啟示錄 17 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

啟示錄 17:1-18

大淫婦的下場

1拿著七碗的七位天使中有一位前來對我說:「你過來!我要讓你看那坐在眾水之上的大淫婦將要遭受的刑罰。 2地上的君王與她行淫,地上其他人也因喝了她淫亂的酒而酩酊大醉。」

3那時,我被聖靈感動,被天使帶到曠野,在那裡見到一個婦人騎著一隻朱紅色的怪獸。怪獸有七頭十角,渾身寫滿褻瀆上帝的名號。 4那婦人身穿紫色和朱紅色的袍子,用黃金、寶石及珍珠裝扮自己。她手中拿著金杯,裡面盛滿了她淫亂的污穢、可憎之物。 5在她額上還寫了一個神秘的名號:「大巴比倫——地上淫婦及可憎事物之母」。 6我又見她醉了,因她喝了眾聖徒的血,就是為耶穌做見證之人的血。

我看見她,非常驚奇。 7天使對我說:「你為什麼這樣驚奇呢?我要將這婦人和她騎的七頭十角怪獸的奧祕告訴你。 8你看見的這怪獸以前出現過,現今沒有出現,將來要從無底坑上來,然後走向滅亡。那些住在地上、自創世以來名字沒有記在生命冊上的人,都因見到這只從前出現過、現今沒有出現、將來會再出現的怪獸而感到驚奇。 9這裡需要智慧才能明白,牠的七個頭代表那婦人坐鎮的七座山,又代表七個王。 10其中五個已經衰亡,一個還在,另外一個還未來到,他來後只能短暫存留。 11那從前出現過、現今沒有出現的怪獸是第八個王,他是七個王之一,也要走向滅亡。 12你看見的那十個角象徵另外十個還沒有得勢的王,他們將取得王權和那怪獸一同統治短暫的一段時期。 13他們一致同意把自己所有的能力和權柄交給那怪獸。 14他們將與羔羊交戰,但羔羊必勝過他們,因為羔羊是萬主之主,萬王之王。那些跟隨羔羊的是被呼召、蒙揀選、忠心耿耿的人。」

15天使又對我說:「你看見的那淫婦所坐的眾水象徵來自各民族、各國家、各語言族群的人。 16怪獸和牠頭上的十角必憎恨那淫婦,使她赤身露體、景況淒涼。牠們要吃她的肉,最後用火將她燒盡。 17因為上帝使眾王定意這樣做,好完成祂的旨意。他們便同心將政權交給那怪獸,直到上帝的話得到實現。 18你看見的那婦人就是那掌管世上眾王的大城。」

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 17:1-18

Obìnrin àti ẹranko

117.1: Jr 51.13.Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje náà tí ó ní ìgò méje wọ̀n-ọn-nì sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín; èmi ó sì fi ìdájọ́ àgbèrè ńlá ní tí ó jókòó lórí omi púpọ̀ han ọ: 217.2: Isa 23.17; Jr 25.15-16.Ẹni tí àwọn ọba ayé bá ṣe àgbèrè, tí a sì fi ọtí wáìnì àgbèrè rẹ̀ pa àwọn tí ń gbé inú ayé.”

3Ó sì gbé mi nínú ẹ̀mí lọ sí aginjù: mo sì rí obìnrin kan ó jókòó lórí ẹranko aláwọ̀ òdòdó kan tí ó kún fún orúkọ ọ̀rọ̀-òdì, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. 417.4: Jr 51.7.A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ òdòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti perli ṣe é ní ọ̀ṣọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbèrè rẹ̀; 5àti níwájú rẹ̀ ni orúkọ kan tí a kọ:

ohun ìjìnlẹ̀ babeli ńlá

ìyá àwọn panṣágà

àti àwọn ohun ìríra ayé.

6Mo sì rí obìnrin náà mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ajẹ́rìí ikú Jesu ní àmuyó.

Nígbà tí mo sì rí i, ẹnu yà mi gidigidi. 7Angẹli sì wí fún mi pé, “Nítorí kí ni ẹnu ṣe yà ọ́? Èmi ó sọ ti ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ, àti ti ẹranko tí ó gùn, ti ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. 817.8: Da 7.3; If 3.5.Ẹranko tí ìwọ ri nì, o ti wà, kò sì ṣí mọ́: Yóò sì ti inú ọ̀gbun gòkè wá, yóò sì lọ sínú ìparun rẹ. Àwọn olùgbé ayé ti a kọ orúkọ wọn sínú ìwé iye láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, nígbà tí wọn ń wò ẹranko tí o ti wà, tí kò sì ṣí mọ́, tí ó sì ń bọ̀ wá, ẹnu si ya wọn.

9“Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà. Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó. 10Ọba méje sì ní wọn: àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé; nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú. 11Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì ṣí, òun náà sì ni ẹ̀kẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun.

1217.12: Da 7.20-24.“Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí ni ọba mẹ́wàá ni wọn, tí wọn kò ì ti gba ìjọba; ṣùgbọ́n wọn gba àṣẹ bí ọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan. 13Àwọn wọ̀nyí ní inú kan, wọ́n yóò sì fi agbára àti ọlá wọn fún ẹranko náà. 1417.14: Da 2.47.Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́-Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn: nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti ọba àwọn ọba: Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtítọ́ yóò sì ṣẹ́gun pẹ̀lú.”

15Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn omi tí ìwọ ti rí ni, níbi tí àgbèrè náà jókòó, àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti orílẹ̀ àti onírúurú èdè ni wọ́n. 16Àti ìwo mẹ́wàá tí ìwọ rí, àti ẹranko náà, àwọn wọ̀nyí ni yóò kórìíra àgbèrè náà, wọn ó sì sọ ọ́ di ahoro àti ẹni ìhòhò, wọn ó sì jẹ ẹran-ara rẹ̀, wọn ó sì fi iná sun ún pátápátá. 17Nítorí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn wọn láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, láti ní inú kan, àti láti fi ìjọba wọn fún ẹranko náà, títí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi ṣẹ 18Obìnrin tí ìwọ rí ní ìlú ńlá ni, tí ń jẹ ọba lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.”