約書亞記 6 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

約書亞記 6:1-27

耶利哥城塌陷

1耶利哥人害怕以色列人,就把所有的城門都關得緊緊的,無人出入。 2耶和華對約書亞說:「看啊,我已經把耶利哥耶利哥王及其英勇的戰士都交在你手中了。 3你所有的軍隊要每天繞城一圈,連續六天, 4讓七個祭司拿著七個羊角號走在約櫃前面。到了第七天,你們要繞城七圈,祭司要吹響號角。 5當你們聽到號角長鳴時,所有的人都要高聲吶喊,城牆就會坍塌,眾人便可以直衝上去。」 6的兒子約書亞便召來祭司,對他們說:「你們抬起約櫃,派七位祭司拿著七個羊角號走在耶和華的約櫃前面。」 7他又對民眾說:「你們要前去繞著城牆走,軍隊要走在耶和華的約櫃前面。」

8聽完約書亞的吩咐,七個祭司便在耶和華面前拿著羊角號邊走邊吹,耶和華的約櫃就跟在他們後面, 9軍隊走在吹號的祭司前面,殿後軍隊跟在約櫃後面。祭司一路上吹著號角。 10約書亞吩咐民眾:「在我下令叫你們吶喊以前,誰也不許作聲,一句話也不許說。」 11這樣,約書亞使耶和華的約櫃繞城一圈,然後眾人各自回營休息。

12第二天,約書亞一早起來,祭司又抬起耶和華的約櫃。 13七個祭司拿著七個羊角號走在耶和華的約櫃前面,一邊走一邊吹角。軍隊走在祭司前面,殿後軍隊跟在耶和華的約櫃後面。 14這一天他們又繞城一圈,然後各自回營。六天都是這樣。

15第七天黎明時分,他們起來照樣繞城,只是這一天他們繞城走了七次。 16走到第七次,祭司吹響了號角,約書亞吩咐民眾說:「吶喊吧!因為耶和華已經將這城交給你們了。 17要把這座城和城裡所有的東西毀滅,作為獻給耶和華之物。只有妓女喇合和她家中所有的人可以活命,因為她曾把我們派去的探子隱藏起來。 18你們要小心,不可私拿任何應當毀滅的東西,免得你們自取滅亡,並給以色列全營帶來災禍。 19要把所有的金銀和銅鐵器皿分別出來獻給耶和華,放進耶和華的庫房裡。」 20於是,民眾聽到號角聲時,就高聲呐喊,城牆便坍塌了。民眾便一擁而上,佔領了耶利哥城, 21用刀殺了城裡所有的男女老少、牛羊和驢。

22約書亞對那兩個探子說:「你們到那個妓女家裡,照著你們向她起過的誓,把她和她的家人都帶出來。」 23於是,那兩個年輕探子便進去,把喇合和她的父母、兄弟及所有的親人都帶出來,安置在以色列人的營外。 24以色列人燒毀全城和城內一切的東西,只把金銀和銅鐵器皿放在耶和華的庫房裡。 25約書亞因為妓女喇合把兩個探子隱藏起來,就饒了她和她一家人的性命。他們至今仍住在以色列人當中。

26之後,約書亞起誓說:

「重建耶利哥城的人必定在耶和華面前受咒詛,

他立地基的時候必死長子,

建城門的時候必喪幼子。」

27耶和華與約書亞同在,他的聲名傳遍各地。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Joṣua 6:1-27

1Wàyí o, a ti há Jeriko mọ́lé gágá nítorí àwọn ọmọ Israẹli, ẹnikẹ́ni kò jáde, ẹnikẹ́ni kò sì wọlé.

2Nígbà náà ni Olúwa wí fún Joṣua pé, “Wò ó, mo ti fi Jeriko lé ọ lọ́wọ́ pẹ̀lú ọba rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀. 3Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan pẹ̀lú gbogbo àwọn jagunjagun. Ẹ ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà. 4Jẹ́ kí àwọn àlùfáà méje gbé fèrè ìwo àgbò ní iwájú àpótí ẹ̀rí. Ní ọjọ́ keje, Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, pẹ̀lú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè. 5Nígbà tí ẹ bá gbọ́ ohùn fèrè náà, kí àwọn ènìyàn hó yèè ní igbe ńlá, nígbà náà ni odi ìlú náà yóò sì wó lulẹ̀, àwọn ènìyàn yóò sì lọ sí òkè, olúkúlùkù yóò sì wọ inú rẹ̀ lọ tààrà.”

6Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ọmọ Nuni pe àwọn àlùfáà ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa náà kí àwọn àlùfáà méje tí ó ru fèrè ìwo wà ní iwájú u rẹ̀.” 7Ó sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ lọ, kí ẹ sì yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ tí ó hámọ́ra kọjá ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa.”

