Lucas 10 – CST & YCB

Nueva Versión Internacional (Castilian)

Lucas 10:1-42

Jesús envía a los setenta y dos

10:4-12Lc 9:3-5

10:13-15,21-22Mt 11:21-23,25-27

10:23-24Mt 13:16-17

1Después de esto, el Señor escogió a otros setenta y dos10:1 setenta y dos. Var. setenta; también en v. 17. para enviarlos de dos en dos delante de él a todo pueblo y lugar adonde pensaba ir. 2«Es abundante la cosecha —les dijo—, pero son pocos los obreros. Pedidle, por tanto, al Señor de la cosecha que mande obreros a su campo. 3¡Id vosotros! Sabed que os envío como corderos en medio de lobos. 4No llevéis monedero ni bolsa ni sandalias; ni os detengáis a saludar a nadie por el camino.

5»Cuando entréis en una casa, decid primero: “Paz a esta casa”. 6Si hay allí alguien digno de paz, gozará de ella; y, si no, la bendición no se cumplirá.10:6 Si hay … se cumplirá. Lit. Si hay allí un hijo de paz, vuestra paz reposará sobre él; y, si no, volverá a vosotros. 7Quedaos en esa casa, y comed y bebed de lo que ellos tengan, porque el trabajador tiene derecho a su sueldo. No andéis de casa en casa.

8»Cuando entréis en un pueblo y os reciban, comed lo que os sirvan. 9Sanad a los enfermos que encontréis allí y decidles: “El reino de Dios ya está cerca de vosotros”. 10Pero, cuando entréis en un pueblo donde no os reciban, salid a las plazas y decid: 11“Aun el polvo de este pueblo, que se nos ha pegado a los pies, nos lo sacudimos en protesta contra vosotros. Pero tened por cierto que ya está cerca el reino de Dios”. 12Os digo que en aquel día será más tolerable el castigo para Sodoma que para ese pueblo.

13»¡Ay de ti, Corazín! ¡Ay de ti, Betsaida! Si se hubieran hecho en Tiro y en Sidón los milagros que se hicieron en medio de vosotras, ya hace tiempo que se habrían arrepentido con grandes lamentos.10:13 con grandes lamentos. Lit. sentados en saco y ceniza. 14Pero en el juicio será más tolerable el castigo para Tiro y Sidón que para vosotras. 15Y tú, Capernaún, ¿acaso serás levantada hasta el cielo? No, sino que descenderás hasta el abismo.

16»El que os escucha a vosotros me escucha a mí; el que os rechaza a vosotros me rechaza a mí; y el que me rechaza a mí rechaza al que me envió».

17Cuando los setenta y dos regresaron, dijeron contentos:

―Señor, hasta los demonios se nos someten en tu nombre.

18―Yo veía a Satanás caer del cielo como un rayo —respondió él—. 19Sí, os he dado autoridad para pisotear serpientes y escorpiones y vencer todo el poder del enemigo; nada os podrá hacer daño. 20Sin embargo, no os alegréis de que podáis someter a los espíritus, sino alegraos de que vuestros nombres están escritos en el cielo.

21En aquel momento Jesús, lleno de alegría por el Espíritu Santo, dijo: «Te alabo, Padre, Señor del cielo y de la tierra, porque, habiendo escondido estas cosas de los sabios e instruidos, se las has revelado a los que son como niños. Sí, Padre, porque esa fue tu buena voluntad.

22»Mi Padre me ha entregado todas las cosas. Nadie sabe quién es el Hijo, sino el Padre, y nadie sabe quién es el Padre, sino el Hijo y aquel a quien el Hijo quiera revelárselo».

23Volviéndose a sus discípulos, les dijo aparte: «Dichosos los ojos que ven lo que vosotros veis. 24Os digo que muchos profetas y reyes quisieron ver lo que vosotros veis, pero no lo vieron; y oír lo que vosotros oís, pero no lo oyeron».

Parábola del buen samaritano

10:25-28Mt 22:34-40; Mr 12:28-31

25En esto se presentó un experto en la ley y, para poner a prueba a Jesús, le hizo esta pregunta:

―Maestro, ¿qué tengo que hacer para heredar la vida eterna?

