歷代志上 10 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

歷代志上 10:1-14

掃羅之死

1非利士人與以色列人交戰,以色列人敗逃,許多人在基利波山被殺。 2非利士人窮追掃羅及其眾子,殺了掃羅的兒子約拿單亞比拿達麥基舒亞3掃羅周圍的戰鬥非常猛烈,他被弓箭手發現、射成重傷, 4就對為他拿兵器的人說:「拔出你的刀來刺死我吧!免得那些未受割禮的人來凌辱我。」但拿兵器的人非常害怕,不敢動手,掃羅就自己伏刀自盡。 5拿兵器的人看見掃羅已死,也伏刀自盡了。 6這樣,掃羅和他的三個兒子及全家都死了。 7住在山谷中的以色列人看見以色列軍敗逃、掃羅及其眾子已死,都棄城而逃。於是,非利士人佔領了那些城邑。 8次日,非利士人來剝陣亡者的衣物,發現掃羅及其眾子橫屍基利波山, 9就剝下掃羅的盔甲,割下他的頭顱,並派人到非利士四境向他們的偶像和民眾通告消息。 10他們將掃羅的盔甲放在他們的神廟裡,把他的頭顱掛在大袞神廟中。 11基列·雅比人聽見非利士人對掃羅的所作所為, 12他們所有的勇士就去把掃羅和他兒子們的屍體運到雅比,葬在雅比的橡樹下,並禁食七天。 13掃羅死了,因為他對耶和華不忠,不聽從祂的教誨,甚至去求問靈媒, 14而不求問耶和華。因此,耶和華使他被殺,把王位交給了耶西的兒子大衛

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 10:1-14

Saulu gba ẹ̀mí ara rẹ̀

110.1-12: 1Sa 31.1-13.Nísinsin yìí, àwọn ará Filistini dojú ìjà kọ Israẹli, Àwọn ará Israẹli sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí orí òkè Gilboa. 2Àwọn ará Filistini sí lépa Saulu gidigidi àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ rẹ̀. Jonatani, Abinadabu àti Malikiṣua. 3Ogun náà sí gbóná janjan fún Saulu, nígbà tí àwọn tafàtafà sì lé e bá, wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́.

4Saulu sì sọ fún ẹni tí ó gbé ìhámọ́ra rẹ̀ pé, Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má wá láti bú mi.

Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ ń bẹ̀rù, kò sì le ṣe é; Bẹ́ẹ̀ ni Saulu mú idà tirẹ̀ ó sì ṣubú lé e. 5Nígbà tí agbé-ìhámọ́ra rí pé Saulu ti kú, òhun pẹ̀lú ṣubú lórí idà tirẹ̀, ó sì kú. 6Bẹ́ẹ̀ ni Saulu àti ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú, gbogbo ilé rẹ̀ sì kú ṣọ̀kan, lọ́jọ́ kan náà.

7Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rí wí pé àwọn ọmọ-ogun ti sálọ àti pé Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú wọ́n kọ àwọn ìlú wọn sílẹ̀, wọ́n sì sálọ. Àwọn ará Filistini wá, wọ́n sì jókòó nínú wọn.

8Ní ọjọ́ kejì, Nígbà tí àwọn ará Filistini wá láti kó òkú, wọ́n rí Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣubú sórí òkè Gilboa. 9Wọ́n bọ́ ní aṣọ, wọ́n sì gbé orí rẹ̀ àti ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì rán ìránṣẹ́ lọ káàkiri ilẹ̀ àwọn ará Filistini láti kéde ìròyìn náà láàrín àwọn òrìṣà wọn àti àwọn ènìyàn wọn. 10Wọ́n gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sí inú ilé tí wọ́n kọ́ fún òrìṣà wọn, wọ́n sì fi orí rẹ̀ kọ́ sí inú ilé Dagoni.

11Nígbà tí gbogbo àwọn olùgbé Jabesi—Gileadi gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ará Filistini ṣe fún Saulu, 12Gbogbo àwọn akọni ọkùnrin wọn lọ láti mú àwọn ará Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Jabesi. Nígbà náà, wọ́n sin egungun wọn sábẹ́ igi óákù ní Jabesi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ méje.

13Saulu kú nítorí kò ṣe òtítọ́ sí Olúwa: Kò pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ pẹ̀lú, ó tọ abókùúsọ̀rọ̀ lọ fún ìtọ́sọ́nà. 14Kò sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa pa á, Ó sì yí ìjọba náà padà sọ́dọ̀ Dafidi ọmọ Jese.