Éxodo 9 – CST & YCB

Nueva Versión Internacional (Castilian)

Éxodo 9:1-35

La plaga en el ganado

1El Señor le ordenó a Moisés que fuera a hablar con el faraón y le advirtiera: «Así dice el Señor y Dios de los hebreos: “Deja ir a mi pueblo para que me rinda culto”. 2Si te niegas a dejarlos ir y sigues reteniéndolos, 3la mano del Señor provocará una terrible plaga entre los ganados que tienes en el campo, y entre tus caballos, asnos, camellos, vacas y ovejas. 4Pero el Señor hará distinción entre el ganado de Israel y el de Egipto, de modo que no morirá un solo animal que pertenezca a los israelitas».

5Además, el Señor fijó un plazo y dijo: «Mañana yo, el Señor, haré esto en el país». 6En efecto, al día siguiente murió todo el ganado de los egipcios, pero del ganado de los israelitas no murió ni un solo animal. 7Envió el faraón gente a ver los ganados de los israelitas, y se encontraron con que ni un solo animal había muerto. Sin embargo, el faraón endureció su corazón y no quiso dejar ir al pueblo.

La plaga de úlceras

8Entonces el Señor les dijo a Moisés y a Aarón: «Tomad de algún horno puñados de ceniza, y que la arroje Moisés al aire en presencia del faraón. 9La ceniza se convertirá en polvo fino, y caerá sobre todo Egipto y abrirá úlceras en personas y animales en todo el país».

10Moisés y Aarón tomaron ceniza de un horno y se plantaron ante el faraón. Allí Moisés la arrojó al aire, y se abrieron úlceras purulentas en personas y animales. 11Los magos no pudieron enfrentarse a Moisés, pues ellos y todos los egipcios tenían úlceras. 12Pero el Señor endureció el corazón del faraón y, tal como el Señor se lo había advertido a Moisés, no quiso el faraón saber nada de Moisés ni de Aarón.

La plaga de granizo

13El Señor le ordenó a Moisés madrugar al día siguiente, y salirle al paso al faraón para advertirle: «Así dice el Señor y Dios de los hebreos: “Deja ir a mi pueblo para que me rinda culto. 14Porque esta vez voy a enviar el grueso de mis plagas contra ti, y contra tus funcionarios y tu pueblo, para que sepas que no hay en toda la tierra nadie como yo. 15Si en este momento desplegara yo mi poder, y a ti y a tu pueblo os azotara con una plaga, desapareceríais de la tierra. 16Pero te he dejado con vida precisamente para mostrarte mi poder, y para que mi nombre sea proclamado por toda la tierra. 17Tú, sin embargo, sigues enfrentándote a mi pueblo y no quieres dejarlo ir. 18Por eso mañana a esta hora enviaré la peor granizada que haya caído en Egipto desde su fundación. 19Ordena inmediatamente que se pongan bajo techo tus ganados y todo lo que tengas en el campo, lo mismo personas que animales, porque el granizo caerá sobre los que anden al aire libre y los matará”».

20Algunos funcionarios del faraón temieron la palabra del Señor y se apresuraron a poner bajo techo a sus esclavos y ganados, 21pero otros no hicieron caso de la palabra del Señor y dejaron en el campo a sus esclavos y ganados.

22Entonces el Señor le dijo a Moisés: «Levanta los brazos al cielo, para que en todo Egipto caiga granizo sobre la gente y los animales, y sobre todo lo que crece en el campo».

23Moisés levantó su vara hacia el cielo, y el Señor hizo que cayera granizo sobre todo Egipto: envió truenos, granizo y rayos sobre toda la tierra. 24Llovió granizo, y con el granizo caían rayos zigzagueantes. Nunca en toda la historia de Egipto como nación hubo una tormenta peor que esta. 25El granizo arrasó con todo lo que había en los campos de Egipto, y con personas y animales; acabó con todos los cultivos y derribó todos los árboles. 26El único lugar en donde no granizó fue en la tierra de Gosén, donde estaban los israelitas.

