以斯拉記 3 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

以斯拉記 3:1-13

重建祭壇

1到了七月,以色列人已安居各城,他們萬眾一心地聚集在耶路撒冷2約薩達的兒子耶書亞及其他祭司、撒拉鐵的兒子所羅巴伯及其親屬,一起重新築造以色列上帝的祭壇,為要照上帝的僕人摩西在律法書上的記載在壇上獻燔祭。 3他們雖然懼怕當地的居民,還是在原來的根基上重建祭壇,並早晚在上面向耶和華獻燔祭。 4他們照律法書的記載守住棚節,每天按規定的數目獻上燔祭。 5之後,他們獻上日常的燔祭,並在朔日3·5 朔日」即每月初一。和耶和華所定的一切節期獻祭,又向耶和華獻上自願獻的祭。 6儘管耶和華殿的根基還沒有立好,從七月一日起,他們就開始向耶和華獻燔祭。 7他們付給石匠和木匠銀子,並經波斯塞魯士批准,供給泰爾人和西頓人食物、酒和油,換取他們把香柏木從黎巴嫩經海路運到約帕

開始重建聖殿

8在回到耶路撒冷上帝殿的第二年二月,撒拉鐵的兒子所羅巴伯約薩達的兒子耶書亞及其祭司和利未親族,以及所有從流亡之地回到耶路撒冷的人,開始重建耶和華的殿,並派二十歲以上的利未人做督工。 9何達威雅3·9 何達威雅」希伯來文是「猶大」,參考2·40的後裔,即耶書亞及其子孫和弟兄、甲篾及其子孫,與利未希拿達的子孫及其弟兄同心協力地監督在上帝殿裡做工的人。

10工人立耶和華殿的根基時,祭司身穿禮服拿著號角,利未亞薩的子孫拿著鈸各就各位,照以色列大衛所定的規矩讚美耶和華。 11他們彼此唱和,讚美、稱謝耶和華,說:

「祂是美善的,

因為祂向以色列人永施慈愛!」

所有人都高聲歡呼讚美耶和華,因為耶和華殿的根基已經立好。 12許多曾見過舊殿的年長的祭司、利未人和族長看見這殿的根基,不禁放聲大哭,也有很多人高聲歡呼。 13人們無法分辨是痛哭聲還是歡呼聲,因為眾人都大聲呼喊,聲音傳到遠處。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esra 3:1-13

Títún pẹpẹ kọ́

1Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Israẹli sì ti wà nínú àwọn ìlú wọn, àwọn ènìyàn péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ní Jerusalẹmu. 23.2: El 27.1.Nígbà náà ni Jeṣua ọmọ Josadaki àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti àwọn ènìyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ pẹpẹ Ọlọ́run Israẹli láti rú ẹbọ sísun níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a ti kọ sínú ìwé òfin Mose ènìyàn Ọlọ́run 3Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ẹ̀rù àwọn ènìyàn tí ó yí wọn ká ń bà wọ́n síbẹ̀, wọ́n kọ́ pẹpẹ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ sí Olúwa, ọrẹ àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́. 4Nígbà náà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ, wọ́n ṣe àjọ àgọ́ ìpàdé pẹ̀lú iye ẹbọ sísun tí a fi lélẹ̀ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. 5Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àtìgbàdégbà, ẹbọ oṣù tuntun àti gbogbo àwọn ẹbọ fún gbogbo àpèjẹ tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, àti àwọn tí a mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá fún Olúwa. 6Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní rú ẹbọ sísun sí Olúwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ì tí ì fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀.

Títún tẹmpili kọ́

7Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ní owó, wọ́n sì tún fi oúnjẹ, ohun mímu àti òróró fún àwọn ará Sidoni àti Tire, kí wọ́n ba à le è kó igi kedari gba ti orí omi Òkun láti Lebanoni wá sí Joppa, gẹ́gẹ́ bí Kirusi ọba Persia ti pàṣẹ.

8Ní oṣù kejì ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti padà dé sí ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Jeṣua ọmọ Josadaki àti àwọn arákùnrin yòókù (àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti gbogbo àwọn tí ó ti ìgbèkùn dé sí Jerusalẹmu) bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Wọ́n sì yan àwọn ọmọ Lefi tí ó tó ọmọ-ogun ọdún sókè láti máa bojútó kíkọ́ ilé Olúwa. 9Jeṣua àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti Kadmieli àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ Juda (àwọn ìran Hodafiah) àti àwọn ọmọ Henadadi àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn—gbogbo ará Lefi—parapọ̀ láti bojútó àwọn òṣìṣẹ́ náà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí í kíkọ́ ilé Ọlọ́run.

10Nígbà tí àwọn ọ̀mọ̀lé gbé ìpìlẹ̀ ilé Olúwa kalẹ̀, àwọn àlùfáà nínú aṣọ iṣẹ́ àlùfáà wọn pẹ̀lú fèrè, àti àwọn ará Lefi (àwọn ọmọ Asafu) pẹ̀lú símbálì, dúró ní ipò wọn láti yin Olúwa, bí Dafidi ọba Israẹli ti fi lélẹ̀. 11Pẹ̀lú ìyìn àti ọpẹ́ ni wọ́n kọrin sí Olúwa:

“Ó dára;

ìfẹ́ rẹ̀ sí Israẹli dúró títí láé.”

Gbogbo àwọn ènìyàn sì fi ohùn ariwo ńlá yin Olúwa, nítorí tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀. 12Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbà àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti àwọn olórí ìdílé, tí ó ti rí tẹmpili Olúwa ti tẹ́lẹ̀, wọ́n sọkún kíkorò nígbà tí wọ́n rí ìpìlẹ̀ tẹmpili Olúwa yìí tí wọ́n fi lélẹ̀, nígbà tí ọ̀pọ̀ kígbe fún ayọ̀. 13Kò sí ẹni tí ó le mọ ìyàtọ̀ láàrín igbe ayọ̀ àti ẹkún, nítorí tí ariwo àwọn ènìyàn náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. Wọ́n sì gbọ́ igbe náà ní ọ̀nà jíjìn réré.