列王紀下 5 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

列王紀下 5:1-27

以利沙醫治乃縵

1乃縵亞蘭王的元帥,甚得亞蘭王器重,因為耶和華藉他使亞蘭人打了許多勝仗。他是英勇的戰士,只是患了痲瘋病。 2亞蘭人襲擊以色列時,曾擄回一個以色列少女,這少女做了乃縵妻子的婢女。 3有一天,她對主母說:「要是我主人去見撒瑪利亞的那位先知就好了!他一定能治好我主人的痲瘋病。」 4乃縵把這以色列少女的話告訴亞蘭王。 5亞蘭王說:「你去吧。我會寫信給以色列王的。」於是,乃縵帶了三百四十公斤銀子、七十公斤金子和十套衣服,啟程前往以色列6他帶給以色列王的信上寫著:「謹以此信介紹我的臣僕乃縵到你那裡,你要醫好他的痲瘋病。」 7以色列王讀完信後,就撕裂衣服說:「難道我是上帝嗎?我能操縱人的生死嗎?這人竟叫我醫好一個人的痲瘋病!他只是想找藉口攻打我。」

8上帝的僕人以利沙聽說以色列王撕裂了衣服,便派人去對王說:「你為什麼撕裂衣服呢?讓那人到我這裡來,我要讓他知道以色列有先知。」 9乃縵帶領車輛和馬匹到了以利沙的家,站在門口。 10以利沙派使者出去對乃縵說:「你到約旦河裡洗七次,你的皮膚就會復原,並得到潔淨。」 11乃縵卻怒沖沖地走了。他說:「我以為他一定會出來見我,為我站著求告他的上帝耶和華,用手在我的患處晃一晃,醫好我的痲瘋病。 12大馬士革亞波納河和法爾法河不比以色列所有的河都好嗎?難道我在那裡洗就不能得到潔淨嗎?」於是,他怒沖沖地轉身走了。 13他的僕人上前對他說:「我父啊,先知若吩咐你做一件大事,難道你會不去做嗎?何況他只是說你去洗洗就可以潔淨!」 14乃縵就去約旦河,照上帝僕人的話在河裡洗了七次,便潔淨了,皮膚變得像小孩子的一樣。

15乃縵率領全體隨從回到上帝的僕人那裡,站在他面前說:「如今我才知道,除了以色列,普天下沒有上帝。請你收下僕人的禮物。」 16以利沙說:「我憑我事奉的永活上帝起誓,我決不接受。」乃縵再三請求,他仍不肯接受。 17乃縵說:「如果你不肯接受禮物,請你容許僕人用兩頭騾子馱些泥土回去。從此以後,我不再獻燔祭或平安祭給其他神明,只獻給耶和華。 18但有一件事,願耶和華饒恕僕人。我主人進入臨門廟祭拜時,他會扶著我的手,這樣我也得隨著他彎腰。若我在臨門廟裡彎腰,願耶和華饒恕我。」 19以利沙對他說:「你安心地走吧。」

20乃縵剛走不遠,上帝僕人以利沙的僕人基哈西心想:「我主人沒有收亞蘭乃縵帶來的禮物就讓他走了。我憑永活的耶和華起誓,我一定要追上去,向他要點東西。」 21他便去追趕乃縵乃縵見後面有人趕來,就下車迎接他,問他:「一切都好嗎?」 22基哈西答道:「一切都好。我主人派我來告訴你,剛才有兩位年輕的先知從以法蓮山區來見他,請你賜給他們三十四公斤銀子和兩套衣服。」 23乃縵說:「請你拿走六十八公斤銀子吧!」並再三請他接受,然後把六十八公斤銀子裝進兩個袋子,連同兩套衣服,交給他的兩個僕人抬走,基哈西跟在他們後面。 24到了山岡,基哈西接過銀子和衣服,放進屋裡,便讓他們回去了。 25基哈西進去侍立在以利沙面前,以利沙問他:「基哈西,你剛才去哪裡了?」基哈西答道:「僕人哪裡也沒有去。」 26以利沙對他說:「那人下車回頭迎接你的時候,我的心不也在那裡嗎?現在豈是接受人家銀子、衣服、橄欖園、葡萄園、牛羊和僕婢的時候? 27因此,你和你的後代會永遠沾染乃縵的痲瘋病。」基哈西離開以利沙時,患了痲瘋病,皮膚像雪一樣白。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 5:1-27

Ìwòsàn Naamani adẹ́tẹ̀

1Naamani jẹ́ olórí ogun ọba Aramu. Ó jẹ́ ènìyàn ńlá níwájú ọ̀gá rẹ̀, wọ́n sì bu ọlá fún un, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni Olúwa ti fi ìṣẹ́gun fún Aramu. Òun jẹ́ alágbára, akọni ọkùnrin ṣùgbọ́n, ó dẹ́tẹ̀.

2Nísinsin yìí ẹgbẹgbẹ́ láti Aramu ti jáde lọ láti mú ọmọ obìnrin kékeré kan ní ìgbèkùn láti Israẹli, ó sì sin ìyàwó Naamani. 3Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samaria! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

4Naamani lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Israẹli ti sọ. 5“Ní gbogbo ọ̀nà, lọ,” ọba Aramu dá a lóhùn pé, “Èmi yóò fi ìwé ránṣẹ́ sí ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni Naamani lọ, ó sì mú pẹ̀lú rẹ̀ tálẹ́ǹtì fàdákà mẹ́wàá, ẹgbẹ̀ta ìwọ̀n wúrà (6,000) àti ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá. 6Ìwé tí ó mú lọ sọ́dọ̀ ọba Israẹli kà pé: “Pẹ̀lú ìwé yìí èmi ń rán ìránṣẹ́ mi Naamani sí ọ pé o lè wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

7Bí ọba Israẹli ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí ààyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo ààrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!”

8Nígbà tí Eliṣa ènìyàn Ọlọ́run gbọ́ pé ọba Israẹli ti ya aṣọ rẹ̀, ó sì rán iṣẹ́ yìí sí i pé: “Kí ni ó dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Jẹ́ kí ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi. Òun yóò sì mọ̀ pé wòlíì wà ní Israẹli.” 9Bẹ́ẹ̀ ni Naamani sì lọ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀ àti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé Eliṣa. 10Eliṣa rán ìránṣẹ́ láti lọ sọ fún un pé, “Lọ, wẹ̀ ara rẹ ní ìgbà méje ní odò Jordani, ẹran-ara rẹ yóò sì tún padà bọ̀ sípò, ìwọ yóò sì mọ́.”

11Ṣùgbọ́n Naamani lọ pẹ̀lú ìbínú ó sì wí pé, “Mo lérò pé yóò sì dìde jáde wá nítòótọ́ sí mi, yóò sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run, fi ọwọ́ rẹ̀ lórí ibẹ̀ kí ó sì wo ẹ̀tẹ̀ mi sàn. 12Abana àti Fapari, odò Damasku kò ha dára ju gbogbo omi Israẹli lọ? Ṣé èmi kò le wẹ̀ nínú wọn kí n sì mọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà, ó sì lọ pẹ̀lú ìrunú.

13Ìránṣẹ́ Naamani lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi, tí wòlíì bá ti sọ fún ọ láti ṣe ohun ńlá kan, ṣé ìwọ kì bá ti ṣe, mélòó mélòó nígbà náà, nígbà tí ó sọ fún ọ pé, ‘Wẹ̀ kí o sì mọ́’!” 14Bẹ́ẹ̀ ni ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ ó sì tẹ ara rẹ̀ bọ inú odò Jordani ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún un, ẹran-ara rẹ̀ sì tún padà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kékeré.

15Nígbà náà Naamani àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ padà lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Ó sì dúró níwájú rẹ̀ ó sì wí pé, “Nísinsin yìí èmi mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run ní gbogbo àgbáyé àyàfi ní Israẹli nìkan. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn láti ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ.”

16Wòlíì náà dáhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ẹni tí mo ń sìn, èmi kò nígbà ohun kan,” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Naamani rọ̀ ọ́ láti gbà á, ó kọ̀.

17Naamani wí pé, “Tí o kò bá nígbà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí a fi fún èmi ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ẹrù erùpẹ̀ tí ìbáaka méjì le rù, nítorí láti òní lọ ìránṣẹ́ rẹ kì yóò rú ẹbọ sísun àti rú ẹbọ sí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́run mìíràn mọ́ bí kò ṣe sí Olúwa. 18Ṣùgbọ́n kí Olúwa kí ó dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún nǹkan yìí: Nígbà tí ọ̀gá mi wọ inú ilé Rimoni láti fi orí balẹ̀ tí ó sì fi ara ti ọwọ́ mi tí mo sì tẹ ara mi ba pẹ̀lú níbẹ̀. Nígbà tí èmi tẹ ara mi ba ní ilé Rimoni, kí Olúwa dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún èyí.”

19Eliṣa wí pé, “Máa lọ ní àlàáfíà.”

Lẹ́yìn ìgbà tí Naamani tí rin ìrìnàjò tí ó jìnnà, 20Gehasi, ìránṣẹ́ Eliṣa ènìyàn Ọlọ́run, ó wí fún ara rẹ̀ pé, “Ọ̀gá mi jẹ́ ẹni tí ó rọ́nú lórí Naamani, ará Aramu, nípa pé kò gba ohunkóhun ní ọwọ́ rẹ̀ ohun tí ó mú wá, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, èmi yóò sá tẹ̀lé e èmi yóò sì gba ohun kan ní ọwọ́ rẹ̀.”

21Bẹ́ẹ̀ ni Gehasi sáré tẹ̀lé Naamani. Nígbà tí Naamani rí i tí ó ń sáré tẹ̀lé e, ó sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ̀. “Ṣé gbogbo nǹkan wà dáradára?” ó béèrè.

22“Gbogbo nǹkan wà dáradára,” Gehasi dá a lóhùn. “Ọ̀gá mi rán mi láti sọ wí pé, ‘Àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin méjì láti ọ̀dọ̀ ọmọ wòlíì wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi láti orí òkè ìlú ti Efraimu. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ẹ̀bùn fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ méjì.’ ”

23Naamani wí pé, “Ní gbogbo ọ̀nà, mú ẹ̀bùn méjì.” Ó sì rọ Gehasi láti gbà wọ́n, ó sì di ẹ̀bùn méjì náà ti fàdákà ní inú àpò méjì, pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì, wọ́n sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ Gehasi. 24Nígbà tí Gehasi sì dé ibi ilé ìṣọ́, ó gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn, ó sì tó wọ́n sínú ilé, ó sì jọ̀wọ́ àwọn ọkùnrin náà lọ́wọ́ lọ, wọ́n sì jáde lọ. 25Nígbà náà ó sì wọlé wá ó sì dúró níwájú ọ̀gá rẹ̀ Eliṣa.

“Níbo ni o ti wà Gehasi?” Eliṣa béèrè.

“Ìránṣẹ́ rẹ kò lọ sí ibìkan kan.” Gehasi dá a lóhùn.

26Ṣùgbọ́n Eliṣa wí fún un pé, “Ẹ̀mí mi kò ha wà pẹ̀lú rẹ nígbà tí ọkùnrin náà sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ? Ṣé àsìkò tí ó yẹ láti gba owó nìyìí, tàbí láti gba aṣọ, ọgbà olifi, ọgbà àjàrà, àgùntàn, màlúù tàbí ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin? 27Ẹ̀tẹ̀ Naamani yóò lẹ̀ mọ́ ọ àti sí irú-ọmọ rẹ títí láé.” Nígbà náà Gehasi kúrò níwájú Eliṣa, ó sì di adẹ́tẹ̀, ó sì funfun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.