撒母耳記下 7 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

撒母耳記下 7:1-29

上帝對大衛的應許

1大衛住在王宮裡,耶和華使他安享太平,不受四圍的仇敵侵擾。 2一天,王對拿單先知說:「你看!我住在香柏木造的王宮中,但上帝的約櫃還留在帳篷裡。」 3拿單答道:「你只管照著自己的想法去做吧,因為耶和華與你同在。」 4當晚耶和華對拿單說: 5「你去告訴我的僕人大衛,『耶和華說,你豈是為我建造殿宇的人? 6從我把以色列人帶出埃及那天起,直到今天,我從未住過殿宇,一路上都住在帳篷裡。 7在我與以色列人同行的日子,我從未責問任何我委派牧養我子民的士師,你為何不為我建香柏木的殿宇呢?』

8「現在你要告訴我的僕人大衛,萬軍之耶和華說,『你原本在草場牧羊,我召你來做我以色列子民的首領。 9無論你去哪裡,我都與你同在,為你剷除所有仇敵。現在我要使你聲名遠播,與世上的偉人齊名。 10-11我必為我的以色列子民預備一個地方,栽培他們,讓他們住在自己的家園,不再受驚擾,不會像從前我設立士師治理他們的時候那樣受惡人壓迫。我必使你安定,免受仇敵的侵擾。我耶和華向你宣告,我必建立你的王室。 12你壽終正寢、與祖先同眠之後,我必立你的後裔接替你的王位,使他江山穩固。 13他必為我的名建造聖殿,我必使他的王位堅立,直到永遠。 14我要做他的父親,他要做我的兒子。如果他犯了罪,我必用人的杖、世人的鞭子來懲治他, 15但我的慈愛卻不會像離開從你面前被廢的掃羅那樣離開他。 16你的家和你的國必在我面前永遠堅立,你的王位必永遠穩固。』」

17拿單就把所聽到的啟示全部告訴大衛

大衛的禱告

18於是,大衛王走進會幕,在耶和華面前坐下,說:「主耶和華啊,我是誰?我的家算什麼?你竟如此厚待我。 19主耶和華啊,你覺得這還不夠,你還要施恩賜福給你僕人的後代。主耶和華啊,這樣的福分豈是常人可以得到的? 20主耶和華啊,我還能對你說什麼呢?你深知你的僕人。 21你讓僕人知道你憑自己的應許、按自己的旨意行了這大事。 22主耶和華啊,你真偉大!我們從未聽過有誰能與你相比,你是獨一無二的上帝。 23世上哪個民族比得上你的以色列子民呢?你從埃及救出他們,讓他們做你的子民,又彰顯你的大名,行神蹟奇事,把列國及其神明從你的以色列子民面前趕走。 24你讓以色列人永遠做你的子民,你耶和華做他們的上帝。

25「耶和華上帝啊,求你永遠信守你對僕人和僕人家的應許。 26這樣,你的名必永遠被尊崇,人們必說,『萬軍之耶和華是治理以色列的上帝。』願你僕人大衛的家在你面前堅立。 27以色列的上帝——萬軍之耶和華啊,因為你曾啟示僕人,說你要使我家世代為王,僕人才有勇氣這樣向你禱告。 28主耶和華啊,只有你是上帝,你的話真實可靠,你給了僕人美好的應許。 29現在求你賜福給僕人家,讓僕人家在你面前永續不斷。主耶和華啊,這些都是你的應許,願你永遠賜福給僕人家。」

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Samuẹli 7:1-29

Ìlérí Ọlọ́run si Dafidi

17.1-29: 1Ki 17.1-27.Ó sì ṣe, nígbà tí ọba ń gbé ní ilé rẹ̀, tí Olúwa sì fún un ní ìsinmi yíkákiri kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. 2Ọba sì wí fún Natani wòlíì pé, “Sá wò ó: èmi ń gbé inú ilẹ̀ tí a fi kedari kọ́, ṣùgbọ́n àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ń gbé inú ibi tí a fi aṣọ gé.”

3Natani sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”

Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọ̀ fún Dafidi láti kọ́ tẹmpili

4Ó sì ṣe ní òru náà, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Natani wá pé:

5“Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé. 6Nítorí pé, èmi kò ì ti gbé inú ilé kan láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ọmọ Israẹli gòkè ti ilẹ̀ Ejibiti wá, títí di òní yìí, ṣùgbọ́n èmi ti ń rìn nínú àgọ́, fún ibùgbé mi. 7Ní ibi gbogbo tí èmi ti ń rìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ǹjẹ́ èmi ti bá ọ̀kan nínú ẹ̀yà Israẹli, tí èmi pa àṣẹ fún láti máa bọ́ àwọn ènìyàn mi àní Israẹli, sọ̀rọ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi kedari kọ́ ilé fún mi.” ’

