Malaquías 4 – CST & YCB

Nueva Versión Internacional (Castilian)

Malaquías 4:1-6

El día del Señor

1»Mirad, ya viene el día, ardiente como un horno. Todos los soberbios y todos los malvados serán como paja, y aquel día les prenderá fuego hasta dejarlos sin raíz ni rama —dice el Señor Todopoderoso—. 2Pero para vosotros que teméis mi nombre, se levantará el sol de justicia trayendo en sus rayos4:2 rayos. Lit. alas. salud. Y saldréis saltando como becerros recién alimentados. 3El día que yo actúe, pisotearéis a los malvados, y bajo vuestros pies quedarán hechos polvo —dice el Señor Todopoderoso—.

4»Acordaos de la ley de mi siervo Moisés. Recordad los preceptos y las leyes que le di en Horeb para todo Israel.

5»Voy a enviaros al profeta Elías antes que llegue el día del Señor, día grande y terrible. 6Él hará que los padres se reconcilien con sus hijos y los hijos con sus padres, y así no vendré a herir la tierra con destrucción total».

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Malaki 4:1-6

Ọjọ́ Olúwa n bọ

1“Dájúdájú, ọjọ́ náà ń bọ̀; tí yóò máa jó bi iná ìléru. Gbogbo àwọn agbéraga, àti gbogbo àwọn olùṣe búburú yóò dàbí àgékù koríko: ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò si jó wọn run,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Ti ki yóò fi kù gbòǹgbò kan tàbí ẹ̀ka kan fún wọn. 2Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, oòrùn òdodo yóò yọ, pẹ̀lú ìmúláradá ni ìyẹ́ apá rẹ̀. Ẹ̀yin yóò sì jáde lọ, ẹ̀yin yóò sì máa fò fún ayọ̀ bi àwọn ẹgbọrọ màlúù tí a tú sílẹ̀ lórí ìso. 3Ẹ̀yin yóò sì tẹ àwọn ènìyàn búburú mọ́lẹ̀: nítorí wọn yóò di eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ náà tí èmi yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

4“Ẹ rántí òfin Mose ìránṣẹ́ mi, àwọn ìlànà àti òfin èyí tí mo fún un ní Horebu fún gbogbo Israẹli.”

54.5: Mt 17.11; Mk 9.12.“Wò ó, èmi yóò rán wòlíì Elijah sí i yín, ki ọjọ́ ńlá, ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa to dé: 64.6: Lk 1.17.Òun yóò sì pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sì ti àwọn baba wọn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò wá, èmi yóò sì fi ilẹ̀ náà gégùn.”