Chinese Contemporary Bible (Traditional)

彌迦書 1:1-16

1猶大約坦亞哈斯希西迦執政期間,耶和華把祂的話傳給了摩利沙彌迦。他看到了有關撒瑪利亞耶路撒冷的異象。

審判將臨

2萬民啊,

你們都要聽!

大地和地上的萬物啊,

你們要側耳傾聽!

主耶和華從祂的聖殿裡作證指控你們。

3看啊,耶和華離開祂的居所,

從天降臨,

腳踏大地的高處。

4群山在祂腳下熔化,

猶如火中的蠟;

山谷崩裂,

岩石如水沿山坡傾瀉。

5這一切都是因為雅各的叛逆,

以色列家的罪惡。

雅各的叛逆在哪裡呢?

豈不是在撒瑪利亞嗎?

猶大的邱壇在哪裡呢?

豈不是在耶路撒冷嗎?

6「所以,我耶和華要使撒瑪利亞淪為荒野的廢墟,

成為種葡萄的地方。

我要把她的石頭拋進山谷,

直到露出她的根基。

7她所有的神像都要被打碎,

她所得的淫資都要化為灰燼;

我要毀滅她的一切偶像。

她以淫資得來的偶像,

也要被用作妓女的淫資。」

先知的哀傷

8為此,我要痛哭哀號,

我要赤身光腳而行,

像豺狼哀嚎,

如鴕鳥悲鳴。

9因為撒瑪利亞的創傷無法救治,

已經禍及猶大

直逼我百姓的城門,直逼耶路撒冷

10不要在迦特宣揚,

也不要哭泣,

要在伯·亞弗拉的灰塵中打滾。

11沙斐的居民啊,

你們將赤身露體,

被羞辱地擄去。

撒南的居民不敢出城,

伯·以薛在痛哭,

你們已失去它的庇護。

12瑪律的居民痛苦不堪,

渴望得到拯救,

因為耶和華已把災難降到耶路撒冷的城門。

13拉吉的居民啊,

用駿馬套車逃命吧!

是你們首先唆使錫安城犯罪,

在你們身上看到了以色列的罪惡。

14去向摩利設·迦特贈送告別禮物吧!

亞革悉人必令以色列諸王受騙上當。

15瑪利沙的居民啊,

我要使征服者到你們那裡。

以色列的領袖1·15 以色列的領袖」希伯來文是「以色列的榮耀」。要躲到亞杜蘭

16猶大人啊,你們要剃光頭髮,

為你們所愛的兒女悲傷;

要剃得如禿鷹一樣光禿,

因為他們要被擄到遠方。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Mika 1:1-16

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Mika ará Moreṣeti wá ní àkókò ìjọba Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, àwọn ọba Juda nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaria àti Jerusalẹmu.

2Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn,

fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,

Olúwa Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín,

1.2: 1Ọb 22.28.Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá.

Ìdájọ́ tí o lòdì sí Samaria àti Jerusalẹmu

3Wò ó! Olúwa ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀;

yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀.

4Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀,

àwọn Àfonífojì yóò sì pínyà,

bí idà níwájú iná,

bí omi tí ó ń sàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.

5Nítorí ìré-òfin-kọjá Jakọbu ni gbogbo èyí,

àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli.

Kí ni ìré-òfin-kọjá Jakọbu?

Ǹjẹ́ Samaria ha kọ?

Kí ni àwọn ibi gíga Juda?

Ǹjẹ́ Jerusalẹmu ha kọ?

6“Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaria bí òkìtì lórí pápá,

bí ibi ti à ń lò fún gbígbin ọgbà àjàrà.

Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì.

Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ palẹ̀.

7Gbogbo àwọn ère fínfín rẹ̀ ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́

gbogbo àwọn ẹ̀bùn tẹmpili rẹ̀ ni a ó fi iná sun:

Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn òrìṣà rẹ̀ run.

Nítorí tí ó ti kó àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ jọ láti inú owó èrè panṣágà,

gẹ́gẹ́ bí owó èrè panṣágà, wọn yóò sì tún padà sí owó iṣẹ́ panṣágà.”

Ẹkún òun ọfọ̀

8Nítorí èyí, èmi yóò sì sọkún,

èmi yóò sì pohùnréré ẹkún:

èmi yóò máa lọ ní ẹsẹ̀ lásán àti ní ìhòhò

Èmi yóò ké bí akátá,

èmi yóò sì máa dárò bí àwọn ọmọ ògòǹgò.

9Nítorí tí ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìlèwòtán;

ó sì ti wá sí Juda.

Ó sì ti dé ẹnu-bodè àwọn ènìyàn mi,

àní sí Jerusalẹmu.

10Ẹ má ṣe sọ ní Gati

ẹ má ṣe sọkún rárá.

Ní ilẹ̀ Beti-Ofra

mo yí ara mi nínú eruku.

11Ẹ kọjá lọ ni ìhòhò àti ni ìtìjú,

ìwọ tí ó ń gbé ni Ṣafiri.

Àwọn tí ó ń gbé ni Ṣaanani

kì yóò sì jáde wá.

Beti-Eseli wà nínú ọ̀fọ̀;

A ó sì gba ààbò rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yin.

12Nítorí àwọn tí ó ń gbé ni Marati ń retí ìre,

Ṣùgbọ́n ibi sọ̀kalẹ̀ ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí ẹnu-bodè Jerusalẹmu.

13Ìwọ olùgbé Lakiṣi,

dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára.

Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀

sí àwọn ọmọbìnrin Sioni,

nítorí a rí àìṣedéédéé Israẹli nínú rẹ̀.

14Nítorí náà ni ìwọ ó ṣe fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀

fún Moreṣeti Gati.

Àwọn ilé Aksibu yóò jẹ́ ẹlẹ́tàn sí àwọn ọba Israẹli.

15Èmi yóò sì mú àrólé kan wá sórí rẹ ìwọ olùgbé Meraṣa.

Ẹni tí ó jẹ́ ògo Israẹli

yóò sì wá sí Adullamu.

16Fá irun orí rẹ nínú ọ̀fọ̀

nítorí àwọn ọmọ rẹ aláìlágbára,

sọ ra rẹ̀ di apárí bí ẹyẹ igún,

nítorí wọn yóò kúrò lọ́dọ̀ rẹ lọ sí ìgbèkùn.