阿摩司書 1 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

阿摩司書 1:1-15

1猶大烏西雅約阿施的兒子以色列耶羅波安執政期間,大地震前兩年,提哥亞的牧人阿摩司看到了關於以色列的異象。以下是阿摩司的話。

2他說:

「耶和華在錫安1·2 錫安」位於耶路撒冷北部,即大衛城,有時用來指耶路撒冷。怒吼,

在耶路撒冷呼喊。

牧人的草場枯乾,

迦密山頂枯黃。」

對亞蘭的審判

3耶和華說:

大馬士革人三番四次地犯罪,

我必不收回對他們的懲罰,

因為他們用打糧食的鐵器蹂躪基列

4所以我要降火在哈薛王家,

燒毀便·哈達王的城堡。

5我要折斷大馬士革城的門閂,

剷除亞文平原1·5 亞文平原」希伯來文是「邪惡谷」。亞文平原和伯·伊甸皆屬於亞蘭人。的居民和伯·伊甸的掌權者,

使亞蘭人被擄到吉珥1·5 吉珥的位置不詳,亞蘭人原來自吉珥。

這是耶和華說的。」

對非利士的審判

6耶和華說:

迦薩人三番四次地犯罪,

我必不收回對他們的懲罰,

因為他們把被擄之人全都帶走,

賣到以東做奴隸。

7所以,我要降火在迦薩的城牆上,

燒毀它的城堡。

8我要剷除亞實突的居民和亞實基倫的掌權者,

伸手攻擊以革倫

剩下的非利士人都要滅亡。

這是主耶和華說的。」

對泰爾的審判

9耶和華說:

泰爾人三番四次地犯罪,

我必不收回對他們的懲罰,

因為他們背棄弟兄之盟,

把被擄之人都賣到以東

10所以,我要降火在泰爾的城牆上,

燒毀它的城堡。」

對以東的審判

11耶和華說:

以東人三番四次地犯罪,

我必不收回對他們的懲罰,

因為他們拔刀追趕自己的弟兄,

沒有半點憐憫之心;

他們怒氣不息,永懷憤怒。

12所以,我要降火在提幔

燒毀波斯拉的城堡。」

對亞捫的審判

13耶和華說:

亞捫人三番四次地犯罪,

我必不收回對他們的懲罰,

因為他們為了擴張領土,

竟剖開基列孕婦的肚腹。

14所以,我要在戰爭的吶喊聲中,

在暴風雨吹襲的時候,

降火在拉巴的城牆上,

燒毀它的城堡。

15他們的君王和首領都要被擄。

這是耶和華說的。」

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Amosi 1:1-15

1Àwọn ọ̀rọ̀ Amosi, ọ̀kan lára àwọn olùṣọ́-àgùntàn Tekoa; ohun tí o rí nípa Israẹli ní ọdún méjì ṣáájú ilẹ̀-rírì, nígbà tí Ussiah ọba Juda àti Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Israẹli.

21.2: Jl 3.16.Ó wí pé:

Olúwa yóò bú jáde láti Sioni

ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jerusalẹmu wá;

Ibùgbé àwọn olùṣọ́-àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀,

orí òkè Karmeli yóò sì rọ.”

Ìdájọ́ àwọn aládùúgbò Israẹli

31.3-5: Isa 17.1-3; Jr 49.23-27; Sk 9.1.Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku,

àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà

Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi.

Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú

4Èmi yóò rán iná sí ilé Hasaeli

Èyí ti yóò jó àwọn ààfin Beni-Hadadi run.

5Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú Damasku;

Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní Àfonífojì Afeni run

àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Beti-Edeni.

Àwọn ará a Aramu yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kiri,”

ni Olúwa wí.

61.6-8: Isa 14.29-31; Jr 47; El 25.15-17; Jl 3.4-8; Sf 2.4-7; Sk 9.5-7.Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Gasa,

àní nítorí mẹ́rin,

Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà

Gẹ́gẹ́ bí í oníṣòwò ẹrú,

ó kó gbogbo àwọn ènìyàn mi ní ìgbèkùn.

Ó sì tà wọ́n fún Edomu,

7Èmi yóò rán iná sí ara odi Gasa

tí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run

8Èmi yóò ké àwọn olùgbé Aṣdodu kúrò,

ti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Aṣkeloni mú.

Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ekroni

títí tí ìyókù Filistini yóò fi ṣègbé,”

ni Olúwa Olódùmarè wí.

91.9-10: Isa 23; El 26.1–28.19; Jl 3.4-8; Sk 9.3-4.Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Tire

àní nítorí mẹ́rin, Èmi kì yóò yí ìpinnu ìjìyà mi padà.

Nítorí wọ́n ta gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìgbèkùn fún Edomu

Wọn kò sì nání májẹ̀mú ọbàkan,

10Èmi yóò rán iná sí ara odi Tire

Tí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run.”

111.11-12: Isa 34; 63.1-6; Jr 49.7-22; El 25.12-14; 35; Ọd; Ml 1.2-5.Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Edomu,

àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà

Nítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀,

Ó sì gbé gbogbo àánú sọnù

ìbínú rẹ̀ sì ń faniya títí

ó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́

12Èmi yóò rán iná sí orí Temani

Tí yóò jó gbogbo ààfin Bosra run.”

131.13-15: Jr 49.1-6; El 21.28-32; 25.1-7; Sf 2.8-11.Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Ammoni

àní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà,

Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún Gileadi

kí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn.

14Èmi yóò rán iná sí ara odi Rabba

èyí tí yóò jó àwọn ààfin rẹ̀ run

pẹ̀lú ìhó ayọ̀ ní ọjọ́ ogun,

pẹ̀lú ìjì líle ni ọjọ́ àjà.

15Ọba wọn yóò sì lọ sí ìgbèkùn

Òun àti àwọn ọmọ-aládé rẹ̀ lápapọ̀,”

ni Olúwa wí.