路加福音 3 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

路加福音 3:1-38

施洗者约翰的传道

1凯撒提庇留执政第十五年,本丢·彼拉多犹太总督,希律加利利的分封王,他的弟弟腓力以土利亚特拉可尼两地的分封王,吕撒聂亚比利尼的分封王, 2亚那该亚法当大祭司。当时,撒迦利亚的儿子约翰住在旷野,上帝向他说话。 3他就到约旦河附近宣讲悔改的洗礼,使人的罪得到赦免。 4这正应验了以赛亚先知书上的话:“在旷野有人大声呼喊,

“‘预备主的道,

修直祂的路。

5一切山谷将被填满,

大山小丘将被削平,

弯曲的道路要被修直,

崎岖的路径要被铺平。

6世人都要看见上帝的救恩。’”

7约翰对前来接受他洗礼的人群说:“你们这些毒蛇的后代!谁指示你们逃避那将临的烈怒呢? 8你们要结出与悔改相称的果子。不要心里说,‘我们是亚伯拉罕的子孙。’我告诉你们,上帝可以从这些石头中兴起亚伯拉罕的子孙。 9现在斧头已经放在树根上了,不结好果子的树都要被砍下丢在火里。”

10众人问道:“那么,我们该怎么办呢?”

11约翰回答说:“有两件衣服的,应当分一件给没有的;食物充裕的,应当分些给饥饿的。”

12有些税吏也来受洗,并问约翰:“老师,我们该怎么办呢?”

13约翰说:“除了规定的税以外,一分钱也不可多收。”

14有些军人问:“我们该怎么办呢?”约翰说:“不可敲诈勒索,自己有粮饷就当知足。”

15当时的百姓正期待着基督的来临,大家心里都在猜想,也许约翰就是基督。 16约翰对众人说:“我是用水给你们施洗,但有一位能力比我更大的快来了,我就是给祂解鞋带也不配。祂要用圣灵和火给你们施洗。 17祂手里拿着簸箕,要清理祂的麦场,把麦子收进仓库,用不灭的火烧尽糠秕。” 18约翰向众人传福音,讲了许多劝勉的话。

19分封王希律娶了自己弟弟的妻子希罗底,又做了许多恶事,因而受到约翰的指责, 20可是他却恶上加恶,将约翰关进监牢里。

耶稣受洗

21众人都受了洗,耶稣也接受了洗礼。祂正在祷告的时候,天开了, 22圣灵像鸽子一样降在祂身上,又有声音从天上传来:“你是我的爱子,我甚喜悦你。”

耶稣的家谱

23耶稣开始传道的时候,年纪约三十岁,照人的看法,

祂是约瑟的儿子,

约瑟希里的儿子,

24希里玛塔的儿子,

玛塔利未的儿子,

利未麦基的儿子,

麦基雅拿的儿子,

雅拿约瑟的儿子,

25约瑟玛他提亚的儿子,

玛他提亚亚摩斯的儿子,

亚摩斯拿鸿的儿子,

拿鸿以斯利的儿子,

以斯利拿该的儿子,

26拿该玛押的儿子,

玛押玛他提亚的儿子,

玛他提亚西美的儿子,

西美约瑟的儿子,

约瑟犹大的儿子,

犹大约亚拿的儿子,

27约亚拿利撒的儿子,

利撒所罗巴伯的儿子,

所罗巴伯撒拉铁的儿子,

撒拉铁尼利的儿子,

尼利麦基的儿子,

28麦基亚底的儿子,

亚底哥桑的儿子,

哥桑以摩当的儿子,

以摩当的儿子,

约细的儿子,

29约细以利以谢的儿子,

以利以谢约令的儿子,

约令玛塔的儿子,

玛塔利未的儿子,

30利未西缅的儿子,

西缅犹大的儿子,

犹大约瑟的儿子,

约瑟约南的儿子,

约南以利亚敬的儿子,

31以利亚敬是米利亚的儿子,

米利亚迈南的儿子,

迈南玛达他的儿子,

玛达他拿单的儿子,

拿单大卫的儿子,

32大卫耶西的儿子,

耶西俄备得的儿子,

俄备得波阿斯的儿子,

波阿斯撒门的儿子,

撒门拿顺的儿子,

33拿顺亚米拿达的儿子,

亚米拿达的儿子,

希斯仑的儿子,

希斯仑法勒斯的儿子,

法勒斯犹大的儿子,

34犹大雅各的儿子,

雅各以撒的儿子,

以撒亚伯拉罕的儿子,

亚伯拉罕他拉的儿子,

他拉拿鹤的儿子,

35拿鹤西鹿的儿子,

西鹿拉吴的儿子,

拉吴法勒的儿子,

法勒希伯的儿子,

希伯沙拉的儿子,

36沙拉该南的儿子,

该南亚法撒的儿子,

亚法撒的儿子,

挪亚的儿子,

挪亚拉麦的儿子,

37拉麦玛土撒拉的儿子,

玛土撒拉以诺的儿子,

以诺雅列的儿子,

雅列玛勒列的儿子,

玛勒列该南的儿子,

该南以挪士的儿子,

38以挪士塞特的儿子,

塞特亚当的儿子,

亚当是上帝的儿子。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 3:1-38

Johanu onítẹ̀bọmi tún ọnà náà ṣe

13.1: Lk 23.1; 9.7; 13.31; 23.7.Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene, 23.2: Jh 18.13; Ap 4.6; Mt 26.3; Jh 11.49.tí Annasi òun Kaiafa ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Johanu ọmọ Sekariah wá ní ijù. 33.3-9: Mt 3.1-10; Mk 1.1-5; Jh 1.6,23.Ó sì wá sí gbogbo ilẹ̀ aginjù Jordani, ó ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; 43.4-6: Isa 40.3-5.Bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah pé,

“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,

‘ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,

ẹ mú ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́.

