1 Petrova 4 – CRO & YCB

Knijga O Kristu

1 Petrova 4:1-19

Živjeti za Boga

1Budući da je Krist trpio u tijelu, i vi budite poput njega—spremni trpjeti. Jer ako ste voljni trpjeti za Krista, znači da ste odlučili da prestanete griješiti 2i da ostatak tjelesnog života proživite prema Božjoj volji, a ne ugađajući ljudskim požudama. 3Dosta je što ste prije živjeli u onome u čemu uživaju bezbožni ljudi: u razvratu, požudama, pijančevanju, razuzdanim gozbama, pijankama i zločinačkim idolopoklonstvima. 4Zato se oni sada čude što se s njima više ne odajete raskalašenosti pa vas vrijeđaju. 5Ali položit će račun Bogu, koji je već spreman suditi i živima i mrtvima. 6Stoga je Radosna vijest bila propovijedana čak i mrtvima, tako da njihov duh, iako su njihova tijela bila kažnjena smrću, može živjeti kao što živi Bog.

7Uskoro će svršetak svega. Budite zato bistra uma i trijezni, da se možete moliti. 8A najvažnije od svega je da žarko volite jedni druge jer ljubav prašta mnoge grijehe. 9Gostoljubivo i bez prigovaranja primajte jedni druge! 10Bog vam je svima dao različite duhovne darove. Uporabite ih tako da služite jedni drugima onim darom koji ste po Božjoj milosti dobili. 11Služi li se tko darom govora, neka pazi da govori Božje riječi. Ima li tko dar služenja, neka služi snagom koju mu daje Bog. Tako će se u svemu proslaviti Bog po Isusu Kristu. Njemu je slava i sila u vijeke vjekova. Amen.

Kršćansko trpljenje

12Braćo voljena, ne čudite se vatrenim kušnjama koje su vas snašle, kao da vam se što neobično događa. 13Radujte se, naprotiv, što ste dionici Kristovih patnji pa ćete se s njime radovati i kad se objavi njegova slava. 14Radujte se ako vas vrijeđaju zbog Kristova imena jer u vama prebiva Duh slave, Božji Duh. 15Neka nitko od vas ne trpi kao ubojica, kradljivac, zločinac, pa čak ni zato što se miješa u tuđa posla. 16Ali ne stidite se trpjeti zato što ste kršćani, nego zahvaljujte Bogu što se tako možete nazivati. 17Jer došlo je vrijeme suda, a on mora započeti s Božjom djecom! A ako se čak i nama kršćanima mora suditi, kakva li tek strašna sudbina očekuje one koji nisu poslušali Božje evanđelje! 18Ako se Bog toliko trudio da spasi pravednike, kako će tek završiti bezbožnici i grešnici?4:18 Izreke 11:31. 19Zato oni koji po Božjoj volji trpe, neka čine dobra djela i neka se pouzdaju u svojega vjernog Stvoritelja.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Peteru 4:1-19

Ìgbé ayé fún Ọlọ́run

1Ǹjẹ́ bí Kristi ti jìyà fún wa nípa ti ará, irú kan náà ni kí ẹ̀yin fi hámọ́ra; nítorí ẹni tí ó bá ti jìyà nípa ti ara, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀; 2Kí ẹ̀yin má ṣe fi ìgbà ayé yín ìyókù wà nínú ara mọ́ sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ènìyàn bí kò ṣe sí ìfẹ́ Ọlọ́run. 3Nítorí ìgbà tí ó ti kọjá ti tó fún ṣíṣe ìfẹ́ àwọn aláìkọlà, rínrìn nínú ìwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ọtí àmupara, ìréde òru, kíkó ẹ̀gbẹ́ ọ̀mùtí, àti ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ohun ìríra. 4Èyí tí ó yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ̀yin kò ba wọn súré sínú irú àṣejù ìwà wọ̀bìà wọ́n, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ yín ní búburú. 5Àwọn ẹni tí yóò jíyìn fún ẹni tí ó ti múra láti ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú. 6Nítorí èyí ní a sá ṣe wàásù ìhìnrere fún àwọn òkú, kí a lè ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nípa ti ara, ṣùgbọ́n kí wọ́n lè wà láààyè si Ọlọ́run nípa tí Ẹ̀mí.

7Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo kù sí dẹ̀dẹ̀; nítorí náà kí ẹ̀yin wà ní àìrékọjá, kí ẹ sì máa ṣọ́ra nínú àdúrà. 8Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrín ara yín: nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀. 9Ẹ máa ṣe ara yín ni àlejò láìsí ìkùnsínú. 10Bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn gbà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe ìpín fún ni rẹ̀ láàrín ara yín, bí ìríjú rere tí onírúurú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. 11Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí ó ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fi fún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jesu Kristi, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé. Àmín.

Jíjìyà fun jíjẹ́ onígbàgbọ́

12Olùfẹ́, ẹ má ṣe ka ìdánwò gbígbóná ti ń bẹ láàrín yín láti dán yín wò bi ẹni pé ohun àjèjì ni ó dé bá yín: 13Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábápín ìyà Kristi, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn. 144.14: Isa 11.2.Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín. 15Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí apànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣe búburú, tàbí bí ẹni tí ń tojú bọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn. 16Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí Kristiani kí ojú má ṣe tì í: ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo nítorí ti o orúkọ yìí. 17Nítorí ti ìgbà náà dé, tí ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti ilé Ọlọ́run wá: bí ó bá sì tètè tí ọ̀dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀, ìgbẹ̀yìn àwọn tí kò gba ìhìnrere Ọlọ́run yó ha ti rí?

184.18: Òw 11.31.“Bí ó bá ṣe pé agbára káká ni a fi gba olódodo là,

níbo ni aláìwà-bí-Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò yọjú sí?”

19Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwọn tí ń jìyà gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run ni ṣíṣe rere, fi ọkàn wọn lè Ẹlẹ́dàá olóòtítọ́ lọ́wọ́.