Saamu 100
Saamu. Fún ọpẹ́
1Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé
2Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa:
Ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
3Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,
kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé
tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀
àti àgùntàn pápá rẹ̀.
4Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;
ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
5Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore
ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;
àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.