2 Korinćanima 4 – CRO & YCB

Knijga O Kristu

2 Korinćanima 4:1-18

Blago u propadljivim posudama

1Tako nam je Bog po svojemu milosrđu dao ovu službu, i nikada ne odustajemo, 2već odbacujemo potajne i sramotne načine rada. Ne služimo se lukavstvima i ne izvrćemo Božju riječ. Govorimo, naprotiv, istinu pred Bogom, i to zna svatko tko savjesno pred Bogom prosuđuje.

3Ako je Radosna vijest koju naviještamo nekome zastrta, zastrta je onima koji su na putu u vječnu propast. 4Njima je bog ovoga svijeta, Sotona, posve oslijepio nevjerničku pamet, pa ju ne može prosvijetliti sjajna svjetlost Radosne vijesti o Kristu, koji je Božja slika.

5Mi ne propovijedamo sebe, nego Gospodina Isusa Krista. Za sebe kažemo samo da smo vaši sluge radi Isusa. 6Bog koji je rekao: “Neka u tami zasja svjetlo!” prosvijetlio je naša srca spoznajom Božje slave na licu Isusa Krista.

7Ali blago tog prosvjetljenja čuva se u propadljivim posudama, u našima slabim tijelima.4:7 U grčkome: u zemljanim posudama. Tako svatko može vidjeti da ta moćna sila dolazi od Boga, a ne od nas. 8Sa svih smo strana pritisnuti nevoljama, ali nismo slomljeni. Zdvojni smo, ali ne očajavamo. 9Progone nas, ali nas Bog ne ostavlja. Obaraju nas, ali nas ne mogu uništiti. 10Naša tijela kroz patnju neprekidno imaju dijela u Isusovim smrtnim patnjama, da bi se na njima također mogao očitovati Isusov život.

11Mi koji smo živi, predajemo se smrti zaradi Isusa, da bi se njegov život očitovao u našemu smrtnom tijelu. 12Suočeni smo sa smrću, ali vama je to donijelo vječni život.

13A kako imamo isti duh vjere kao i onaj tko je u Svetome pismu napisao “Povjerovao sam, te zato govorim”,4:13 Psalam 116:10. i mi vjerujemo pa zato i govorimo. 14Znamo da će isti Bog koji je podignuo Gospodina Isusa od mrtvih i nas uskrisiti s Isusom te nas, skupa s vama, postaviti uza se. 15Sve se to događa zaradi vaše dobrobiti, da sve više i više ljudi primi Božju milost. Tada će više ljudi zahvaljivati Bogu, pa će se Bog tako više proslaviti.

16Zato ne malakšemo. Iako naša tijela polako propadaju, naše se unutarnje biće obnavlja iz dana u dan. 17Jer naše male i prolazne nevolje pribavljaju nam vječnu i golemu slavu. 18Zato ne gledamo na ono što je vidljivo, nego na nevidljivo. Jer to što je vidljivo će proći, a nevidljivo je vječno.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kọrinti 4:1-18

Ìṣúra nínú ohun-èlò amọ̀

1Nítorí náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nípa àánú Ọlọ́run ni a rí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí gba, àárẹ̀ kò mú ọkàn wa rara; 2Ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nípa fífi òtítọ́ hàn, àwa ń fi ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run. 3Ṣùgbọ́n báyìí, bí Ìhìnrere wa bá sí fi ara sin, ó fi ara sin fún àwọn tí ó ń ṣègbé. 44.4: Jh 12.31; Kl 1.15.Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn. 5Nítorí àwa kò wàásù àwa tìkára wa, bí kò ṣe Kristi Jesu Olúwa; àwa tìkára wa sì jẹ́ ẹrú yín nítorí Jesu. 64.6: Gẹ 1.3.Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó tan láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń tan mọ́lẹ̀ lọ́kàn wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jesu Kristi.

7Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò amọ̀, kí ọláńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá. 8A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dààmú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù. 9A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run. 10Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jesu Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jesu hàn pẹ̀lú lára wa. 11Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fi àwa tí ó wà láààyè fún ikú nítorí Jesu, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú. 12Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín.

134.13: Sm 116.10.Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ pé, “Èmi gbàgbọ́, nítorí náà ni èmi ṣe sọ,” pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan náà, a tún gbàgbọ́ àti nítorí náà ni àwa sì ṣe ń sọ. 144.14: 1Tẹ 4.14.Àwa mọ̀ pé, ẹni tí o jí Jesu Olúwa dìde yóò sì jí wa dìde pẹ̀lú nípa Jesu, yóò sì mú wa wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú yín 15Nítorí tiyín ní gbogbo rẹ̀, ki ọ̀pẹ lè dí púpọ̀ fún ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ ti ń gbòòrò sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.

16Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́. 17Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayé tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa. 18Níwọ́n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.