8“Ǹjẹ́, nítorí náà, báyìí ni ìwọ yóò sì wí fún ìránṣẹ́ mi àní Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ti mú ìwọ kúrò láti inú agbo àgùntàn wá láti má tẹ̀lé àwọn àgùntàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli. 9Èmi sì wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí ìwọ ń lọ, èmi sá à gé gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ, èmi sì ti sọ orúkọ rẹ di ńlá, gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá tí ó wà ní ayé. 10Èmi ó sì yan ibìkan fún àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi ó sì gbìn wọ́n, wọn ó sì má gbé bí ibùjókòó tiwọn, wọn kì yóò sì sípò padà mọ́; àwọn ọmọ ènìyàn búburú kì yóò sì pọ́n wọn lójú mọ́, bí ìgbà àtijọ́. 11Àti gẹ́gẹ́ bí àkókò ìgbà tí èmi ti fi àṣẹ fún àwọn onídàájọ́ lórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi fi ìsinmi fún ọ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ.

“ ‘Olúwa sì wí fún ọ pé Olúwa yóò kọ ilé kan fún ọ: 12Nígbà tí ọjọ́ rẹ bá pé, tí ìwọ ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ lékè lẹ́yìn rẹ, èyí tí ó ti inú rẹ jáde wá, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀. 13Òun ó sì kọ́ ilé fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ láéláé. 147.14: Hb 1.5.Èmi ó máa ṣe baba fún un, òun yóò sì máa jẹ́ ọmọ mi. Bí òun bá dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì fi ọ̀pá ènìyàn nà án, àti ìnà àwọn ọmọ ènìyàn. 15Ṣùgbọ́n àánú mi kì yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú un kúrò lọ́dọ̀ Saulu, tí èmi ti mú kúrò níwájú rẹ. 16A ó sì fi ìdílé rẹ àti ìjọba rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ títí láé: a ó sì fi ìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ títí láé.’ ”

17Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìran yìí, bẹ́ẹ̀ ni Natani sì sọ fún Dafidi.

Àdúrà Dafidi

18Dafidi ọba sì wọlé lọ, ó sì dúró níwájú Olúwa, ó sì wí pé:

Olúwa Olódùmarè, ta ni èmi, àti kí sì ni ìdílé mi, tí ìwọ fi mú mi di ìsinsin yìí? 19Nǹkan kékeré ni èyí sá à jásí lójú rẹ, Olúwa Olódùmarè; ìwọ sì ti sọ nípa ìdílé ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀lú ní ti àkókò tí o jìnnà. Èyí ha ṣe ìwà ènìyàn bí, Olúwa Olódùmarè?

20“Àti kín ní ó tún kù tí Dafidi ìbá tún máa wí fún ọ? Ìwọ, Olúwa Olódùmarè mọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. 21Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni ìwọ ṣe ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí, kí ìránṣẹ́ rẹ lè mọ̀.

22“Ìwọ sì tóbi, Olúwa Olódùmarè! Kò sì sí ẹni tí ó dàbí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan lẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí àwa fi etí wá gbọ́. 23Orílẹ̀-èdè kan wo ni ó sì ń bẹ ní ayé tí ó dàbí àwọn ènìyàn rẹ, àní Israẹli, àwọn tí Ọlọ́run lọ rà padà láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ̀, àti láti sọ wọ́n ní orúkọ, àti láti ṣe nǹkan ńlá fún un yín, àti nǹkan ìyanu fún ilé rẹ̀, níwájú àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ ti rà padà fún ara rẹ láti Ejibiti wá, àní àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn òrìṣà wọn. 24Ìwọ sì fi ìdí àwọn ènìyàn rẹ, àní Israẹli kalẹ̀ fún ara rẹ láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ títí láé; ìwọ Olúwa sì wá di Ọlọ́run fún wọn.

25“Ǹjẹ́, Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tí ìwọ sọ ní ti ìránṣẹ́ rẹ, àti ní ti ìdílé rẹ̀, kí ó dúró títí láé, kí ó sí ṣe bí ìwọ ti wí. 26Jẹ́ kí orúkọ rẹ ó ga títí láé, pé, ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run lórí Israẹli!’ Sì jẹ́ kí a fi ìdílé Dafidi ìránṣẹ́ rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ.

27“Nítorí pé ìwọ, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli ti sọ létí ìránṣẹ́ rẹ, pé, ‘Èmí ó kọ́ ilé kan fún ọ.’ Nítorí náà ni ìránṣẹ́ rẹ sì ṣe ní i lọ́kàn rẹ̀ láti gbàdúrà yìí sí ọ. 28Ǹjẹ́, Olúwa Olódùmarè, ìwọ ni Ọlọ́run náà, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ sì jásí òtítọ́, ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ nǹkan rere yìí fún ìránṣẹ́ rẹ. 29Ǹjẹ́, jẹ́ kí ó wù ọ́ láti bùkún ìdílé ìránṣẹ́ rẹ, kí ó wà títí láé níwájú rẹ: nítorí ìwọ, Olúwa Olódùmarè, ni ó ti sọ ọ́: sì jẹ́ kí ìbùkún wà ní ìdílé ìránṣẹ́ rẹ títí láé, nípasẹ̀ ìbùkún rẹ.”