מעשי השליחים 26 – HHH & YCB

Habrit Hakhadasha/Haderekh

מעשי השליחים 26:1-32

1”יש לך רשות לספר את גרסתך“, אמר אגריפס לפולוס.

בתנועות ידיים החל פולוס להגן על עצמו לפני בית־הדין.

2”בר־מזל אני, כבוד המלך אגריפס, על שניתנה לי הזכות להשמיע באוזניך את תשובותיי להאשמותיהם של היהודים, 3כי אני יודע שאתה בקיא בחוקינו ובמנהגינו. אני מבקש ממך, אנא, הקשב לי בסבלנות.

4”כל היהודים יודעים שמאז ימי נעורי בטרסוס, ומאוחר יותר בירושלים, קיבלתי חינוך יהודי מסורתי, ותמיד חייתי על־פי הדרך שבה חונכתי. 5לו היו מוכנים להודות בכך, היו מאשרים שבשאלת קיום התורה והמסורת הייתי תמיד בין הפרושים המחמירים ביותר. 6אולם הסיבה האמיתית להאשמותיהם שונה לחלוטין; הם מתנכלים לי רק משום שאני מצפה להתגשמות הבטחת ה׳ לאבותינו. 7שנים־עשר שבטי ישראל מתפללים יומם ולילה שה׳ יגשים את אותה הבטחה שלה אני מצפה. אדוני המלך, בגלל צפייה זאת הם מאשימים אותי! 8אך האם זה פשע להאמין בתחיית המתים? האם אינכם מאמינים שאלוהים יכול להקים בני אדם לתחייה?

9”גם אני חשבתי בעבר שחובתי להציק ולהזיק למאמינים בישוע מנצרת. 10אסרתי רבים מהקדושים בירושלים, ואף קיבלתי מראשי הכוהנים רשות בכתב לעשות זאת. וכאשר נידונו הקדושים למוות, נתתי את הסכמתי המלאה. 11פעמים רבות עברתי מבית־כנסת אחד לשני, ותחת עינויים אילצתי את המאמינים המשיחיים לגדף את המשיח. למעשה התנגדתי להם בחריפות שכזאת, עד שרדפתי אותם גם בחוץ לארץ.

12”יום אחד יצאתי לדמשק, בסמכותם של הכוהנים ועם ברכתם, כדי לאסור את המאמינים המשיחיים. 13בצהרי היום, אדוני המלך, זרח לפתע אור בהיר יותר מזוהר השמש והציף אותי ואת מלווי. 14כולנו נפלנו ארצה, ואני שמעתי קול מדבר אלי: ’שאול, שאול, מדוע אתה רודף אותי? קשה לך לבעוט בדרבנות!‘26‏.14 כו 14 פירושו: ”הרי אתה מכאיב לעצמך בלבד!“

15” ’מי אתה, אדוני?‘ שאלתי.

”והקול ענה: ’אני ישוע שאותו אתה רודף! 16עתה קום על רגליך, כי נגליתי אליך כדי למנותך להיות לי למשרת ועד. עליך לספר לעולם כולו את אשר ראית היום ואת אשר אראה לך בעתיד. 17אני אגן עליך מפני בני עמך ומפני הגויים. כן, אשלח אותך אל הגויים, 18כדי שתפקח את עיניהם לראות את מצבם האמיתי, כך שיחזרו בתשובה ויחיו באור האלוהים, ולא בחשכת השטן. לשם מה? כדי שאלוהים יסלח לחטאיהם, וייתן להם נחלה יחד עם שאר בני־האדם שטוהרו מחטאיהם והוקדשו לי באמונה‘.

19”וכך, המלך אגריפס, לא התמרדתי נגד החיזיון הזה מן השמים. 20תחילה בישרתי את הדבר לאנשי דמשק, לאחר מכן בירושלים ובכל יהודה, ואחר כך גם לגויים. קראתי לכל בני־האדם לזנוח את חטאיהם, לשוב אל אלוהים ולהוכיח את חרטת לבם במעשים טובים. 21מסיבה זאת עצרו אותי היהודים בבית־המקדש וניסו להרוג אותי. 22אולם ה׳ הגן עלי, והיום אני עדיין חי ויכול לספר עובדות אלה לכולם – לקטנים ולגדולים. אני מלמד אך ורק את דבריהם של משה רבנו ושל הנביאים: 23שהמשיח יסבול ושיהיה הראשון אשר יקום מן המתים, כדי להביא אור ליהודים ולגויים כאחד.“

