利未記 1 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

利未記 1:1-17

獻燔祭的條例

1耶和華在會幕裡呼喚摩西,對他說: 2「你把以下條例告訴以色列人。

「如果你們有人獻祭給耶和華,要用牛羊作祭物。 3如果用牛作燔祭,必須用毫無殘疾的公牛,在會幕門口獻上,便可蒙耶和華悅納。 4獻祭者要把手放在牛頭上,所獻的燔祭便蒙悅納,為他贖罪。 5他要在耶和華面前宰牛,然後祭司——亞倫的子孫要把牛血灑在會幕門口的祭壇四周。 6獻祭者要剝掉牛皮,把牛切成塊。 7祭司——亞倫的子孫要在祭壇上生火,把木柴擺在火上, 8然後將肉塊、頭顱和脂肪都擺在祭壇燃燒的木柴上。 9獻祭者要用水洗淨牛的內臟和腿。祭司要把這一切都放在壇上焚燒。這是燔祭,是蒙耶和華悅納的馨香火祭。

10「如果用綿羊或山羊作燔祭,必須用毫無殘疾的公羊。 11獻祭者要在祭壇北面,在耶和華面前宰羊。祭司——亞倫的子孫要把羊血灑在祭壇四周。 12獻祭者將羊切成塊後,祭司要把肉塊、頭顱和脂肪擺在祭壇燃燒的木柴上。 13獻祭者要用水洗淨羊的內臟和腿。祭司要把這一切都放在壇上焚燒。這是燔祭,是蒙耶和華悅納的馨香火祭。

14「如果有人用鳥作燔祭,要用斑鳩或雛鴿。 15祭司要把鳥帶到祭壇前,擰下鳥頭,放在祭壇上焚燒;要在祭壇旁放盡鳥血; 16要除掉鳥的嗉子和羽毛,丟在祭壇東邊倒灰的地方。 17祭司要抓著兩個翅膀把鳥撕開,但不可撕斷,然後把鳥放在壇上焚燒。這是燔祭,是蒙耶和華悅納的馨香火祭。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 1:1-17

Ọrẹ ẹbọ sísun

1Olúwa sì pe Mose, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú àgọ́ àjọ. Ó wí pé; 2“Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sì wí fún wọn pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, kí ọrẹ ẹbọ yín jẹ́ ẹran ọ̀sìn láti inú agbo ẹran tàbí láti inú ọ̀wọ́ ẹran.

3“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú agbo ẹran kí òun kí ó mú akọ màlúù tí kò lábùkù. Ó sì gbọdọ̀ mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ kí ó ba à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú Olúwa 4kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹbọ sísun náà yóò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò o rẹ̀, yóò sì jẹ́ ètùtù fún un. 5Kí ó pa ọ̀dọ́ akọ màlúù náà níwájú Olúwa, lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà tí í ṣe ọmọ Aaroni yóò gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà yí pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ ká. 6Òun yóò bó awọ ara ẹbọ sísun náà, òun yóò sì gé e sí wẹ́wẹ́. 7Àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò fi iná sí orí pẹpẹ, wọn yóò sì to igi sórí pẹpẹ náà. 8Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò tó ègé ẹran náà, pẹ̀lú orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ. 9Kí ó fi omi sàn nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ, ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.

10“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú ọ̀wọ́ ẹran, láti ara àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ tàbí àgùntàn, kí ó mú akọ tí kò lábùkù, 11kí ó pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Olúwa, kí àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà ká 12Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, kí àlùfáà sì to ègé ẹran náà; orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ. 13Kí ó fi omi ṣan nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì gbé gbogbo rẹ̀ wá láti sun lórí pẹpẹ. Ó jẹ́ ẹbọ sísun tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.

14“ ‘Bí ó bá sì ṣe pé ti ẹyẹ ni ẹbọ sísun ọrẹ ẹbọ rẹ̀ sí Olúwa, ǹjẹ́ kí ó mú ọrẹ ẹbọ rẹ̀ wá nínú àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé 15Kí àlùfáà mu wá sí ibi pẹpẹ, kí ó yín in lọ́rùn, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, kí ó sì ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 16Kí ó yọ àjẹsí (àpò oúnjẹ) ẹyẹ náà pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, kí ó gbe lọ ṣí apá ìlà-oòrùn pẹpẹ níbi tí eérú wà 17Kí ó gbá apá rẹ̀ méjèèjì mú, kí ó fà á ya, ṣùgbọ́n kí ó má ya á tan pátápátá. Lẹ́yìn náà ni àlùfáà yóò sun ún lórí igi tí ó ń jó lórí pẹpẹ, ẹbọ sísun ni ọrẹ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.