創世記 39 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

創世記 39:1-23

約瑟遭陷害

1約瑟以實瑪利商人帶到埃及,賣給了法老的內臣護衛長波提乏2約瑟住在他的埃及主人家中,耶和華與他同在,使他凡事亨通。 3他主人看出耶和華與他同在,使他凡事亨通, 4就賞識他,讓他服侍自己,派他管理自己家中一切事務。 5自從埃及波提乏約瑟管理自己家中一切事務以後,耶和華因為約瑟的緣故而賜福他主人家,使他主人家裡和田間的一切都蒙福。 6於是,波提乏把一切事都交給約瑟管理,除了自己要吃的食物以外,什麼也不管。

約瑟體格健壯,相貌英俊。 7後來,波提乏的妻子看中了約瑟,向他眉目傳情,要引誘他上床。 8約瑟拒絕了她,說:「我主人信任我,把家裡一切事都交給我管理。 9在這家裡,沒有人比我權力更大了,我主人把一切都交給了我,唯獨你除外,因為你是他的妻子。我怎能做這種醜事得罪上帝呢?」 10但她還是每天勾引約瑟約瑟不從,並儘量避開她。

11一天,約瑟進屋裡辦事,那時屋裡沒有其他人。 12波提乏的妻子抓住約瑟的外衣,硬要與他上床。約瑟丟下外衣擺脫她逃了出去。 13她見約瑟丟下外衣逃了出去, 14就叫來家裡的人,對他們說:「你們看,我丈夫帶回家的這個希伯來人戲弄我們!他進來要與我上床,我就大聲呼喊, 15他聽見我大聲喊叫,就把衣服丟在我這裡,逃了出去。」 16她把約瑟的外衣留在身邊,等她丈夫回來後, 17就對他說:「你帶回來的那個希伯來人進來要戲弄我, 18我大聲喊叫,他就把衣服丟在我這裡,逃了出去。」

19波提乏聽了妻子講述約瑟如何對待她之後,勃然大怒, 20約瑟關進王囚禁犯人的監牢。 21約瑟坐牢的時候,耶和華與他同在,恩待他,使監獄長賞識他。 22監獄長把獄中所有囚犯及一切事務都交給約瑟管理。 23凡交到約瑟手中的事情,監獄長都很放心,因為耶和華與約瑟同在,使他凡事亨通。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 39:1-23

Josẹfu àti aya Potiferi

139.1,2,21: Ap 7.9.Nígbà tí wọ́n mú Josẹfu dé Ejibiti, Potiferi, ará Ejibiti tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Farao. Òun ni olórí àwọn ọmọ-ogun Farao. Ó ra Josẹfu lọ́wọ́ àwọn ará Iṣmaeli tí wọ́n mú un lọ síbẹ̀.

2Olúwa sì wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì bùkún un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará Ejibiti. 3Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé. 4Josẹfu sì rí ojúrere Potiferi, ó sì di aṣojú rẹ̀, Potiferi fi Josẹfu ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. 5Láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará Ejibiti nítorí Josẹfu. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Potiferi ní, nílé àti lóko. 6Ó sì fi Josẹfu ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu ṣe àkóso ilé e rẹ̀.

Josẹfu sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀, 7lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!”

8Ṣùgbọ́n Josẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́. 9Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?” 10Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Josẹfu, Josẹfu kọ̀ láti bá a lòpọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà.

11Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí. 12Ó sì di aṣọ Josẹfu mú, ó sì wí pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n Josẹfu fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì sá jáde.

13Nígbà tí ó rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ó sì ti sá jáde, 14ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Heberu kan wọlé tọ̀ wá wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lòpọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe. 15Nígbà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sókè, tí mo sì kígbe, ó jọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sọ́dọ̀ mi, ó sì sá, ó bọ́ sóde.”

16Ó sì fi aṣọ náà sọ́dọ̀ títí tí ọkọ rẹ̀ fi dé. 17Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará Heberu tí o rà wá ilé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lòpọ̀. 18Ṣùgbọ́n bí mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sá kúrò nínú ilé.”

19Nígbà tí Potiferi gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi. 20Ó sì ju Josẹfu sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí.

Ṣùgbọ́n, nígbà tí Josẹfu wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀, 2139.21: Ap 7.9.Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ṣàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n (wọ́dà). 22Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi Josẹfu ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń ṣe níbẹ̀. 23Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso Josẹfu, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé.