Números 30 – CST & YCB

Nueva Versión Internacional (Castilian)

Números 30:1-16

Votos de las mujeres

1Moisés les dijo a los jefes de las tribus de Israel: «El Señor ha ordenado que 2cuando un hombre haga un voto al Señor, o bajo juramento haga un compromiso, no deberá faltar a su palabra, sino que cumplirá con todo lo prometido.

3»Cuando una joven, que todavía viva en casa de su padre, haga un voto al Señor y se comprometa en algo, 4si su padre se entera de su voto y de su compromiso, pero no le dice nada, entonces ella estará obligada a cumplir con todos sus votos y promesas. 5Pero, si su padre se entera y no lo aprueba, todos los votos y compromisos que la joven haya hecho quedarán anulados, y el Señor la absolverá porque fue el padre quien los desaprobó.

6»Si la joven se casa después de haber hecho un voto o una promesa precipitada que la compromete, 7y su esposo se entera, pero no le dice nada, entonces ella estará obligada a cumplir sus votos y promesas. 8Pero, si su esposo se entera y no lo aprueba, el voto y la promesa que ella hizo en forma precipitada quedarán anulados, y el Señor la absolverá.

9»La viuda o divorciada que haga un voto o compromiso estará obligada a cumplirlo.

10»Cuando una mujer casada haga un voto, o bajo juramento se comprometa en algo, 11si su esposo se entera, pero se queda callado y no lo desaprueba, entonces ella estará obligada a cumplir todos sus votos y promesas. 12Pero, si su esposo se entera y los anula, entonces ninguno de los votos o promesas que haya hecho le serán obligatorios, pues su esposo los anuló. El Señor la absolverá.

13»El esposo tiene la autoridad de confirmar o de anular cualquier voto o juramento de abstinencia que ella haya hecho. 14En cambio, si los días pasan y el esposo se queda callado, su silencio confirmará todos los votos y compromisos contraídos por ella. El esposo los confirmará por no haber dicho nada cuando se enteró. 15Pero, si llega a anularlos después de un tiempo de haberse enterado, entonces él cargará con la culpa de su esposa».

16Estos son los estatutos que el Señor dio a Moisés en cuanto a la relación entre esposo y esposa, y entre el padre y la hija que todavía viva en su casa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 30:1-16

Ẹ̀jẹ́

1Mose sì sọ fún olórí àwọn ẹ̀yà ọmọ Israẹli pé: “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: 230.2-16: De 23.21-23.30.2: Mt 5.33.Nígbà tí ọkùnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ ní ìdè kí òun má bà ba ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sọ.

3“Nígbà tí ọmọbìnrin kan bá sì wà ní ilé baba rẹ̀ tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ 4tí baba rẹ̀ bá sì gbọ́ ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ìdè rẹ̀ tí kò sì sọ nǹkan kan sí i, kí gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ kí ó dúró àti gbogbo ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ yóò sì dúró. 5Ṣùgbọ́n tí baba rẹ̀ bá kọ̀ fun un ní ọjọ́ tí ó gbọ́, kò sí ọ̀kan nínú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí nínú ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tí yóò dúró; Olúwa yóò sì tú u sílẹ̀ nítorí baba rẹ̀ kọ̀ fún un.

6“Tí ó bá sì ní ọkọ lẹ́yìn ìgbà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí lẹ́yìn ìgbà tí ó sọ ọ̀rọ̀ kan láti ẹnu rẹ̀ jáde nínú èyí tí ó fi de ara rẹ̀ ní ìdè, 7Tí ọkọ rẹ̀ sì gbọ́ nípa èyí ṣùgbọ́n tí kò sọ nǹkan kan, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tó dúró. 8Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ nígbà tí ó gbọ́, ǹjẹ́ òun yóò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ àti ohun tí ó ti ti ẹnu rẹ̀ jáde, èyí tí ó fi de ara rẹ̀ dasán, Olúwa yóò sì dáríjì í.

9“Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ́ kí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè kí ìdè tí opó tàbí obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ bá ṣe yóò wà lórí rẹ̀.

10“Bí obìnrin tí ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí de ara rẹ̀ ní ìdè lábẹ́ ìbúra, 11tí ọkọ rẹ̀ bá sì gbọ́, ṣùgbọ́n tí kò sọ̀rọ̀, tí kò sì kọ̀, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ rẹ̀ yóò dúró. 12Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá sọ wọ́n dasán, nígbà tí ó gbọ́, nígbà náà kò sí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde tí yóò dúró, ọkọ rẹ̀ ti sọ wọ́n dasán, Olúwa yóò tú u sílẹ̀. 13Ọkọ rẹ̀ lè ṣe ìwádìí tàbí sọ ọ́ dasán ẹ̀jẹ́ tàbí ìbúra ìdè tí ó ti ṣe láti fi de ara rẹ̀. 14Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ kò bá sọ nǹkan kan sí í nípa rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́, nígbà náà ni ó ṣe ìwádìí nípa ẹ̀jẹ́ àti ìbúra ìdè tí ó dè é. Kí ọkùnrin náà ṣe ìwádìí lórí rẹ̀ láìsọ nípa rẹ̀ si nígbà tí ó gbọ́ nípa rẹ̀. 15Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọkùnrin náà bá sọ ọ́ dasán, ní àkókò kan lẹ́yìn tí ó ti gbọ́ wọn, nígbà náà ó jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.”

16Èyí ni ìlànà tí Olúwa fún Mose nípa ìbátan láàrín ọkùnrin àti obìnrin àti láàrín baba àti ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ̀ tí ó sì ń gbé ní ilé rẹ̀.