24לפתע התפרץ פסטוס וקרא: ”פולוס, יצאת מדעתך! לימודיך הממושכים בלבלו את דעתך.“

25”לא יצאתי מדעתי, פסטוס הנכבד“, השיב פולוס. ”אני מדבר דברי אמת מפוכחים. 26המלך אגריפס יודע היטב את כל הדברים האלה. אני מעז לדבר בכנות, כי אני בטוח שהמלך מכיר ויודע את כל המאורעות האלה; הרי הם לא התרחשו בסתר! 27המלך אגריפס, האם אתה מאמין לדברי הנביאים? אני יודע שכן…“

28אך אגריפס שיסע את דבריו של פולוס: ”כמעט שכנעת אותי להאמין שישוע הוא המשיח!“

29ופולוס השיב: ”אני מקווה ומתפלל לאלוהים שבמוקדם או במאוחר אתה וכל הנוכחים כאן תהיו כמוני… אך בלי האזיקים, כמובן!“

30המלך, המושל, ברניקה וכל האחרים קמו 31ויצאו מהאולם. כששבו ודנו בעניינו של פולוס מאוחר יותר, החליטו: ”איש זה אינו אשם בשום פשע שדינו מאסר או מוות.“

32”אלמלא דרש לערער לפני הקיסר,“ אמר אגריפס לפסטוס, ”אפשר היה לשחרר אותו.“

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìṣe àwọn Aposteli 26:1-32

1Agrippa sì wí fún Paulu pé, “A fún ọ láààyè láti sọ tí ẹnu rẹ.”

Nígbà náà ní Paulu ná ọwọ́, ó sì sọ ti ẹnu rẹ pé: 2“Agrippa ọba, inú èmi tìkára mi dùn nítorí tí èmi yóò wí ti ẹnu mi lónìí níwájú rẹ, ní ti gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn Júù fi kan mi, 3pàápàá bí ìwọ tí mọ gbogbo àṣà àti ọ̀ràn tí ń bẹ́ láàrín àwọn Júù dájúdájú. Nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́ kí ìwọ fi sùúrù tẹ́tí gbọ́ tèmi.

4“Àwọn Júù mọ irú ìgbé ayé tí mo ń gbé láti ìgbà èwe mi, láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi ní orílẹ̀-èdè mi àti ní Jerusalẹmu. 5Nítorí wọ́n mọ̀ mi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́rìí sí i, wí pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìsìn wa tí ó lè jùlọ, Farisi ni èmi. 6Nísinsin yìí nítorí ìrètí ìlérí tí Ọlọ́run tí ṣe fún àwọn baba wa ni mo ṣe dúró níhìn-ín fún ìdájọ́. 7Ìlérí èyí tí àwọn ẹ̀yà wa méjèèjìlá tí ń fi ìtara sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru tí wọ́n ń retí àti rí i gbà. Ọba Agrippa, nítorí ìrètí yìí ni àwọn Júù ṣe ń fi mi sùn. 8Èéṣe tí ẹ̀yin fi rò o sí ohun tí a kò lè gbàgbọ́ bí Ọlọ́run bá jí òkú dìde?

926.9-18: Ap 9.1-8; 22.4-16.“Èmi tilẹ̀ rò nínú ará mi nítòótọ́ pé, ó yẹ ki èmi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun lòdì sí orúkọ Jesu tí Nasareti. 10Èyí ni mo sì ṣe ni Jerusalẹmu. Pẹ̀lú àṣẹ tí mo tí gba lọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, mo sọ àwọn púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn mímọ́ sí inú túbú, nígbà tí wọ́n sí ń pa wọ́n, mo ní ohùn sí i. 11Nígbà púpọ̀ ni mo ń fi ìyà jẹ wọ́n láti inú Sinagọgu dé inú Sinagọgu, mo ń fi tipá mú wọn láti sọ ọ̀rọ̀-òdì. Mo sọ̀rọ̀ lòdì sí wọn gidigidi, kódà mo wá wọn lọ sí ìlú àjèjì láti ṣe inúnibíni sí wọn.