5Gbogbo ọ̀gbun ni a yóò kún,

gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ́ pẹẹrẹ;

Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́,

àti ọ̀nà gbọ́ngungbọ̀ngun ni a o sọ di dídán.

63.6: Lk 2.30.Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”

73.7: Mt 12.34; 23.33.Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? 83.8: Jh 8.33,39.Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí. 93.9: Mt 7.19; Hb 6.7-8.Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà: gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.”

10Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ṣe?”

11Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”

12Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?”

13Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”

14Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?”

Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”

153.15: Ap 13.25; Jh 1.19-22.Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Johanu, bí òun ni Kristi tàbí òun kọ́; 163.16-18: Mt 3.11-12; Mk 1.7-8; Jh 1.26-27,33; Ap 1.5; 11.16; 19.4.Johanu dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamitiisi yín; ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú: òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín: 17Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tó tó, kí ó sì kó alikama rẹ̀ sínú àká; ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.” 18Johanu lo oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìhìnrere fún wọn.

193.19-20: Mt 14.3-4; Mk 6.17-18.Ṣùgbọ́n nígbà ti Johanu bú Herodu tetrarki, tí ó bá wí nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, àti nítorí ohun búburú gbogbo tí Herodu tí ṣe, 20Ó fi èyí parí gbogbo rẹ̀ nígba tí ó fi Johanu sínú túbú.

Ìtẹ̀bọmi àti ìtàn ìdílé Jesu

213.21-22: Mt 3.13-17; Mk 1.9-11; Jh 1.29-34.3.21: Lk 5.16; 6.12; 9.18,28; 11.1; Mk 1.35.Nígbà tí a ṣe ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamitiisi Jesu pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀, 223.22: Sm 2.7; Isa 42.1; Lk 9.35; Ap 10.38; 2Pt 1.17.Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

233.23-38: Mt 1.1-17; Gẹ 5.3-32; 11.10-26; Ru 4.18-22; 1Ki 1.1-4,24-28; 2.1-15.3.23: Jh 8.57; Lk 1.27.Jesu tìkára rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Josẹfu,

tí í ṣe ọmọ Eli, 24tí í ṣe ọmọ Mattati,

tí í ṣe ọmọ Lefi, tí í ṣe ọmọ Meliki,

tí í ṣe ọmọ Janai, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,

25tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Amosi,

tí í ṣe ọmọ Naumu, tí í ṣe ọmọ Esili,

tí í ṣe ọmọ Nagai, 26tí í ṣe ọmọ Maati,

tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Ṣimei,

tí í ṣe ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Joda,

27Tí í ṣe ọmọ Joana, tí í ṣe ọmọ Resa,

tí í ṣe ọmọ Serubbabeli, tí í ṣe ọmọ Ṣealitieli,

tí í ṣe ọmọ Neri, 28tí í ṣe ọmọ Meliki,

tí í ṣe ọmọ Adi, tí í ṣe ọmọ Kosamu,

tí í ṣe ọmọ Elmadamu, tí í ṣe ọmọ Eri,

29Tí í ṣe ọmọ Joṣua, tí í ṣe ọmọ Elieseri,

tí í ṣe ọmọ Jorimu, tí í ṣe Mattati,

tí í ṣe ọmọ Lefi, 30tí í ṣe ọmọ Simeoni,

tí í ṣe ọmọ Juda, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,

tí í ṣe ọmọ Jonamu, tí í ṣe ọmọ Eliakimu,

31Tí í ṣe ọmọ Melea, tí í ṣe ọmọ Menna,

tí í ṣe ọmọ Mattata, tí í ṣe ọmọ Natani,

tí í ṣe ọmọ Dafidi, 32tí í ṣe ọmọ Jese,

tí í ṣe ọmọ Obedi, tí í ṣe ọmọ Boasi,

tí í ṣe ọmọ Salmoni, tí í ṣe ọmọ Nahiṣoni,

33Tí í ṣe ọmọ Amminadabu, tí í ṣe ọmọ Ramu,

tí í ṣe ọmọ Hesroni, tí í ṣe ọmọ Peresi,

tí í ṣe ọmọ Juda. 34Tí í ṣe ọmọ Jakọbu,

tí í ṣe ọmọ Isaaki, tí í ṣe ọmọ Abrahamu,

tí í ṣe ọmọ Tẹra, tí í ṣe ọmọ Nahori,

35Tí í ṣe ọmọ Serugu, tí í ṣe ọmọ Reu,

tí í ṣe ọmọ Pelegi, tí í ṣe ọmọ Eberi,

tí í ṣe ọmọ Ṣela. 36Tí í ṣe ọmọ Kainani,

tí í ṣe ọmọ Arfaksadi, tí í ṣe ọmọ Ṣemu,

tí í ṣe ọmọ Noa, tí í ṣe ọmọ Lameki,

37Tí í ṣe ọmọ Metusela, tí í ṣe ọmọ Enoku,

tí í ṣe ọmọ Jaredi, tí í ṣe ọmọ Mahalaleli,

tí í ṣe ọmọ Kainani. 38Tí í ṣe ọmọ Enosi,

tí í ṣe ọmọ Seti, tí í ṣe ọmọ Adamu,

tí í ṣe ọmọ Ọlọ́run.