אגרתו הראשונה של יוחנן השליח 3 – HHH & YCB

Habrit Hakhadasha/Haderekh

אגרתו הראשונה של יוחנן השליח 3:1-24

1ראו מה רבה אהבת אלוהים אלינו – הוא אף קרא לנו ”בני אלוהים“! ואין זה כינוי בלבד, אלא עובדה. לצערי, אנשים רבים אינם מאמינים באלוהים, ועל כן אינם מבינים כיצד אנו יכולים להיות בניו. 2אחי היקרים, עכשיו אנחנו בני אלוהים; איננו יודעים עדיין מה נהיה בעתיד, אנחנו רק יודעים שבבוא המשיח נהיה כמוהו, כי נראהו פנים אל פנים. 3כל המחזיק בתקווה זאת צריך להישאר טהור ונקי מחטא, כי המשיח עצמו טהור ונקי.

4מי שחוטא, חוטא נגד אלוהים, כי כל חטא נָעָשָה נגד תורת אלוהים. 5אתם הרי יודעים שהוא בא אלינו בדמות אדם, כדי לקחת על עצמו את העונש על חטאינו, למרות שבו לא היה חטא. 6אם נתמיד באמונתנו, נשמע בקולו ונעשה את הטוב בעיניו, לא נחטא. הממשיכים לחטוא חוטאים מסיבה פשוטה: הם מעולם לא האמינו במשיח ולא אהבו אותו.

7בני היקרים, אל תניחו לאיש לרמותכם. העושה מעשים טובים עושה אותם משום שהוא עצמו טוב – כמו המשיח ובזכותו. 8והעושה מעשים רעים מוכיח שהוא שייך לשטן – החוטא הראשון בעולם, שממשיך עדיין במעשיו הרעים – שכן בן־האלוהים בא לבטל את פעולות השטן. 9בני־אלוהים אינם חוטאים יותר מתוך הרגל, מכיוון שאלוהים האב נתן להם חיים וטבע חדש; הם אינם יכולים להמשיך בהרגל החטא.

10כיצד יכולים אנו להבדיל בין ילדי אלוהים לבין ילדי השטן? כל מי שחי חיי חטא ואינו אוהב את אחיו, אינו שייך למשפחת אלוהים. 11שהרי כבר מבראשית מסר לנו אלוהים את המצוה: אהבו איש את רעהו.

12אל לנו להידמות לקין, הורג אחיו, אשר השתייך לשטן. מדוע הרג את אחיו? מפני שקין עשה מעשים רעים, וידע היטב שחיי הבל אחיו היו טובים משלו. 13לכן, אחים יקרים, אל תתפלאו אם העולם שונא אתכם.

14אם אנחנו אוהבים את אחינו המאמינים, אנו יודעים שעברנו ממוות לחיים. בעוד שאדם אשר אין בו אהבה עדיין מת. 15כל השונא את אחיו רוצח אותו בלבו, ואתם יודעים שלרוצחים אין חיי נצח! 16מהי אהבה אמיתית? קורבנו של המשיח! כשם שהקריב את חייו למעננו, כך עלינו להקריב את חיינו למען אחינו.

17אדם הנקרא מאמין משיחי, ויש לו מספיק כסף, אך אין הוא עוזר לאחיו העני הנתון במצוקה, אהבת אלוהים אינה שוכנת בו. 18בני היקרים, הבה נפסיק לדבר על אהבת איש את רעהו; הבה נאהב באמת ונוכיח את אהבתנו במעשים. 19כך נדע בוודאות שאנו שייכים לאלוהים, וכאשר נעמוד לפניו יהיה מצפוננו נקי ושקט. 20אך אם חטאנו ומצפוננו מציק לנו, אלוהים יודע בדיוק מה עשינו וכיצד אנו מרגישים.

21ידידי היקרים, אם מצפוננו נקי אנו יכולים לבוא לפני אלוהים בביטחון מלא, 22והוא ייתן לנו כל מה שנבקש ממנו, שכן אנו שומעים בקולו ועושים את הטוב בעיניו. 23הזוכרים אתם מה ציווה עלינו אלוהים? להאמין בשם ישוע המשיח בנו ולאהוב איש את רעהו. 24כל השומע בקול אלוהים ומקיים את מצוותיו, חי באלוהים ואלוהים חי בו. כיצד אנו יודעים זאת? רוח הקודש השוכן בקרבנו מאשר את הדבר.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Johanu 3:1-24

13.1: Jh 1.12; 16.3.Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba fi fẹ́ wa, tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọ́run; bẹ́ẹ̀ ni a sá à jẹ́. Nítorí èyí ni ayé kò ṣe mọ̀ wá, nítorí tí kò mọ̀ ọ́n. 2Olùfẹ́, ọmọ Ọlọ́run ni àwa ń ṣe nísinsin yìí, a kò ì tí i fihàn bí àwa ó ti rí: àwa mọ̀ pé, nígbà tí òun ba farahàn, àwa yóò dàbí rẹ̀; nítorí àwa yóò rí i, àní bí òun tí rí. 3Olúkúlùkù ẹni tí ó ba sì ní ìrètí yìí nínú rẹ̀, ń wẹ ara rẹ̀ mọ́, àní bí òun ti mọ́.

4Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ó ń rú òfin pẹ̀lú: nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ni rírú òfin. 53.5: Jh 1.29.Ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òun farahàn láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò; ẹ̀ṣẹ̀ kò sì ṣí nínú rẹ̀. 6Ẹnikẹ́ni tí ó ba ń gbé inú rẹ̀ kì í dẹ́ṣẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń dẹ́ṣẹ̀ kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n.

7Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín: ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí òun tí jẹ olódodo. 83.8: Jh 8.34,44.Ẹni tí ó ba ń dẹ́ṣẹ̀ tí èṣù ni; nítorí láti àtètèkọ́ṣe ni èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni ọmọ Ọlọ́run ṣe farahàn, kí ó lè pa iṣẹ́ èṣù run. 93.9: 1Jh 5.18.Ẹnikẹ́ni tí a ti ipa Ọlọ́run bí, kì í dẹ́ṣẹ̀; nítorí tí irú rẹ̀ ń gbé inú rẹ̀: kò sì lè dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé a ti ti ipa Ọlọ́run bí i. 10Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ń farahàn, àti àwọn ọmọ èṣù; ẹnikẹ́ni tí kò ba ń ṣe òdodo, àti ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọ́run.

Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ

113.11: 1Jh 1.5.Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ̀yin tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé ki àwa fẹ́ràn ara wa. 12Kì í ṣe bí Kaini, tí í ṣe ẹni búburú, tí o sì pa arákùnrin rẹ̀. Nítorí kín ni ó sì ṣe pa á? Nítorí tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́ búburú ṣùgbọ́n tí arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ òdodo. 133.13: Jh 15.18-19.Kì ẹnu má ṣe yà yín, ẹ̀yin ará mi, bí ayé bá kórìíra yín. 143.14: Jh 5.24.Àwa mọ̀ pé àwa tí rékọjá láti inú ikú sínú ìyè, nítorí tí àwa fẹ́ràn àwọn ará. Ẹni tí kò ba ni ìfẹ́, ó ń gbé inú ikú. 15Ẹnikẹ́ni tí ó ba kórìíra arákùnrin rẹ̀ apànìyàn ni: ẹ̀yin sì mọ́ pé kò sí apànìyàn tí ó ni ìyè àìnípẹ̀kun láti máa gbé inú rẹ̀.

163.16: Jh 13.1; 15.13.Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa: ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará. 17Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀? 183.18: Jk 1.22.Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́.

19Àti nípa èyí ni àwa ó mọ̀ pé àwa jẹ́ ti òtítọ́, àti pé àwa ó sì fi ọkàn ara wa balẹ̀ níwájú rẹ̀. 20Nínú ohunkóhun tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi; nítorí pé Ọlọ́run tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo. 213.21: 1Jh 5.14.Olùfẹ́, bí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, ǹjẹ́ àwa ni ìgboyà níwájú Ọlọ́run? 22Àti ohunkóhun tí àwa bá béèrè, ni àwa ń rí gbà lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí tí àwa ń pa òfin rẹ̀ mọ́, àwa sì ń ṣe àwọn nǹkan tí ó dára lójú rẹ̀. 233.23: Jh 6.29; 13.34; 15.17.Èyí sì ni òfin rẹ̀, pé kí àwa gba orúkọ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, kí a sì fẹ́ràn ara wá gẹ́gẹ́ bí ó tí fi òfin fún wa. 243.24: 1Jh 4.13.Ẹni tí ó bá sì pa òfin rẹ̀ mọ́ ń gbé inú rẹ̀, àti òun nínú rẹ̀. Àti nípa èyí ni àwa mọ̀ pé ó ń gbé inú wa, nípa Ẹ̀mí tí ó fi fún wa.