Chinese Contemporary Bible (Traditional)

路得記 4:1-22

波阿斯娶路得

1波阿斯來到城門口,坐在那裡,恰巧看見他所說的那位至親經過,便招呼他說:「某人啊,請過來坐一坐。」那人便走過來坐下。 2波阿斯又邀請了城裡的十位長老,對他們說:「請過來坐一坐。」他們都坐下以後, 3波阿斯便對那位至親說:「拿俄米摩押回來了,現在要賣我們族兄以利米勒的那塊地, 4我想應該讓你知道這件事。你最有權贖那塊地,其次才是我,此外再沒有別人了。如果你願意贖回那塊地,希望你當著在座各位長老的面表明。如果不願意,請你讓我知道。」那人說:「我願意贖。」 5波阿斯說:「那麼,你從拿俄米手中買地的那天,也要娶已死之人的妻子摩押女子路得,好讓死者繼續在產業上留名。」 6那位至親說:「那我就不能贖了,免得損害到我的產業。你來贖吧,我不能贖。」

7從前在以色列,買贖或交易有這樣的規矩:一旦成交,一方要把鞋脫下來交給另一方,以色列人以此為成交的憑據。 8那位至親對波阿斯說:「你自己買吧!」他就把鞋子脫了下來。 9波阿斯向長老和所有在場的人說:「請各位今天為我作證,所有屬於以利米勒基連瑪倫的產業,我都從拿俄米手上買了。 10同時,我要娶瑪倫的遺孀摩押女子路得為妻,好使死者繼續在產業上留名,免得他的名在本族本鄉中消失。今天,請各位作證。」 11聚集在城門口的眾人和長老都說:「我們願意作證。願耶和華使要進你家門的這女子,像建立以色列家的拉結利亞一樣。願你在以法他家業興隆,在伯利恆聲名遠播。 12願耶和華藉著這年輕女子賜你後裔,使你家像先祖猶大她瑪的兒子法勒斯家一樣。」

13這樣,波阿斯便娶了路得為妻,與她同房。耶和華使她懷孕生了一個兒子。 14婦女們對拿俄米說:「耶和華當受稱頌!因為今日祂賜給你一位至親,使你後繼有人,願這孩子在以色列得享盛名! 15他必讓你的生命重新得力,奉養你,使你安度晚年,因為他是愛你的兒媳婦所生的。有這兒媳婦比有七個兒子還要好!」 16拿俄米接過嬰孩抱在懷中,照顧他。 17鄰居的婦女們喊著說:「拿俄米有孩子了!」她們給孩子取名叫俄備得,這俄備得就是耶西的父親,耶西大衛的父親。

18以下是法勒斯的家譜:法勒斯希斯崙19希斯崙亞米拿達20亞米拿達拿順拿順撒門21撒門波阿斯波阿斯俄備得22俄備得耶西耶西大衛

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Rutu 4:1-22

Boasi gbé Rutu ní ìyàwó

1Nígbà náà ni Boasi gòkè lọ sí ẹnu ibodè ìlú, ó sì jókòó síbẹ̀. Nígbà tí ìbátan tí ó súnmọ́ Elimeleki jùlọ, arákùnrin tí Boasi ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń kọjá, Boasi pè é wí pé, “Máa bọ̀ wá síbí ìwọ ọ̀rẹ́ mi, kí o sì jókòó.” Ó sì lọ jókòó.

2Boasi sì pe mẹ́wàá nínú àwọn àgbàgbà ìlú, wí pé ki wọn jókòó, wọn sí ṣe bẹ́ẹ̀, 3ó sì sọ fún ìbátan rẹ̀ náà pé, “Arábìnrin Naomi tí ó dé láti ilẹ̀ Moabu fẹ́ ta ilẹ̀, èyí tí ó ṣe ti arákùnrin Elimeleki wa. 4Mó sì rò wí pé ó yẹ kí n mú ọ̀rọ̀ náà wá sí etí ìgbọ́ rẹ, wí pé kí o rà á ní iwájú gbogbo àwọn tí ó jókòó sí ibi yìí. Bí ìwọ yóò bá rà á padà rà á. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ní rà á padà, sọ fún mi, kí èmi ó le è mọ̀. Nítorí pé kò sí ẹlòmíràn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á ju ìwọ lọ, èmi sì ni ẹni tí ó tún kàn lẹ́yìn rẹ̀.”

