雅各书 3 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

雅各书 3:1-18

邪恶的舌头

1我的弟兄姊妹,不要个个当教师,因为你们知道,我们为人师表的将受到更严格的评判, 2因为我们在许多方面难免有过失。如果谁在言语上没有过失,他就是纯全的人,也能在各方面保持自制。 3我们如果把嚼环放在马嘴里,便可以使它顺服,驾驭它。 4一艘大船在遭遇暴风吹袭时,船身虽然庞大,但舵手只要操纵一个小小的舵,就能随意驾驶它。

5同样,人的舌头虽然很小,却能说夸大的话。

看啊,小火星能点燃大森林。 6舌头就是火,是我们身体上的一个充满邪恶的世界,能玷污人的全身,足以毁掉人的一生,它是从地狱点燃的火。 7自然界中的各类走兽、飞禽、爬虫、水族都可以被驯服,也已经被人类驯服了, 8但无人能驯服自己的舌头,因为舌头是个无法控制的邪恶之物,充满了致命的毒气。 9我们用舌头来赞美主和天父,也用舌头来咒诅照着上帝的形象被造的人。 10赞美和咒诅竟然从同一张嘴里发出来。我的弟兄姊妹,这是不应该的! 11同一个泉源能涌出甜苦两样水吗? 12我的弟兄姊妹,无花果树能结出橄榄吗?葡萄树能结出无花果吗?一个咸水泉必流不出甜水来。

天上的智慧

13你们当中谁是有智慧、有见识的呢?请他带着来自智慧的谦和,在善行上表现出来。 14但如果你们心怀苦毒的嫉妒和自私的野心,就不要自夸说有智慧,也不要违背真理去撒谎。 15这种智慧并非来自天上,而是从世俗、私欲和魔鬼来的。 16哪里有嫉妒和自私的野心,哪里就会有混乱和各样的恶事。

17但从天上来的智慧首先是纯洁,然后是爱好和平、温良柔顺、充满怜悯、多结善果、不存偏见、没有虚伪。 18使人和睦的人撒下和平的种子,必收获仁义的果实。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jakọbu 3:1-18

Kíkó ahọ́n ní ìjánu

1Ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí púpọ̀ nínú yín jẹ́ olùkọ́, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé àwa ni yóò jẹ̀bi jù. 2Nítorí nínú ohun púpọ̀ ni gbogbo wa ń ṣe àṣìṣe. Bí ẹnìkan kò bá ṣì ṣe nínú ọ̀rọ̀, òun náà ni ẹni pípé, òun ni ó sì le kó gbogbo ara ní ìjánu.

3Bí a bá sì fi ìjánu bọ ẹṣin lẹ́nu, kí wọn kí ó le gbọ́ tiwa, gbogbo ara wọn ni àwa sì ń tì kiri pẹ̀lú. 4Kíyèsi i, àwọn ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú, bí wọ́n ti tóbi tó nì, tí a sì ń ti ọwọ́ ẹ̀fúùfù líle gbá kiri, ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí wọn kiri, síbikíbi tí ó bá wu ẹni tí ó ń tọ́ ọkọ̀. 5Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kékeré, ó sì ń fọhùn ohùn ńlá. Wo igi ńlá tí iná kékeré ń sun jóná! 6Iná sì ni ahọ́n, ayé ẹ̀ṣẹ̀ sì ni: ní àárín àwọn ẹ̀yà ara wa, ní ahọ́n ti ń bá gbogbo ara jẹ́, tí yóò sì ti iná bọ ipa ayé wa; ọ̀run àpáàdì a sì tiná bọ òun náà.

7Nítorí olúkúlùkù ẹ̀dá ẹranko, àti ti ẹyẹ, àti ti ejò, àti ti ohun tí ó ń bẹ ní Òkun, ni à ń tù lójú, tí a sì ti tù lójú láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn wá. 8Ṣùgbọ́n ahọ́n ni ẹnikẹ́ni kò le tù lójú; ohun búburú aláìgbọ́ràn ni, ó kún fún oró ikú tí í pa ni.

9Òun ni àwa fi ń yin Olúwa àti Baba, òun ni a sì fi ń bú ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run. 10Láti ẹnu kan náà ni ìyìn àti èébú ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, nǹkan wọ̀nyí kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀. 11Orísun odò kan a ha máa sun omi dídára àti omi iyọ̀ jáde láti orísun kan náà bí? 12Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ ha le so èso olifi bí? Tàbí àjàrà ha lè so èso ọ̀pọ̀tọ́? Bẹ́ẹ̀ ni orísun kan kò le sun omíró àti omi tútù.

Oríṣìí ọgbọ́n méjì

13Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n. 14Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́. 15Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni. 16Nítorí níbi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà.

17Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, a sì máa sọ òtítọ́. 18Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ àlàáfíà a sì máa gbin èso àlàáfíà ní àlàáfíà.