路加福音 2 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

路加福音 2:1-52

耶稣降生伯利恒

1那时,凯撒奥古斯都颁下谕旨,命罗马帝国的人民都办理户口登记。 2这是第一次户口登记,正值居里纽叙利亚总督。 3大家都回到本乡办理户口登记。 4约瑟因为是大卫家族的人,就从加利利拿撒勒镇赶到犹太地区大卫的故乡伯利恒5要和已许配给他、怀着身孕的玛丽亚一起登记。 6他们抵达目的地时,玛丽亚产期到了, 7便生下第一胎,是个儿子。她用布把孩子裹好,安放在马槽里,因为旅店没有房间了。

牧羊人和天使

8当晚,伯利恒郊外有一群牧羊人正在看守羊群。 9忽然,主的天使向他们显现,主的荣光四面照着他们,他们非常害怕。 10天使对他们说:“不要怕!我告诉你们一个有关万民的大喜讯, 11今天在大卫的城里有一位救主为你们降生了,祂就是主基督! 12你们将看见一个婴孩包着布躺在马槽里,这就是给你们的记号。”

13忽然,有一大队天军出现,与那天使一同赞美上帝说:

14“在至高之处,

愿荣耀归于上帝!

在地上,

愿平安临到祂所喜悦的人!”

15众天使离开他们升回天上之后,牧羊人便商议说:“我们现在去伯利恒,察看一下主刚才告诉我们的那件事吧!” 16他们就连忙进城,找到了玛丽亚约瑟以及躺在马槽里的婴孩。 17他们看过之后,就把天使告诉他们有关这婴孩的事传开了。 18听见的人都对牧羊人的话感到惊讶。

19玛丽亚把这些事牢记在心里,反复思想。 20牧羊人在归途中不断地将荣耀归于上帝,赞美祂,因为他们的所见所闻跟天使告诉他们的一样。

奉献圣婴

21在第八天,婴孩接受了割礼,祂的名字叫耶稣,是玛丽亚怀孕前天使取的。

22摩西律法规定的洁净期满后,约瑟玛丽亚把婴孩带到耶路撒冷去献给主, 23因为主的律法规定:必须把长子分别出来献给主。 24他们又按照主的律法献上祭物,即一对斑鸠或两只雏鸽。 25耶路撒冷有一位公义敬虔、有圣灵同在的人名叫希缅,他一直期待着以色列的安慰者到来。 26圣灵曾启示他:他去世前必能亲眼看见主所立的基督。

27一天,他受圣灵感动进入圣殿,看见约瑟玛丽亚抱着婴孩耶稣进来,要依照律法的规定为祂行奉献礼, 28就把祂抱过来,称颂上帝说:

29“主啊,现在你的话已经成就,

可以让你的奴仆安然离世了,

30因为我已亲眼看到你的救恩,

31就是你为万民所预备的救恩。

32这救恩是启示外族人的光,

也是你以色列子民的荣耀。”

33约瑟玛丽亚听见这番话,感到惊奇。 34希缅给他们祝福后,就对孩子的母亲玛丽亚说:“看啊,这孩子必使以色列许多人跌倒、许多人兴起。祂将成为众人攻击的对象, 35好叫许多人的心思意念暴露出来,你自己则会心如刀割。”

36-37亚设支派中有一位八十四岁高龄的女先知名叫亚拿,是法内利的女儿,婚后七年便开始守寡,之后一直住在圣殿里,禁食祷告,日夜事奉上帝。 38正在那时,她也前来感谢上帝,并把耶稣的事报告给所有盼望耶路撒冷蒙救赎的人。

39约瑟玛丽亚办完了主的律法规定的一切事之后,就回到他们的家乡——加利利拿撒勒40耶稣渐渐长大,身心强健,充满智慧,上帝的恩典与祂同在。

少年耶稣圣殿论道

41约瑟玛丽亚每年都上耶路撒冷去过逾越节。 42耶稣十二岁那年,跟父母照例上去过节。 43节期完了,约瑟玛丽亚便启程回家,他们并不知道少年耶稣仍然留在耶路撒冷44还以为祂跟在同行的人中间。他们走了一天的路后,才开始在亲戚朋友中找祂, 45结果没有找到,只好回到耶路撒冷46三天后,他们才在圣殿里找到耶稣,祂正和教师们坐在一起,一边听一边问问题。 47祂的知识和对答令听见的人感到惊奇。 48约瑟玛丽亚看见耶稣在那里,大为惊奇。

玛丽亚对祂说:“儿子,你为什么这样对我们呢?你父亲和我急得到处找你!”

49耶稣对他们说:“你们为什么找我呢?难道你们不知道我应该在我父的家吗?” 50但他们不明白祂在讲什么。

51于是,耶稣随父母回到拿撒勒,并顺从他们。玛丽亚把这一切事牢记在心。 52耶稣渐渐长大,智慧与日俱增,越来越受上帝和人们的喜爱。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 2:1-52

Ìbí Jesu

12.1: Lk 3.1.Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àṣẹ ti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu jáde wá pé, kí a kọ orúkọ gbogbo ayé sínú ìwé. 2(Èyí ni ìkọ sínú ìwé èkínní tí a ṣe nígbà tí Kirene fi jẹ baálẹ̀ Siria.) 3Gbogbo àwọn ènìyàn sì lọ láti kọ orúkọ wọn sínú ìwé, olúkúlùkù sí ìlú ara rẹ̀.

42.4: Lk 1.27.Josẹfu pẹ̀lú sì gòkè láti Nasareti ni Galili, sí ìlú Dafidi ní Judea, tí à ń pè ní Bẹtilẹhẹmu; nítorí ti ìran àti ìdílé Dafidi ní í ṣe, 5láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú Maria aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ ti tó bí. 6Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé tí òun yóò bí. 7Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí ààyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò.

Àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti àwọn angẹli

8Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ń bẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé. 92.9: Lk 1.11; Ap 5.19.Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká: ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. 10Angẹli náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìhìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo. 112.11: Jh 4.42; Ap 5.31; Mt 16.16; Ap 2.36.Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tí í ṣe Kristi Olúwa. 122.12: 1Sa 2.34; 2Ọb 19.29; Isa 7.14.Èyí ni yóò sì ṣe ààmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.

13Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ angẹli náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé,

142.14: Lk 19.38; 3.22.“Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run,

Àti ní ayé Àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”

15Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn angẹli náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ tààrà sí Bẹtilẹhẹmu, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀, tí Olúwa fihàn fún wa.”

16Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí Maria àti Josẹfu, àti ọmọ ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran. 17Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí. 18Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá. 192.19: Lk 2.51.Ṣùgbọ́n Maria pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀. 20Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn.

A gbé Jesu kalẹ̀ nínú Tẹmpili

212.21: Lk 1.31,59; Mt 1.25.Nígbà tí ọjọ́ mẹ́jọ sì pé láti kọ ọmọ náà nílà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ angẹli náà wá kí á tó lóyún rẹ̀.

222.22-24: Le 12.2-8.Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Maria sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, Josẹfu àti Maria gbé Jesu wá sí Jerusalẹmu láti fi í fún Olúwa 232.23: Ek 13.2,12.(bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”), 24àti láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “Àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.”

252.25: Lk 2.38; 23.51.Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà ní Jerusalẹmu, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Simeoni; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Israẹli: Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e. 26A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí Kristi Olúwa. 27Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹmpili: nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé Jesu wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin, 28Nígbà náà ni Simeoni gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní:

29“Olúwa Olódùmarè, nígbà yìí ni ó tó jọ̀wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ,

ní Àlàáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ:

302.30: Isa 52.10; Lk 3.6.Nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná,

31Tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo;

322.32: Isa 42.6; 49.6; Ap 13.47; 26.23.ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà,

àti ògo Israẹli ènìyàn rẹ̀.”

33Ẹnu sì ya Josẹfu àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí. 34Simeoni sì súre fún wọn, ó sì wí fún Maria ìyá rẹ̀ pé: “Kíyèsi i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Israẹli; àti fún ààmì tí a ń sọ̀rọ̀-òdì sí; 35(Idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú) kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.”

362.36: Ap 21.9; Jo 19.24; 1Tm 5.9.Ẹnìkan sì ń bẹ, Anna wòlíì, ọmọbìnrin Penueli, nínú ẹ̀yà Aṣeri: ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúńdíá rẹ̀ wá; 37Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹmpili, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru. 38Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerusalẹmu.

39Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Galili, sí Nasareti ìlú wọn. 402.40: On 13.24; 1Sa 2.26.Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n: oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀.

Ọ̀dọ́mọkùnrin Jesu ni tẹmpili

412.41: De 16.1-8; Ek 23.15.Àwọn òbí rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerusalẹmu ní ọdọọdún sí àjọ ìrékọjá. 42Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà. 43Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jesu dúró lẹ́yìn ní Jerusalẹmu; Josẹfu àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀. 44Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ èrò, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan; wọ́n wá a kiri nínú àwọn ará àti àwọn ojúlùmọ̀ wọn. 45Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a kiri. 46Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta wọ́n rí i nínú tẹmpili ó jókòó ní àárín àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ tiwọn, ó sì ń bi wọ́n léèrè. 47Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀. 482.48: Mk 3.31-35.Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n: ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, baba rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbànújẹ́ wá ọ kiri.”

49Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri, ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?” 50Ọ̀rọ̀ tí o sọ kò sì yé wọn.

512.51: Lk 2.19.Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Nasareti, sì fi ara balẹ̀ fún wọn: ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀. 522.52: Lk 1.80; 2.40.Jesu sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.