27Entonces el faraón mandó llamar a Moisés y a Aarón, y les dijo:

―Esta vez reconozco mi pecado. El Señor ha actuado con justicia, mientras que yo y mi pueblo hemos actuado mal. 28No voy a deteneros más tiempo; voy a dejaros ir. Pero rogad por mí al Señor, que truenos y granizo los hemos tenido de sobra.

29―En cuanto yo salga de la ciudad —le contestó Moisés—, elevaré mis manos en oración al Señor, y cesarán los truenos y dejará de granizar. Así sabrás que la tierra es del Señor. 30Sin embargo, yo sé que tú y tus funcionarios aún no tenéis temor de Dios el Señor.

31El lino y la cebada fueron destruidos, ya que la cebada estaba en espiga, y el lino en flor. 32Sin embargo, el trigo y la espelta no se echaron a perder porque maduran más tarde.

33Tan pronto como Moisés dejó al faraón y salió de la ciudad, elevó sus manos en oración al Señor y, en seguida, cesaron los truenos y dejó de granizar y de llover sobre la tierra. 34Pero, en cuanto vio el faraón que habían cesado la lluvia, el granizo y los truenos, reincidió en su pecado, y tanto él como sus funcionarios endurecieron su corazón. 35Tal como el Señor lo había advertido por medio de Moisés, el faraón endureció su corazón y ya no dejó que los israelitas se fueran.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 9:1-35

Ààrùn lára ẹran ọ̀sìn

1Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sọ fún Farao, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu sọ: “Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn Mí” 2Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn ó lọ, tí ó sì dá wọn dúró. 3Ọwọ́ Olúwa yóò mú ààrùn búburú wá sí ara ẹran ọ̀sìn nínú oko, sí ara ẹṣin, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìbákasẹ, màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́ yín. 4Ṣùgbọ́n Olúwa yóò pààlà sí àárín ẹran ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti Israẹli àti ti àwọn ara Ejibiti tí yóò fi jẹ́ pé kò sí ẹran ọ̀sìn ti ó jẹ́ ti ará Israẹli tí yóò kùú.’ ”

5Olúwa sì dá àkókò kan wí pé, “Ní ọ̀la ni Olúwa yóò ṣe èyí ni ilẹ̀ yìí.” 6Olúwa sí ṣe é ni ọjọ́ kejì. Gbogbo ẹran ọ̀sìn ará Ejibiti kú, ṣùgbọ́n ẹyọ kan kò kú lára ẹran ọ̀sìn àwọn Israẹli. 7Farao rán àwọn ènìyàn rẹ̀ láti lọ ṣe ìwádìí, wọ́n sì rí pé ẹyọ kan kò kú lára àwọn ẹran ọ̀sìn ará Israẹli. Síbẹ̀ náà, Farao kò yí ọkàn rẹ̀ padà àti pé kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ.

Ààrùn Oówo

8Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni, “Ẹ bu ẹ̀kúnwọ́ eérú gbígbóná láti inú ààrò, kí Mose kù ú sí inú afẹ́fẹ́ ni iwájú Farao. 9Yóò sì di eruku lẹ́búlẹ́bú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, yóò sì di oówo ti ń tú pẹ̀lú ìléròrò sí ara àwọn ènìyàn àti ẹran jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.”

109.10: If 16.2.Nígbà náà ni wọ́n bú eérú gbígbóná láti inú ààrò, wọ́n dúró ní iwájú Farao. Mose sì ku eérú náà sínú afẹ́fẹ́, ó sì di oówo tí ń tú pẹ̀lú ìléròrò ni ara àwọn ènìyàn àti lára ẹran. 11Àwọn onídán kò le è dúró níwájú Mose nítorí oówo ti ó wà lára wọn àti ni ara gbogbo àwọn ara Ejibiti. 12Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sé ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ ti Mose àti Aaroni, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose.

