kì yóò gbọ́.

20Nígbà náà, ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Sekariah ọmọ Jehoiada wòlíì, ó dúró níwájú àwọn ènìyàn ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tẹ̀lé àṣẹ Olúwa? Ìwọ kì yóò ṣe rere. Nítorí tí ìwọ ti kọ Olúwa sílẹ̀, òun pẹ̀lú ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ”

21Ṣùgbọ́n wọ́n dìtẹ̀ sí i, àti nípa àṣẹ ọba, wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa nínú àgbàlá ààfin ilé Olúwa 22Ọba Joaṣi kò rántí inú rere tí Jehoiada baba Ṣakariah ti fihàn án ṣùgbọ́n, ó pa ọmọ rẹ̀, tí ó wí bí ó ti ń kú lọ pé, “Kí Olúwa kí ó rí èyí kí ó sì pè ọ́ sí ìṣirò.”

2324.23-26: 2Ọb 12.17,18,20,21.Ní òpin ọdún, àwọn ọmọ-ogun Aramu yàn láti dojúkọ Joaṣi; wọ́n gbógun ti Juda àti Jerusalẹmu, wọ́n sì pa gbogbo àwọn aṣáájú àwọn ènìyàn. Wọ́n rán gbogbo àwọn ìkógun sí ọba wọn ní Damasku. 24Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ-ogun Aramu ti wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀ Olúwa sì fi ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ogun lé wọn lọ́wọ́, nítorí tí Juda ti kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe ìdájọ́ Joaṣi. 25Nígbà tí àwọn ará Aramu kúrò, wọ́n fi Joaṣi sílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọgbẹ́. Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ si fún pípa ọmọ Jehoiada àlùfáà, wọ́n sì pa á ní orí ibùsùn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, a sì sin ín sínú ìlú ńlá ti Dafidi, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú àwọn ibojì àwọn ọba.

26Àwọn tí ó dìtẹ̀ sì jẹ́ Sabadi, ọmọ Ṣimeati arábìnrin Ammoni àti Jehosabadi ọmọ Ṣimiriti arábìnrin Moabu. 27Àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, àti àkọsílẹ̀ ti ìmúpadà sípò ilé Ọlọ́run ní a kọ sínú ìwé ìtumọ̀ ti àwọn ọba. Amasiah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.