Matej 23 – CRO & YCB

Knijga O Kristu

Matej 23:1-39

Isus opominje vjerske poglavare

(Mk 12:38-39; Lk 11:39-52; 20:45-46)

1Tada Isus reče mnoštvu i svojim učenicima: 2“Pismoznanci i farizeji službeni su tumači Svetoga pisma.23:2 U grčkome: su zasjeli na Mojsijevu stolicu. 3Zato činite i slušajte sve što vam kažu, ali nemojte slijediti njihov primjer jer oni sami ne čine ono što druge poučavaju. 4Tlače vas teškim teretom vjerskih zahtjeva, a ni prstom ne žele maknuti da vam taj teret pomognu nositi.

5Sve što čine, čine zato da ih ljudi vide. Trude se da ono što na sebi nose u znak pobožnosti—kutijice sa stihovima iz Svetoga pisma na čelu ili oko ruke te rese na odjeći—bude što veće i što duže. 6Na gozbama vole sjediti na pročelju stola, a u sinagogama na počasnome mjestu. 7Godi im kad ih ljudi pozdravljaju na javnim mjestima i kad ih zovu ‘Učitelju’.23:7 U grčkome: Rabbi.

8Vi nikome nemojte dopustiti da vas zove učiteljem jer imate samo jednoga učitelja, a svi ste vi ravnopravna braća i sestre.23:8 U grčkome: svi ste vi braća. 9I ne zovite nikoga ovdje na zemlji Ocem jer imate samo jednoga Oca—onoga na nebesima. 10I ne dajte da vas tko naziva vođom jer imate samo jednoga vođu: Krista. 11Tko je najveći među vama, neka vam bude sluga! 12Tko sebe uzvisuje, bit će ponižen, a ponizni će biti uzvišeni.

13Teško vama, pismoznanci i farizeji! Licemjeri! Zatvarate pred ljudima vrata u nebesko kraljevstvo. Sami ne ulazite u njega, a ne dopuštate da uđu ni oni koji bi htjeli.23:13 U nekim je rukopisima dodan i 14. stih: Teško vama, pismoznanci i farizeji! Bestidno lišavate udovice njihovih dobara, a prikrivate se dugim molitvama u javnosti. Zato ćete vam kazna biti veća.

15Teško vama, pismoznanci i farizeji! Licemjeri! Obilazite morem i kopnom da biste pridobili jednog sljedbenika, a kad vam postane sljedbenikom, učinite od njega sina paklenoga dvostruko gorega nego što ste i sami!

16Teško vama! Slijepi vođe! Tvrdite: ‘Zakune li se tko Hramom, to ne vrijedi. Ali zakune li se hramskim zlatom, onda ga zakletva obvezuje.’ 17Slijepe budale! Pa što je veće—zlato ili Hram koji posvećuje zlato? 18I još kažete: ‘Zakune li se tko žrtvenikom, to ne vrijedi. Ali zakune li se darom koji je na njemu, zakletva ga obvezuje.’ 19Slijepci! Što je veće? Žrtveni dar ili žrtvenik koji ga posvećuje? 20Tko se zakune žrtvenikom, kune se njime i svime što je na njemu. 21A tko se zakune Hramom, kune se njime i Onime koji u njemu prebiva. 22Tko se zakune nebom, kune se Božjim prijestoljem i Bogom koji na njemu sjedi.

23Teško vama, pismoznanci i farizeji! Licemjeri! Jer revno namirujete čak i desetinu metvice, i kopra, i kima, a zanemarujete ono najvažnije u Zakonu: pravednost, milosrđe i vjernost. Treba davati desetinu, ali ne smijete zanemarivati važnije stvari.23:23 U grčkome: Ovo je trebalo činiti, a ono ne propuštati. 24Slijepi vođe! Procjeđujete vodu da ne biste s njom popili i komarca, a kadri ste, ne opazivši, progutati i cijelu devu!

25Teško vama, pismoznanci i farizeji! Licemjeri! Toliko se trudite očistiti svoju čašu i zdjelu izvana, a napunili ste ih svojim grabežom i pohlepom. 26Slijepi farizeju! Očisti najprije ono što je u čaši, pa će i izvana biti čista.

27Teško vama, pismoznanci i farizeji! Vi ste poput obijeljenih grobova. Izvana izgledaju lijepo, a iznutra su prepuni mrtvačkih kostiju i svakojake prljavštine! 28Tako i vi ljudima izvana izgledate pravednima, a iznutra ste prepuni licemjerja i bezakonja.