26Jesús replicó:

―¿Qué está escrito en la ley? ¿Cómo la interpretas tú?

27Como respuesta, el hombre citó:

―“Ama al Señor tu Dios con todo tu corazón, con todo tu ser, con todas tus fuerzas y con toda tu mente”,10:27 Dt 6:5 y: “Ama a tu prójimo como a ti mismo”.10:27 Lv 19:18

28―Bien contestado —le dijo Jesús—. Haz eso y vivirás.

29Pero él quería justificarse, así que preguntó a Jesús:

―¿Y quién es mi prójimo?

30Jesús respondió:

―Bajaba un hombre de Jerusalén a Jericó, y cayó en manos de unos ladrones. Le quitaron la ropa, lo golpearon y se fueron, dejándolo medio muerto. 31Resulta que viajaba por el mismo camino un sacerdote, quien, al verlo, se desvió y siguió de largo. 32Así también llegó a aquel lugar un levita y, al verlo, se desvió y siguió de largo. 33Pero un samaritano que iba de viaje llegó adonde estaba el hombre y, viéndolo, se compadeció de él. 34Se acercó, le curó las heridas con vino y aceite, y se las vendó. Luego lo montó sobre su propia cabalgadura, lo llevó a un alojamiento y lo cuidó. 35Al día siguiente, sacó dos monedas de plata10:35 monedas de plata. Lit. denarios. y se las dio al dueño del alojamiento. “Cuida de él —le dijo—, y lo que gastes de más, te lo pagaré cuando vuelva”. 36¿Cuál de estos tres piensas que demostró ser el prójimo del que cayó en manos de los ladrones?

37―El que se compadeció de él —contestó el experto en la ley.

―Anda entonces y haz tú lo mismo —concluyó Jesús.

En casa de Marta y María

38Mientras iba de camino con sus discípulos, Jesús entró en una aldea, y una mujer llamada Marta lo recibió en su casa. 39Tenía ella una hermana llamada María que, sentada a los pies del Señor, escuchaba lo que él decía. 40Marta, por su parte, se sentía abrumada porque tenía mucho que hacer. Así que se acercó a él y le dijo:

―Señor, ¿no te importa que mi hermana me haya dejado sirviendo sola? ¡Dile que me ayude!

41―Marta, Marta —le contestó Jesús—, estás inquieta y preocupada por muchas cosas, 42pero solo una es necesaria.10:42 solo una es necesaria. Var. se necesitan pocas cosas, o una sola. María ha escogido la mejor, y nadie se la quitará.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 10:1-42

Jesu rán àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn jáde

110.1: Lk 9.1-2,51-52; 7.13.Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjì méjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkára rẹ̀ yóò sì dé. 210.2: Mt 9.37-38; Jh 4.35.Ó sì wí fún wọn pé, “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀. 310.3-12: Mt 10.7-16; Mk 6.8-11; Lk 9.2-5; 22.35-36.Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n: sá wò ó, èmi rán yín lọ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sáàrín ìkookò. 4Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà.

510.5: 1Sa 25.6.“Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, ‘Àlàáfíà fún ilé yìí!’ 6Bí ọmọ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín. 710.7: 1Kọ 10.27; 9.14; 1Tm 5.18; De 24.15.Ẹ dúró sínú ilé náà, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fi fún yín; nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i, Ẹ má ṣe lọ láti ilé dé ilé.

8“Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín: 9Ẹ sì mú àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ láradá, kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ sí yín!’ 10Ṣùgbọ́n ní ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, tí wọn kò bá sì gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá sì jáde ní ìgboro ìlú náà, kí ẹ̀yin sì wí pé, 1110.11: Ap 13.51.‘Eruku ìlú yín tí ó kù sí wa lẹ́sẹ̀, a gbọ̀n ọ́n sílẹ̀ fún yín! Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.’ 1210.12: Mt 11.24; Gẹ 19.24-28; Jd 7.Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Sodomu ní ọjọ́ náà, ju fún ìlú náà lọ.

