耶利米书 12 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

耶利米书 12:1-17

耶利米的抱怨

1耶和华啊,每次我与你争论,

都显明你是对的。

然而,我还是对你的公正有所不解:

为什么恶人总是得势?

为什么诡诈之人反而生活安逸?

2你栽培他们,让他们生根长大,

结出果实。

他们嘴上尊崇你,

心却远离你。

3但耶和华啊,你认识我,了解我,

察验我的内心。

求你拖走他们,

就像拖走待宰的羊,

留到宰杀之日。

4大地哀恸、

田野的植物枯槁要到何时呢?

由于这地方居民的罪恶,

野兽和飞鸟都灭绝了。

他们说:“上帝看不见我们的行为12:4 上帝看不见我们的行为”参照《七十士译本》,希伯来文也可译作“他(指耶利米)看不见我们的结局”。。”

5耶和华说:“如果你与步行的人竞走,

尚且感到疲乏,

又怎能与马赛跑呢?

如果你在宽阔之地尚且跌倒,

约旦河边的丛林中又会怎样呢?

6你的弟兄和家人都背叛了你,

与你作对。

任他们甜言蜜语,你不要相信。

7“我已离开我的殿,

撇弃我的产业,

把我爱的子民交给他们的敌人。

8我的子民像林中的狮子一样向我吼叫,

因此我憎恶他们;

9我的子民就像一只带斑点的鸷鸟,

被其他鸷鸟围攻。

招聚野兽来吞吃它吧!

10列国的首领毁坏我的葡萄园,

践踏我美好的土地,

使它荒凉;

11他们使这片土地荒凉,

以致它在我面前哀哭。

遍地如此荒凉,却无人在意。

12杀戮者已来到旷野中光秃的山岭,

耶和华使刀剑横扫全境,

无人幸免。

13我的子民播种麦子,

却收割荆棘;

辛勤耕耘,却一无所获。

他们必因耶和华的烈怒而收获羞辱。”

14耶和华说:“邪恶的邻国侵占了我赐给我以色列子民的土地,我要把这些恶邻逐出他们的本土,正如我要逐出犹大一样。 15我逐出他们以后,还要再怜悯他们,把他们带回各自的家园和故土。 16如果他们真心接受我子民的信仰,凭永活的耶和华之名起誓,正如他们教导我子民向巴力起誓一样,他们便能成为我的子民。 17如果哪一国不听我的话,我必把它连根拔起,彻底毁灭。这是耶和华说的。”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 12:1-17

Ọ̀rọ̀ Jeremiah

1Olúwa, olódodo ni ọ́ nígbàkúgbà,

nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá.

Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ.

Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédé?

Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìṣòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn?

2Ó ti gbìn wọ́n, wọ́n sì ti fi egbò múlẹ̀,

wọ́n dàgbà wọ́n sì so èso.

Gbogbo ìgbà ni ó wà ní ètè wọn,

o jìnnà sí ọkàn wọn.

3Síbẹ̀ o mọ̀ mí ní Olúwa,

o ti rí mi o sì ti dán èrò mi nípa rẹ wò.

Wọ, wọ́n lọ bí àgùntàn tí a fẹ́ pa.

Yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ pípa.

4Yóò ti pẹ́ tó tí ọ̀gbẹlẹ̀ yóò fi wà,

tí gbogbo ewéko igbó sì ń rọ?

Nítorí àwọn ènìyàn búburú ni ó ń gbé ibẹ̀.

Àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ ti ṣègbé,

pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ènìyàn ń sọ pé,

“Kò lè rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa.”

Ìdáhùn Ọlọ́run

5Bí ìwọ bá ń bá ẹlẹ́ṣẹ̀ sáré,

tí àárẹ̀ sì mú ọ,

báwo ni ìwọ yóò ṣe bá ẹṣin díje?

Bí ìwọ bá kọsẹ̀ ní ilẹ̀ àlàáfíà,

bí ìwọ bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé,

kí ni ìwọ ó ṣe nínú ẹkùn odò Jordani?

6Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn

ìdílé—

ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọ

Wọ́n ti hó lé ọ lórí;

Má ṣe gbà wọ́n gbọ́

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáradára.

7Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀,

èmi yóò fi ìní mi sílẹ̀.

Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́

lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.

8Ogún mi ti rí sí mi

bí i kìnnìún nínú igbó.

Ó ń bú ramúramù mọ́ mi;

nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.

9Ogún mi kò ha ti rí sí mi

bí ẹyẹ kannakánná

tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì ka, tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i?

Ẹ lọ, kí ẹ sì kó gbogbo ẹranko igbó jọ,

ẹ mú wọn wá jẹ.

10Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́-àgùntàn ni yóò sì ba ọgbà àjàrà mi jẹ́,

tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀;

Wọ́n ó sọ oko dídára mi di

ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.

11A ó sọ ọ́ di aṣálẹ̀ ilẹ̀

tí kò wúlò níwájú mi,

gbogbo ilẹ̀ ni yóò di ahoro

nítorí kò sí ẹnìkankan tí yóò náání.

12Gbogbo ibi gíga tí ó wà nínú aṣálẹ̀

ni àwọn apanirun ti gorí,

nítorí idà Olúwa yóò pa

láti ìkangun kìn-ín-ní dé ìkangun èkejì ilẹ̀ náà;

kò sí àlàáfíà fún gbogbo alààyè.

13Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká,

wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn.

Kí ojú kí ó tì yín nítorí èrè yín,

nítorí ìbínú gbígbóná Olúwa.

14Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ní ti gbogbo àwọn aládùúgbò mi búburú tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ogún tí mo fún àwọn ènìyàn Israẹli mi, Èmi yóò fà wọ́n tu kúrò lórí ilẹ̀ wọn, èmi yóò fa ìdílé Juda tu kúrò ní àárín wọn. 15Ṣùgbọ́n tí mo bá fà wọ́n tu tán, Èmi yóò padà yọ́nú sí wọn. Èmi yóò sì padà fún oníkálùkù ní ogún ìní rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ìní oníkálùkù. 16Bí wọ́n bá sì kọ ìwà àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì fi orúkọ mi búra wí pé, ‘níwọ̀n bí Olúwa ń bẹ láààyè,’ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ́ àwọn ènìyàn mi láti fi Baali búra, nígbà náà ni a ó gbé wọn ró láàrín àwọn ènìyàn mi. 17Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kan kò bá gbọ́, Èmi yóò fà á tu pátápátá, èmi yóò sì pa wọ́n run,” ni Olúwa wí.