Otkrivenje 19 – CRO & YCB

Knijga O Kristu

Otkrivenje 19:1-21

Pobjednička pjesma u nebu

1Začujem zatim silno mnoštvo u nebu kako viče: “Aleluja! Spasenje je djelo našega Boga. Slava i moć njemu pripadaju! 2Njegovi su sudovi istiniti i pravedni. Kaznio je veliku Bludnicu koja je pokvarila zemlju svojim bludom i osvetio je krv svojih slugu.” 3I opet: “Aleluja! Dim s njezina zgarišta dizat će se u vijeke vjekova!”

4Nato dvadeset četvorica starješina i četiri bića padnu ničice i poklone se Bogu koji sjedi na prijestolju govoreći: “Amen! Aleluja!”

5S prijestolja se začuje glas: “Hvalite našega Boga, sve njegove sluge, svi koji ga se bojite, od najmanjega do najvećega!”

6Začujem potom opet glas silnog mnoštva, poput silnoga huka vode i praska silnih gromova: “Aleluja! Naš Gospodin Bog Svemogući kraljuje! 7Radujmo se i veselimo i slavu mu dajmo jer je došao trenutak Jaganjčeve svadbe i njegova je zaručnica pripravna! 8Dopušteno joj je da se odjene u fini, blistavi i čisti lan.”

A lan predstavlja pravedna djela Božjega naroda.

9Anđeo mi reče: “Napiši: Blago onima koji su pozvani na Jaganjčevu svadbenu gozbu!” I još doda: “Ove su riječi istinite, Božje.”

10Pao sam do njegovih nogu da mu se poklonim, ali on reče: “Ne klanjaj mi se! Ta ja sam samo Božji sluga kao i ti, kao i ostala tvoja braća koja svjedoče o svojoj vjeri u Isusa. Bogu se klanjaj! Jer koji svjedoče o Isusu, imaju proročkog duha.”

Jahač na bijelome konju

11Ugledam zatim otvoreno nebo i ondje konja bijelca. Na njemu je sjedio On, zvan Vjerni i Istiniti, koji pravedno sudi i ratuje. 12Oči su mu bile poput ognjenih plamenova, na glavi mnoge krune. Nosio je napisano ime koje samo on zna. 13Ogrtač mu je bio natopljen krvlju. Ime mu je: Riječ Božja. 14Za njim su išle nebeske vojske odjevene u fini, bijeli i čisti lan. 15Iz usta mu je izlazio oštar mač kojim će posjeći narode. Vladat će njima željeznom palicom. On gazi u tijesku gnjevne srdžbe Svemogućega Boga. 16Na boku ogrtača piše mu ime:

“Kralj kraljeva i Gospodar gospodara”.

17Ugledam zatim anđela kako stoji na suncu i kako na sav glas viče lešinarima što lete nebom: “Dođite! Skupite se na veliku gozbu koju vam je Bog priredio 18da se najedete mesa kraljeva, vojskovođa i moćnika, mesa konja i konjanika, mesa svih ljudi—slobodnih i robova, malih i velikih!”

19I vidim: Zvijer i svi zemaljski kraljevi okupili su se s vojskama da zarate s Onim što sjedi na konju i s njegovom vojskom. 20Ali zarobljeni su Zvijer i lažni prorok koji je u njezinoj nazočnosti činio čudesa i njima zavodio ljude koji su primili žig Zvijeri i klanjali se njezinome kipu. I Zvijer i lažni prorok bačeni su u ognjeno jezero s gorućim sumporom. 21Ostatak njihove vojske posjekao je mač izišao iz usta Onoga koji sjedi na bijelome konju. I svi su se lešinari nasitili njihova mesa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 19:1-21

Haleluya

1Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run bí ẹni pé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ń wí pé:

“Haleluya!

Ti Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà, àti ọlá àti agbára,

219.2: De 32.43.nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀.

Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì,

tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ̀ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà.”

319.3: Isa 34.10.Àti lẹ́ẹ̀kejì wọ́n wí pé:

“Haleluya!

Èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ láé àti láéláé.”

4Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé:

“Àmín, Haleluya!”

519.5: Sm 115.13.Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé:

“Ẹ máa yin Ọlọ́run wa,

ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo,

ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

àti èwe àti àgbà!”

6Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé:

“Haleluya!

Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba.

719.7: Sm 118.24.Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,

kí a sì fi ògo fún un.

Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,

aya rẹ̀ sì ti múra tán.

8Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀

wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”

(Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

9Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”

10Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jesu mú. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jesu ni ìsọtẹ́lẹ̀.”

Ẹni tó gun ẹṣin funfun

1119.11: El 1.1.Mo sì rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó, ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòtítọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun. 1219.12: Da 10.6.Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkára rẹ̀. 13A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 14Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun. 1519.15: Sm 2.9.Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè. 1619.16: De 10.17; Da 2.47.Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:

ọba àwọn ọba àti olúwa àwọn olúwa.

1719.17: El 39.4,17-20.Mo sì rí angẹli kan dúró nínú oòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé: “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè ńlá Ọlọ́run; 18kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹṣin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrú, àti ti èwe àti ti àgbà.”

19Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbá jọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà àti ogun rẹ̀ jagun. 20A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba ààmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ. Àwọn méjèèjì yìí ni a sọ láààyè sínú adágún iná tí ń fi sulfuru jó. 21Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde: Gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran-ara wọn yó.