Òjò o yìnyín

13Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Dìde ni òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí o sì tọ Farao lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu wí: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn mí, 14Nítorí nígbà yìí ni èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé. 15Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọlù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ààrùn búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀. 169.16: Ro 9.17.Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni èmi ṣe mú ọ dúró, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé. 17Síbẹ̀ ìwọ tún gbógun ti àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì jẹ́ kí wọn lọ. 18Nítorí náà, ni ìwòyí ọ̀la, Èmi yóò rán òjò o yìnyín tí irú rẹ̀ kò tí i rọ̀ rí ni Ejibiti láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ títí di àkókò yìí. 19Pàṣẹ nísinsin yìí láti kó ẹran ọ̀sìn yín àti ohun gbogbo ti ẹ ni ní pápá wá sí abẹ́ ààbò, nítorí òjò yìnyín yóò rọ̀ sí orí àwọn ènìyàn àti ẹran ti a kò kó wá sí abẹ́ ààbò tí wọ́n sì wà ni orí pápá, wọn yóò sì kú.’ ”

20Àwọn ti ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Olúwa lára àwọn ìjòyè Farao yára lọ láti kó àwọn ẹrú àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn wá sí abẹ́ ààbò. 21Ṣùgbọ́n àwọn ti kò kà ọ̀rọ̀ Olúwa sí fi àwọn ẹrú wọn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sílẹ̀ ni pápá.

22Olúwa sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ọ̀run kí yìnyín bá à lè rọ̀ sí orí gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, sí orí ènìyàn àti ẹranko, àti sí orí gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko.” 239.23,24: If 8.7; 16.21.Nígbà tí Mose gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, Olúwa rán àrá àti yìnyín, mọ̀nàmọ́ná sì bùsi orí ilẹ̀. Olúwa rọ òjò yìnyín sí orí ilẹ̀ Ejibiti; 24Yìnyín rọ̀, mọ̀nàmọ́ná sì bẹ̀rẹ̀ sí bùsi orí ilẹ̀ èyí ni ó tí ì burú jù ti ó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ti Ejibiti ti di orílẹ̀-èdè. 25Jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti ni yìnyín ti pa gbogbo ohun tí ó wà ni orí pápá; ènìyàn àti ẹranko, ó wò gbogbo ohun ọ̀gbìn lulẹ̀ ó sì fa gbogbo igi ya pẹ̀lú. 26Ilẹ̀ Goṣeni ni ibi ti àwọn Israẹli wà nìkan ni òjò yìnyín náà kò rọ̀ dé.

27Nígbà náà ni Farao pe Mose àti Aaroni sì ọ̀dọ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ ní àkókò yìí; Olúwa jẹ́ olódodo ṣùgbọ́n èmi àti àwọn ènìyàn mi ni aláìṣòdodo. 28Èyí ti òjò yìnyín àti àrá rọ̀ yìí tó gẹ́ẹ́, gbàdúrà sí Olúwa kí ó dáwọ́ rẹ̀ dúró. Èmi yóò jẹ́ kí ẹ lọ, n kò tún ni dá a yín dúró mọ́.”

29Mose dá a lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúrò ní àárín ìlú, èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí Olúwa, sísán àrá yóò dáwọ́ dúró, yìnyín kò sì ni rọ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé Olúwa ni ó ni ilẹ̀. 30Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ kò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run.”

31(A sì lu ọ̀gbọ̀ àti ọkà barle bolẹ̀; nítorí barle wà ní ìpẹ́, ọ̀gbọ̀ sì rudi. 32Alikama àti ọkà ni a kò lù bolẹ̀, nítorí tí wọ́n kò tí ì dàgbà.)

33Nígbà náà ni Mose jáde kúrò ni iwájú Farao, ó kúrò ni àárín ìgboro kọjá lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Olúwa, sísán àrá àti òjò yìnyín ti ń rọ̀ sì dáwọ́ dúró, òjò kò sì rọ̀ sí orí ilẹ̀ mọ́. 34Nígbà tí Farao rí i pé òjò àti yìnyín àti àrá ti ń sán ti dáwọ́ dúró, ó tún ṣẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣì sé àyà wọn le. 35Àyà Farao sì le, bẹ́ẹ̀ ni kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli kí ó lọ, bí Olúwa ti sọ láti ẹnu Mose.