12“Nínú irú ìrìnàjò yìí ní mo ń bá lọ sí Damasku pẹ̀lú ọlá àti àṣẹ ikọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 13Ni ọ̀sán gangan, ìwọ ọba Agrippa, bí mo ti wà ní ojú ọ̀nà, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run wá, tí ó mọ́lẹ̀ ju oòrùn lọ, ó mọ́lẹ̀ yí mi ká, àti àwọn tí ń bá mi lọ sì àjò. 14Gbogbo wa sì ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn tí ń fọ sì mi ni èdè Heberu pé, ‘Saulu, Saulu! Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ohun ìrora ní fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún!’

15“Èmi sì wí pé, ‘Ìwọ ta ni, Olúwa?’

“Olúwa sì wí pé, ‘Èmi ni Jesu tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí. 1626.16-17: El 2.1,3.Ṣùgbọ́n dìde, kí o sí fi ẹsẹ̀ rẹ tẹlẹ̀: nítorí èyí ni mo ṣe farahàn ọ́ láti yàn ọ́ ní ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí, fún ohun wọ̀nyí tí ìwọ tí rí nípa mi, àti àwọn ohun tí èmi yóò fi ara hàn fún ọ: 17Èmi yóò gbà ọ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn rẹ àti lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Èmi rán ọ sí wọn nísinsin yìí 1826.18: Isa 42.7,16.láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Satani sí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ́ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi.’

19“Nítorí náà, Agrippa ọba, èmi kò ṣe àìgbọ́ràn sì ìran ọ̀run náà. 20Ṣùgbọ́n mo kọ́kọ́ sọ fún àwọn tí ó wà ní Damasku, àti ní Jerusalẹmu, àti já gbogbo ilẹ̀ Judea, àti fún àwọn kèfèrí, kí wọn ronúpìwàdà, kí wọ́n sì yípadà sí Ọlọ́run, kí wọn máa ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ sì ìrònúpìwàdà. 21Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni àwọn Júù ṣe gbá mi mú nínú tẹmpili, tí wọ́n sì ń fẹ́ pa mí. 22Ṣùgbọ́n bí mo sì tí ri ìrànlọ́wọ́ gbà láti ọ́dọ̀ Ọlọ́run, mo dúró títí ó fi di òní, mo ń jẹ́rìí fún èwe àti àgbà, èmi kò sọ ohun mìíràn bí kò ṣe ohun tí àwọn wòlíì àti Mose tí wí pé, yóò ṣẹ: 23Pé, Kristi yóò jìyà, àti pé òun ni yóò jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti jíǹde kúrò nínú òkú, òun ni yóò sí kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn àti fún àwọn aláìgbàgbọ́.”

24Bí ó sì ti ń sọ tẹnu rẹ̀, Festu wí ní ohùn rara pé, “Paulu! Orí rẹ dàrú; ẹ̀kọ́ àkọ́jù rẹ ti dà ọ́ ní orí rú!”

25Paulu dalóhùn wí pé, “Orí mi kò dàrú, Festu ọlọ́lá jùlọ; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ òtítọ́ àti ọ̀rọ̀ òye ni èmi ń sọ jáde. 26Nítorí ọba mọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, níwájú ẹni tí èmi ń sọ̀rọ̀ ni àìbẹ̀rù: nítorí mo gbàgbọ́ pé ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò pamọ́ fún un, nítorí tí a kò ṣe nǹkan yìí ní ìkọ̀kọ̀. 27Agrippa ọba, ìwọ gba àwọn wòlíì gbọ́ bí? Èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́.”

28Agrippa sì wí fún Paulu pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lérò pé ìwọ le fi àkókò díẹ̀ yìí sọ mí di Kristiani?”

29Paulu sì dáhùn wí pé, “Ní àkókò kúkúrú tàbí gígùn, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó má ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú lè di irú ènìyàn tí èmi jẹ́ láìsí ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí.”

30Nígbà tí ó sì sọ nǹkan wọ̀nyí tan, ọba dìde, àti baálẹ̀, àti Bernike, àti àwọn tí o bá wọn jókòó; 31Nígbà tí wọn wọ ìyẹ̀wù lọ, wọn bá ara wọn jíròrò, wọ́n sọ pé, “Ọkùnrin yìí kò ṣe nǹkan kan tí ó yẹ sí ikú tàbí sì ẹ̀wọ̀n.”

32Agrippa sì wí fún Festu pé, “A bà dá ọkùnrin yìí sílẹ̀ bí ó bá ṣe pe kò ì tí ì fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Kesari.”