29Teško vama, pismoznanci i farizeji! Licemjeri! Vi prorocima gradite grobnice i pravednicima kitite spomenike 30pa kažete: ‘Da smo živjeli u doba svojih otaca, ne bismo sudjelovali u prolijevanju proročke krvi.’ 31Tako sami protiv sebe svjedočite da ste sinovi onih koji su ubijali proroke. 32Dovršite, dakle, to što su oni započeli!23:32 U grčkome: Dopunite mjeru svojih otaca!

33Zmije! Leglo zmijsko! Kako ćete izbjeći osudi pakla? 34Šaljem vam, evo, proroke, mudrace i pismoznance. Neke ćete od njih ubiti i raspeti, druge bičevati po sinagogama i progoniti od grada do grada 35tako da na vas padne sva pravedna krv prolivena na zemlji, od krvi pravednog Abela pa do krvi Zaharije, sina Barahijina, kojega ste ubili između Hrama i žrtvenika. 36Zaista vam kažem, sva će ta krv pasti na ovaj naraštaj!”

Isus tuži nad Jeruzalemom

(Lk 13:34-35)

37“Jeruzaleme, Jeruzaleme, koji ubijaš proroke i kamenuješ Božje poslanike! Koliko sam puta htio okupiti tvoju djecu kao što kvočka skuplja piliće pod krila, ali niste htjeli! 38A sada će ti, eto, kuća biti napuštena. 39I kažem vam, nećete me više vidjeti sve dok ne uzviknete: ‘Blagoslovljen koji dolazi u ime Gospodnje!’”23:39 Vidjetii Psalam 118:26.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 23:1-39

Ìdí méje fún ìdájọ́

1Nígbà náà ni Jesu wí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: 2“Àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi jókòó ní ipò Mose, 3Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ gbọ́ tiwọn, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fún yín. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ṣe, nítorí àwọn pàápàá kì í ṣe ohun tí wọn kọ́ yín láti ṣe. 4Wọ́n á di ẹrù wúwo tí ó sì ṣòro láti rù, wọ́n a sì gbé e le àwọn ènìyàn léjìká, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan an.

523.5: Mt 6.1; 5.16; Ek 13.9; De 6.8; Mt 9.20.“Ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí àwọn ènìyàn ba à lè rí wọn ni: Wọ́n ń sọ filakteri wọn di gbígbòòrò. Wọ́n tilẹ̀ ń bùkún ìṣẹ́tí aṣọ oyè wọn nígbà gbogbo kí ó ba à lè máa tóbi sí i. 6Wọ́n fẹ́ ipò ọlá ní ibi àsè, àti níbi ìjókòó ìyàsọ́tọ̀ ni Sinagọgu. 7Wọ́n fẹ́ kí ènìyàn máa kí wọn ní ọjà, kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní ‘Rabbi.’

823.8: Jk 3.1.“Ṣùgbọ́n kí a má ṣe pè yín ni Rabbi, nítorí pé ẹnìkan ni Olùkọ́ yín, àní Kristi, ará sì ni gbogbo yín. 9Ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ni ayé yìí, nítorí baba kan náà ni ẹ ní tí ó ń bẹ ní ọ̀run. 10Kí a má sì ṣe pè yín ní Olùkọ́ nítorí Olùkọ́ kan ṣoṣo ni ẹ̀yin ní, òun náà ni Kristi. 11Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá pọ̀jù nínú yín, ni yóò jẹ́ ìránṣẹ́ yín. 12Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara wọn sílẹ̀ ni a ó gbéga.

1323.13: Lk 11.52.“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin sé ìjọba ọ̀run mọ́ àwọn ènìyàn nítorí ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ wọlé ó wọlé.

14“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin jẹ ilé àwọn opó run, àti nítorí àṣehàn, ẹ̀ ń gbàdúrà gígùn, nítorí náà ni ẹ̀yin yóò ṣe jẹ̀bi púpọ̀.

1523.15: Ap 2.10; 6.5; 13.43.“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin rin yí ilẹ̀ àti Òkun ká láti yí ẹnìkan lọ́kàn padà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń sọ ọ́ di ọmọ ọ̀run àpáàdì ní ìlọ́po méjì ju ẹ̀yin pàápàá.

