Djela Apostolska 21 – CRO & YCB

Knijga O Kristu

Djela Apostolska 21:1-40

Pavlovo putovanje u Jeruzalem

1Pošto smo se od njih oprostili, otplovili smo jedrenjakom do otoka Kosa, a sutradan do Roa, pa u Pataru. 2Ondje smo se ukrcali na lađu za sirijsku pokrajinu Feniciju. 3Kad smo ugledali Cipar, prošli smo pokraj njega s desne strane jedreći prema Siriji. Pristali smo u Tiru da lađa iskrca teret. 4Sišli smo na kopno te ondje našli vjernike.21:4 U grčkome: učenike. Isto i u 21:16. Kako im je Sveti Duh otkrio21:4 U grčkome: rekli su Pavlu kroz Svetoga Duha. Vidjeti stihove: 20:22-24 i 22:10-12. da će Pavao u Jeruzalemu imati nevolja, rekli su mu da ne ide onamo. 5Ali kad je prošlo tjedan dana, ipak smo otputovali. Oni su nas svi ispratili do izvan grada, skupa sa ženama i djecom. Na obali smo kleknuli i pomolili se. 6Pozdravili smo se i ukrcali na lađu, a oni su se vratili doma.

7Otplovili smo tako iz Tira u Ptolemaidu. Pozdravili smo ondje braću i ostali s njima jedan dan. 8Zatim smo otišli u Cezareju i boravili u domu Filipa evanđelista, jednoga od sedmorice koji su dijelili hranu. 9On je imao četiri neudane kćeri koje su imale dar prorokovanja.

10Kad smo ondje bili već nekoliko dana, dođe neki Agab koji je također imao dar prorokovanja, 11uzme Pavlov pojas te njime sebi zaveže noge i ruke. “Ovo govori Sveti Duh”, reče. “Vlasnika ovog pojasa ovako će svezati židovski vođe u Jeruzalemu i predati ga Rimljanima.” 12Kad smo to čuli, i mi koji smo s njime putovali i mještani počnemo preklinjati Pavla da ne ide u Jeruzalem.

13Ali on reče: “Što plačete? Slamate mi srce! Spreman sam ne samo da me svežu nego i umrijeti za Gospodina Isusa.” 14Kad je bilo jasno da se ne daje nagovoriti, odustali smo i rekli: “Neka bude volja Gospodnja!”

Pavao stiže u Jeruzalem

15Ubrzo nakon toga spremili smo se i otišli u Jeruzalem. 16Neki vjernici iz Cezareje koji su pošli s nama odvedu nas nekome Mnasonu s Cipra, jednomu od prvih učenika, da ondje odsjednemo. 17Svi su nas vjernici u Jeruzalemu srdačno dočekali.

18Sutradan Pavao pođe s nama k Jakovu. Ondje su bili i svi starješine jeruzalemske Crkve. 19On ih pozdravi te im podrobno izloži što je Bog učinio među poganima kroz njegovu službu.

20Kad su to čuli, dadu slavu Bogu. Zatim mu rekoše: “Dragi brate, deseci tisuća Židova također su povjerovali. Oni se revno drže Mojsijeva zakona, 21a za tebe su im rekli da Židove koje žive među poganima učiš da ne poštuju Mojsijev zakon. Kažu da ih poučavaš da ne obrezuju djecu i da se ne drže židovskih običaja. 22Što da učinimo? Sigurno će čuti da si došao.

23Učini zato kako ti kažemo. Među nama su četvorica koji su se zavjetovali i sad se spremaju obrijati glavu. 24Idi s njima u Hram i pridruži im se u obredu posvećenja te plati da im obriju glave. Tako će svi znati da su te glasine lažne, da si na pravome putu i da poštuješ židovski Zakon.

25A glede pogana koji su povjerovali, od njih tražimo što smo im napisali u pismu: da ne jedu meso žrtvovano idolima, krv ni meso udavljenih životinja te da se klone bluda.”

Pavlovo uhićenje

26Pavao dakle pristane na njihov zahtjev te sljedećeg dana obavi s njima obred očišćenja te ode u Hram. Ondje oglasi da je njihov zavjet istekao i da će za svakoga od njih prinijeti žrtvu.

27Upravo se navršavalo sedam dana kad neki Židovi iz Male Azije opaze Pavla u Hramu i podjare narod protiv njega. Ščepaju ga 28vičući: “Izraelci! U pomoć! Evo čovjeka koji poučava protiv naroda, protiv našega Zakona i protiv Hrama! Čak ga je oskvrnuo dovodeći Grke u njega!” 29Prije su, naime, u gradu s njime vidjeli Trofima iz Efeza pa su mislili da je Pavao njega doveo u Hram.