8Nígbà tí Joṣua ti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ tán, àwọn àlùfáà méje tí wọ́n gbé fèrè méje ní iwájú Olúwa kọjá sí iwájú, wọ́n sì fọn fèrè wọn, àpótí ẹ̀rí Olúwa sì tẹ̀lé wọn. 9Àwọn olùṣọ tí ó hámọ́ra sì lọ níwájú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè, olùṣọ́ ẹ̀yìn sì tẹ̀lé àpótí ẹ̀rí náà. Ní gbogbo àsìkò yìí fèrè sì ń dún. 10Ṣùgbọ́n Joṣua tí pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ kígbe ogun, ẹ kò gbọdọ̀ gbé ohùn yín sókè, ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ kan títí ọjọ́ tí èmi yóò sọ fún un yín pé kí ẹ hó. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sì hó!” 11Bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí àpótí ẹ̀rí Olúwa yí ìlú náà ká, ó sì yí i ká lẹ́ẹ̀kan. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà padà sí ibùdó, wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún alẹ́ náà.

12Joṣua sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa. 13Àwọn àlùfáà méje tí ó gbé ìpè ìwo àgbò méje ń lọ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n sì ń fọ́n àwọn ìpè: àwọn tí ó hámọ́ra ogun ń lọ níwájú u wọn; àwọn ọmọ tó wà lẹ́yìn sì ń tọ àpótí ẹ̀rí Olúwa lẹ́yìn, àwọn àlùfáà sì ń fọn ìpè bí wọ́n ti ń lọ. 14Ní ọjọ́ kejì, wọ́n yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan wọ́n sì padà sí ibùdó. Wọ́n sì ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà.

15Ní ọjọ́ keje, wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní àfẹ̀mọ́júmọ́, wọ́n sì wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí i ti ìṣáájú, ní ọjọ́ keje nìkan ṣoṣo ni wọ́n wọ́de ogun yí ìlú náà ká nígbà méje. 16Ní ìgbà keje, nígbà tí àwọn àlùfáà fọn fèrè, Joṣua pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ hó! Nítorí pé Olúwa ti fún un yín ní ìlú náà. 17Ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀ ni yóò jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ fún Olúwa. Rahabu tí ó jẹ́ panṣágà nìkan àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ ni a ó dá sí; nítorí tí ó pa àwọn ayọ́lẹ̀wò tí á rán mọ́. 18Ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ̀yin kí ó má ba à ṣojú kòkòrò nípa mímú nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ ó sọ ibùdó Israẹli di ìparun. Kí ẹ sì mú wàhálà wá sórí i rẹ̀. 19Gbogbo fàdákà àti wúrà àti ohun èlò idẹ àti irin jẹ́ mímọ́ fún Olúwa, wọ́n yóò wá sínú ìṣúra Olúwa.”

20Nígbà tí àwọn àlùfáà fọn ìpè, àwọn ènìyàn náà sì hó. Ó sì ṣe, bí àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìró ìpè, tí àwọn ènìyàn sì hó ìhó ńlá, odi ìlú náà wó lulẹ̀ bẹẹrẹ; bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ya wọ inú ìlú náà lọ tààrà, wọ́n sì kó ìlú náà. 21Wọ́n ya ìlú náà sọ́tọ̀ fún Olúwa àti fún ìparun, wọ́n sì fi idà run gbogbo ohun alààyè ní ìlú náà—ọkùnrin àti obìnrin, ọ́mọdé, àti àgbà, màlúù, àgùntàn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

22Joṣua sì sọ fún àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ti wá ṣe ayọ́lẹ̀wò ilẹ̀ náà pé, “Ẹ lọ sí ilé panṣágà nì, kí ẹ sì mu jáde àti gbogbo ohun tí í ṣe tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ tí búra fún un.” 23Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó lọ ṣe ayọ́lẹ̀wò wọlé lọ, wọ́n sì mú Rahabu jáde, baba rẹ̀, ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Wọ́n sì mú gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde, wọ́n sì fi wọ́n sí ibìkan ní ìta ibùdó àwọn ará Israẹli.

24Nígbà náà ni wọ́n sun gbogbo ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú u rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fi fàdákà, wúrà ohun èlò idẹ àti irin sínú ìṣúra ilé Olúwa. 25Ṣùgbọ́n Joṣua dá Rahabu panṣágà pẹ̀lú gbogbo ìdílé e rẹ̀ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tirẹ̀ sí nítorí pé, ó pa àwọn ọkùnrin tí Joṣua rán gẹ́gẹ́ bí ayọ́lẹ̀wò sí Jeriko mọ́. Ó sì ń gbé láàrín ará Israẹli títí di òní yìí.

266.26: 1Ọb 16.34.Ní àkókò náà Joṣua sì búra pé; “Ègún ni fún ẹni náà níwájú Olúwa tí yóò dìde, tí yóò sì tún ìlú Jeriko kọ́:

“Pẹ̀lú ikú àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni

yóò fi pilẹ̀ rẹ̀;

ikú àbíkẹ́yìn rẹ̀ ní yóò fi

gbé ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ ró.”

27Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wà pẹ̀lú Joṣua; òkìkí rẹ̀ sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.