1310.13-15: Mt 11.21-23; Lk 6.24-26.“Ègbé ni fún ìwọ, Koraṣini! Ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Nítorí ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ agbára tí a ṣe nínú yín, ní Tire àti Sidoni, wọn ìbá ti ronúpìwàdà lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, wọn ìbá sì jókòó nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti nínú eérú. 14Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tire àti Sidoni nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ. 15Àti ìwọ, Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run? A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú.

1610.16: Mt 10.40; 18.5; Mk 9.37; Lk 9.48; Jh 13.20; 12.48.“Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”

17Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”

1810.18: If 12.9; Jh 12.31.Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Satani ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá. 19Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára. 2010.20: Ek 32.32; Sm 69.28; Da 12.1; Fp 4.3; Hb 12.23; If 3.5; 13.8; 21.27.Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ nítorí èyí pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!”

2110.21-22: Mt 11.25-27.10.21: 1Kọ 1.26-29.Ní wákàtí kan náà Jesu yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́: bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sá à yẹ ní ojú rẹ.

2210.22: Mt 28.18; Jh 3.35; 13.3; 10.15; 17.25.“Ohun gbogbo ni a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Baba mi; kò sì ṣí ẹni tí ó mọ ẹni tí ọmọ jẹ́, bí kò ṣe Baba; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wu ọmọ láti fi í hàn fún.”

2310.23-24: Mt 13.16-17; Jh 8.56; Hb 11.13; 1Pt 1.10-12.Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apá kan. Ó ní, “Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí. 24Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.”

Òwe aláàánú ará Samaria

2510.25-28: Mt 22.34-39; Mk 12.28-31.10.25: Mk 10.17; Mt 19.16; Lk 18.18.Sì kíyèsi i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kín ni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

26Ó sì bi í pé, “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? Báwo ni ìwọ sì ti kà á?”

2710.27: De 6.5; Le 19.18; Ro 13.9; Ga 5.14; Jk 2.8.Ó sì dáhùn wí pé, “ ‘Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ’; àti, ‘ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ”

2810.28: Lk 20.39; Le 18.25.Ó sì wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn rere. Ṣe èyí, ìwọ ó sì yè.”

29Ṣùgbọ́n ó ń fẹ́ láti da ara rẹ̀ láre, ó wí fún Jesu wí pé, “Ta ha sì ni ẹnìkejì mi?”

30Jesu sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jeriko, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n sá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán. 31Ní kòńgẹ́ àkókò yìí ni àlùfáà kan sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ lọ́nà náà. Nígbà tí ó sì rí i ó kọjá lọ níhà kejì. 32Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọmọ Lefi kan pẹ̀lú, nígbà tí ó dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó kọjá lọ níhà kejì. 3310.33: Lk 9.51-56; 17.11-19; Jh 4.4-42.Ṣùgbọ́n ará Samaria kan, bí ó ti ń re àjò, ó dé ibi tí ó gbé wà; nígbà tí ó sì rí i, àánú ṣe é. 34Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì di ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti ọtí wáìnì sí i, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti òun tìkára rẹ̀, ó sì mú un wá sí ilé èrò, a sì ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀. 35Nígbà tí ó sì lọ ní ọjọ́ kejì, ó fi owó idẹ méjì fún olórí ilé èrò ó sì wí fún un pé, ‘Máa tọ́jú rẹ̀; ohunkóhun tí ìwọ bá sì ná kún un, nígbà tí mo bá padà dé, èmi ó san án fún ọ.’

36“Nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, ta ni ìwọ rò pé ó jẹ́ ẹnìkejì ẹni tí ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà?”

37Ó sì dáhùn wí pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.”

Jesu sì wí fún un pé, “Lọ, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́!”

Ní ilé Marta àti Maria

3810.38-42: Jh 12.1-3; 11.1-45.Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Marta sì gbà á sí ilé rẹ̀. 39Ó sì ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Maria tí ó sì jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Olúwa, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 40Ṣùgbọ́n Marta ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkan ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”

4110.41: Lk 7.13.Ṣùgbọ́n Olúwa sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Marta, Marta, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀. 42Ṣùgbọ́n ohun kan ni a kò lè ṣe aláìní, Maria sì ti yan ipa rere náà tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ̀.”