30Sav se grad uzbuni te nastane metež. Ščepaju Pavla i odvuku ga iz Hrama te odmah zatvore za njim vrata. 31Dok su ga nastojali ubiti, zapovjedniku rimske čete dojave da je u Jeruzalemu pobuna. 32On odmah s vojnicima i stotnicima potrči prema pobunjenicima. Kad je svjetina vidjela zapovjednika s vojnicima, prestanu udarati Pavla. 33Zapovjednik priđe, uhiti ga i zapovjedi da ga okuju dvostrukim lancima. Onda počne ispitivati tko je on i što je učinio. 34Iz svjetine su jedni vikali jedno, a drugi drugo. Zbog graje nije mogao pouzdano saznati razlog pa zato Pavla povede u vojarnu. 35Kad su došli do stuba, svjetina se tako razjarila da su ga vojnici morali nositi kako bi ga zaštitili. 36Mnoštvo je išlo za njima i vikalo: “Smakni ga!”

Pavao propovijeda mnoštvu

37Na ulazu u vojarnu Pavao reče zapovjedniku: “Smijem li što reći?”

“Zar ti znaš grčki?” upita ga ovaj iznenađeno. 38“Ti dakle nisi onaj Egipćanin koji je nedavno digao pobunu i poveo u pustinju četiri tisuće prevratnika?”

39“Nisam”, odgovori Pavao. “Ja sam Židov iz Tarza, znamenitoga grada u Ciliciji. Molim te, dopusti mi da se obratim narodu.” 40Zapovjednik mu dopusti. Pavao stane na stube i mahne rukom narodu. Nastane velika tišina. Prozbori im na hebrejskome.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìṣe àwọn Aposteli 21:1-40

Sí Jerusalẹmu

1Lẹ́yìn tí àwa ti kúrò lọ́dọ̀ wọn, tí a sì ṣíkọ̀, àwa bá ọ̀nà wa lọ tààrà sí Kosi. Ní ọjọ́ kejì a sì lọ sí Rodu, àti gba ibẹ̀ lọ sí Patara: 2A rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń rékọjá lọ sí Fonisia, a wọ inú ọkọ̀ náà, a sì ṣíkọ̀. 3Nígbà tí àwa sì ń wo Saipurọsi lókèèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Siria, a sì gúnlẹ̀ ni Tire; nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù sílẹ̀. 4Nígbà tí a sì ti rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn níbẹ̀, a dúró ní ọ̀dọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọjọ́ méje: àwọn ẹni tí ó ti ipá Ẹ̀mí wí fún Paulu pé, kí ó má ṣe lọ sí Jerusalẹmu. 5Nígbà tí a sì tí lo ọjọ́ wọ̀nyí tan, àwa jáde, a sì mu ọ̀nà wá pọ̀n; gbogbo wọn sì sìn wá, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé títí àwa fi jáde sí ẹ̀yìn ìlú, nígbà tí àwa sì gúnlẹ̀ ní èbúté, a sì gbàdúrà. 6Nígbà tí a sì ti dágbére fún ara wa, a bọ́ sí ọkọ̀; bẹ́ẹ̀ ni àwọn sì padà lọ sí ilé wọn.

7Nígbà tí a sì ti parí àjò wa láti Tire, àwa dé Pitolemai; nígbà ti a sì kí àwọn ará, a sì bá wọn gbé ní ọjọ́ kan. 8Ní ọjọ́ kejì a lọ kúrò, a sì wá sí Kesarea; nígbà tí á sì wọ ilé Filipi efangelisti tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méje; àwa sì wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. 9Ọkùnrin yìí sì ní ọmọbìnrin mẹ́rin, wúńdíá, tí wọ́n máa ń sọtẹ́lẹ̀.

10Bí a sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, wòlíì kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, tí a ń pè ní Agabu. 11Nígbà tí ó sì dé ọ̀dọ̀ wa, ó mú àmùrè Paulu, ó sì de ara rẹ̀ ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí: ‘Báyìí ni àwọn Júù tí ó wà ní Jerusalẹmu yóò de ọkùnrin tí ó ní àmùrè yìí, wọn ó sì fi í lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́.’ ”

12Nígbà tí a sì tí gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, àti àwa, àti àwọn ará ibẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 13Nígbà náà ni Paulu dáhùn wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í ṣe fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerusalẹmu, nítorí orúkọ Jesu Olúwa.” 14Nígbà tí a kò lè pa á ní ọkàn dà, a dákẹ́ wí pé, “Ìfẹ́ tí Olúwa ni kí ó ṣe!”

15Lẹ́yìn ọjọ́ wọ̀nyí, a palẹ̀mọ́, a sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 16Nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti Kesarea bá wa lọ, wọ́n sì mú wa lọ sí ilé Munasoni ọmọ-ẹ̀yìn àtijọ́ kan ara Saipurọsi, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa yóò dé sí.