Ọkùnrin náà sì sọ wí pé, “Èmi yóò rà á padà.”

5Nígbà náà ni Boasi sọ wí pé, “Bí ìwọ bá ti ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Naomi àti lọ́wọ́ Rutu ará Moabu, ìwọ gbọdọ̀ fẹ́ opó ọkùnrin náà, kí orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà má ba à parẹ́ pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ àti kí o le è bímọ ní orúkọ rẹ̀.”

6Nígbà náà ni ọkùnrin náà dáhùn sí èyí pé, “Nípa ti èyí, èmi kò le è rà á padà, nítorí pé, ọmọ rẹ̀, ọkùnrin yóò wá jẹ́ ajogún àwọn ohun ìní mi pẹ̀lú. Rà á fún ara rẹ, èmi kò le ṣe é.”

74.7: De 25.8-10.Ní ayé ìgbàanì, kí a tó le sọ wí pé ohun ìràpadà tàbí pàṣípàrọ̀ ohun ìní fi ìdí múlẹ̀ ní ilẹ̀ Israẹli, ẹnìkan ni láti yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó sì fi fún ẹnìkejì, ó jẹ́ òfin fún ẹni tí ó fẹ́ rà á. Nípa ṣíṣe èyí, àwọn ará Israẹli fihàn wí pé ọ̀rọ̀ náà ti fìdímúlẹ̀.

8Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin náà sọ fún Boasi wí pé, “Ìwọ rà á fúnrarẹ̀,” ó yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

9Nígbà náà ni Boasi wí fún àwọn àgbàgbà àti àwọn mìíràn tí ó wà ní ibẹ̀ pé, “Gbogbo yín jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní òní wí pé mo ti ra ohun gbogbo tí í ṣe ti Elimeleki àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì: Maloni àti Kilioni lọ́wọ́ Naomi. 10Ní àfikún, mo ra Rutu ará Moabu opó Maloni padà láti di aya mi. Èyí tí yóò mú kí orúkọ ọkùnrin òkú náà wà pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀, kí ìran rẹ̀ má ba à lè parẹ́ láàrín àwọn ẹbí rẹ̀ àti ìlú rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ní òní.”

11Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí, kí Olúwa jẹ́ kí obìnrin tí ó ń bọ̀ wá sí inú ilẹ̀ rẹ dàbí Rakeli àti Lea láti ara àwọn ẹni tí gbogbo ìdílé Israẹli ti jáde wá. Kí ìwọ sì di ọlọ́rọ̀ ní ìran Efrata àti olókìkí ní ìlú Bẹtilẹhẹmu. 12Olúwa fún ọ ní ọmọ tí yóò mú ìdílé rẹ dàbí ti Peresi ọmọkùnrin tí Tamari bí fún Juda láti ipasẹ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin yìí.”

Èyí ni ìran Dafidi

13Báyìí ni Boasi ṣe mú Rutu, tí ó sì di aya rẹ̀. Nígbà náà ni ó wọlé tọ aya rẹ̀, Olúwa sì mú kí ó lóyún, ó sì bí ọmọ ọkùnrin kan. 14Àwọn obìnrin sì wí fún Naomi pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí kò fi ọ sílẹ̀ ní òní yìí láìní ìbátan, Olùràpadà. Kí ọmọ náà di olókìkí ní Israẹli. 15Yóò tún ayé rẹ ṣe, yóò sì dáàbò bò ọ́ ní ọjọ́ ogbó rẹ. Nítorí pé ìyàwó ọmọ rẹ, èyí tí ó sàn fún ọ ju ọmọkùnrin méje lọ, tí ó sì fẹ́ràn rẹ ni ó bí ọmọ yìí fún.”

16Naomi sì gbé ọmọ náà lé orí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. 17Àwọn obìnrin àdúgbò sì wí pé, “A bí ọmọkùnrin kan fún Naomi.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Obedi. Òun sì ni baba Jese tí í ṣe baba Dafidi.

18Èyí ni ìran Peresi:

Peresi ni baba Hesroni,

19Hesroni ni baba Ramu,

Ramu ni baba Amminadabu

20Amminadabu ni baba Nahiṣoni,

Nahiṣoni ni baba Salmoni,

21Salmoni ni baba Boasi,

Boasi ni baba Obedi,

22Obedi ní baba Jese,

Jese ni baba Dafidi.