1623.16-22: Mt 5.33-37; 15.14.“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin afọ́jú ti ń fi ọ̀nà han afọ́jú! Tí ó wí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ba fi tẹmpili búra kò sí nǹkan kan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà inú tẹmpili búra, ó di ajigbèsè.’ 17Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú: èwo ni ó ga jù, wúrà tàbí tẹmpili tí ó ń sọ wúrà di mímọ́? 18Àti pé, Ẹnikẹ́ni tó bá fi pẹpẹ búra, kò jámọ́ nǹkan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni tí ó ba fi ẹ̀bùn tí ó wà lórí rẹ̀ búra, ó di ajigbèsè. 19Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú wọ̀nyí! Èwo ni ó pọ̀jù: ẹ̀bùn tí ó wà lórí pẹpẹ ni tàbí pẹpẹ fúnrarẹ̀ tí ó sọ ẹ̀bùn náà di mímọ́? 20Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fi pẹpẹ búra, ó fi í búra àti gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀. 21Àti pé, ẹni tí ó bá fi tẹmpili búra, ó fi í búra àti ẹni tí ń gbé inú rẹ̀. 22Àti pé, ẹni tí ó bá sì fi ọ̀run búra, ó fi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ búra.

2323.23-24: Lk 11.42; Le 27.30; Mt 6.8.“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin ń gba ìdámẹ́wàá minti, dili àti kumini, ẹ̀yin sì ti fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú òfin sílẹ̀ láìṣe, ìdájọ́, àánú àti ìgbàgbọ́: Wọ̀nyí ni ó tọ́ tí ẹ̀yin ìbá ṣe, ẹ̀yin kò bá fi wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ láìṣe. 24Ẹ̀yin afọ́jú tó ń fi afọ́jú mọ̀nà! Ẹ tu kòkòrò-kantíkantí tó bọ́ sì yín lẹ́nu nù, ẹ gbé ìbákasẹ mì.

2523.25-26: Lk 11.39-41; Mk 7.4.“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ̀yin ń fọ òde ago àti àwo ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kún fún ìrẹ́jẹ àti ẹ̀gbin gbogbo. 26Ìwọ afọ́jú Farisi, tètè kọ́ fọ inú ago àti àwo, gbogbo ago náà yóò sì di mímọ́.

2723.27-28: Lk 11.44; Ap 23.3; Sm 5.9.“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ dàbí ibojì funfun tí ó dára ní wíwò, ṣùgbọ́n tí ó kún fún egungun ènìyàn àti fún ẹ̀gbin àti ìbàjẹ́. 28Ẹ̀yin gbìyànjú láti farahàn bí ènìyàn mímọ́, olódodo, lábẹ́ aṣọ mímọ́ yín ni ọkàn tí ó kún fún ìbàjẹ́ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àgàbàgebè àti ẹ̀ṣẹ̀ wà.

2923.29-32: Lk 11.47-48; Ap 7.51-53.“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè, nítorí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì tí í ṣe ibojì àwọn olódodo ní ọ̀ṣọ́. 30Ẹ̀yin sì wí pé, Àwa ìbá wà ní àsìkò àwọn baba wa, àwa kì bá ní ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì. 31Ǹjẹ́ ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí fún ara yín pé, ẹ̀yin ni ọmọ àwọn tí ó pa àwọn wòlíì. 32Àti pé, ẹ̀yin ń tẹ̀lé ìṣísẹ̀ àwọn baba yín. Ẹ̀yin ń kún òṣùwọ̀n ìwà búburú wọn dé òkè.

3323.33: Mt 3.7; Lk 3.7.“Ẹ̀yin ejò! Ẹ̀yin paramọ́lẹ̀! Ẹ̀yin yóò ti ṣe yọ nínú ẹ̀bi ọ̀run àpáàdì? 34Nítorí náà èmi yóò rán àwọn wòlíì àti àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin tí ó kún fún ẹ̀mí mímọ́, àti àwọn akọ̀wé sí yín. Ẹ̀yin yóò pa àwọn kan nínú wọn nípa kíkàn wọ́n mọ́ àgbélébùú. Ẹ̀yin yóò fi pàṣán na àwọn ẹlòmíràn nínú Sinagọgu yín, tí ẹ̀yin yóò sì ṣe inúnibíni sí wọn láti ìlú dé ìlú. 35Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ ta sílẹ̀ ní ayé, láti ẹ̀jẹ̀ Abeli títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah ọmọ Berekiah ẹni tí ẹ pa nínú tẹmpili láàrín ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run. 36Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò wà sórí ìran yìí.

3723.37-39: Lk 13.34-35.“Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìlú tí ó pa àwọn wòlíì, tí ó sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi tí ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ̀. 38Wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. 39Nítorí èmi sọ èyí fún yín, ẹ̀yin kì yóò rí mi mọ́, títí ẹ̀yin yóò fi sọ pé ‘Olùbùkún ni ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa.’ ”