Dídé Paulu sí Jerusalẹmu

17Nígbà tí a sì dé Jerusalẹmu, àwọn arákùnrin sì fi ayọ̀ gbà wá, 18Ní ọjọ́ kejì, a bá Paulu lọ sọ́dọ̀ Jakọbu; gbogbo àwọn alàgbà sì wà níbẹ̀. 19Nígbà tí ó sì kí wọn tan, ó ròyìn lẹ́sẹẹsẹ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe láàrín àwọn aláìkọlà nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.

20Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ rí iye ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn Júù tí ó gbàgbọ́, gbogbo wọn ni ó sì ní ìtara fún òfin. 21Wọ́n sì ti ròyìn rẹ̀ fún wọn pé, ìwọ ń kọ́ gbogbo àwọn Júù tí ó wà láàrín àwọn aláìkọlà pé, kí wọn kọ Mose sílẹ̀, ó ń wí fún wọn pé kí wọn má ṣe kọ àwọn ọmọ wọn ní ilà mọ́, kí wọn má sì ṣe rìn gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn. 22Ǹjẹ́ èwo ni ṣíṣe? Ìjọ kò lè ṣàìmá péjọpọ̀: dájúdájú wọn yóò gbọ́ pé, ìwọ dé. 23Ǹjẹ́ èyí tí àwa ó wí fún ọ yìí ni kí o ṣe: Àwa ni ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́; 24Àwọn ni kí ìwọ mú, kí o sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, kí ó sì san owó láti fá irun orí wọn: gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, kò sì òtítọ́ kan nínú ohun tí wọ́n gbọ́ sí ọ; àti pé, ìwọ tìkára rẹ ń rìn déédé, ìwọ sì ń pa òfin Mose mọ́. 25Ṣùgbọ́n ní ti àwọn aláìkọlà tí ó gbàgbọ́, àwa tí kọ̀wé, a sì ti pinnu rẹ̀ pé, kí wọn pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, àti ẹ̀jẹ̀ àti ohun ìlọ́lọ́rùnpa, àti àgbèrè.”

26Nígbà náà ni Paulu mú àwọn ọkùnrin náà; ní ọjọ́ kejì ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, ó sì wọ inú tẹmpili lọ, láti sọ ìgbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ náà yóò pé tí a ó sì fi ọrẹ lélẹ̀ fún olúkúlùkù wọn.

A mú Paulu

27Nígbà tí ọjọ́ méje sì fẹ́rẹ̀ pé, tí àwọn Júù tí ó ti Asia wá rí i ni tẹmpili, wọ́n rú gbogbo àwọn ènìyàn sókè, wọ́n nawọ́ mú un. 28Wọ́n ń kígbe wí pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbà wá: Èyí ni ọkùnrin náà tí ń kọ́ gbogbo ènìyàn níbi gbogbo lòdì sí àwọn ènìyàn, àti sí òfin, àti sí ibí yìí: àti pẹ̀lú ó sì mú àwọn ará Giriki wá sínú tẹmpili, ó sì tí ba ibi mímọ́ yìí jẹ́.” 29Nítorí wọ́n tí rí Tirofimu ará Efesu pẹ̀lú rẹ̀ ní ìlú, ẹni tí wọ́n ṣe bí Paulu mú wá sínú tẹmpili.

30Gbogbo ìlú sì wà ní ìrúkèrúdò, àwọn ènìyàn sì súré jọ: wọ́n sì mú Paulu, wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú tẹmpili: lójúkan náà, a sì ti ìlẹ̀kùn. 31Bí wọn sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun pé, gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú. 32Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ; nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Paulu.

33Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì béèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe. 34Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun. 35Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà ipá àwọn ènìyàn. 36Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ́ tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Mú un kúrò!”

Ọ̀rọ̀ Paulu níwájú àwọn ènìyàn

37Bí wọ́n sì tí fẹ́rẹ̀ mú Paulu wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó wí fún olórí ogun pé, “Èmi ha lè bá ọ sọ̀rọ̀ bí?”

Ó sì dáhùn wí pé, “Ìwọ mọ èdè Giriki bí? 38Ìwọ ha kọ ní ara Ejibiti náà, tí ó ṣọ̀tẹ̀ ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ti ó sì ti mú ẹgbàajì ọkùnrin nínú àwọn tí í ṣe apànìyàn lẹ́yìn lọ sí ijù?”

39Ṣùgbọ́n Paulu sì wí pé, “Júù ní èmi jẹ́, ará Tarsu ìlú Kilikia, tí kì í ṣe ìlú yẹpẹrẹ kan, èmi síbẹ̀ ọ, fún mi ní ààyè láti bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ̀rọ̀!”

40Nígbà tí ó sì tí fún un ní ààyè, Paulu dúró lórí àtẹ̀gùn, ó sì juwọ́ sí àwọn ènìyàn. Nígbà tí wọ́n sì dákẹ́ rọ́rọ́, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, wí pé: