约翰三书 1 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

约翰三书 1:1-15

1我这做长老的写信给亲爱的该犹,就是我本着真理所爱的人。 2亲爱的弟兄,衷心地祝你凡事顺利,身体和灵魂一样健康。

该犹的好品行

3有弟兄们来为你的行为做见证,说你忠心地遵行真理,这使我非常欣慰。 4没有比听见自己的孩子遵行真理更使我欢喜了。

5亲爱的弟兄,你常常忠心地照顾素不相识的弟兄, 6他们把你的爱心告诉了教会。愿你照着上帝所喜悦的方式继续帮助他们, 7因为他们为了主耶稣的名四处传道,不收取非信徒的任何东西。 8我们应该接待这样的人,好与他们一同传扬真理。

丢特腓的恶行

9我曾写信给你那里的教会,但喜欢做领袖的丢特腓不理会我们。 10因此,我若去你们那里,会提及他的所作所为,就是他怎样恶言中伤我们。不仅如此,他还拒绝接待弟兄,并且禁止别人接待,甚至将接待的人赶出教会。

抑恶扬善

11亲爱的弟兄,不要效法罪恶,要效法美善。行善的人属于上帝,行恶的人不认识上帝。 12低米丢得到了众人的好评,真理本身也为他做见证,我们也为他做见证。你们知道我们的见证是真实的。

结语

13我本来有很多事想跟你谈,但不想用笔墨写给你, 14只希望可以快快地见到你,跟你当面畅谈。

15祝你平安!这里的朋友们都问候你,请代我一一问候你那边的朋友。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

3 Johanu 1:1-15

11: Ap 19.29; 2Jh 1.Alàgbà,

Sì Gaiusi, olùfẹ́, ẹni tí mo fẹ́ nínú òtítọ́.

2Olùfẹ́, èmi ń gbàdúrà pé nínú ohun gbogbo kí o lè máa dára fún ọ, kí o sì máa wà ni ìlera, àní bí o tí dára fún ọkàn rẹ. 3Nítorí mo yọ̀ gidigidi, nígbà tí àwọn arákùnrin dé tí wọn sì jẹ́rìí sí ìwà òtítọ́ inú rẹ̀, àní bí ìwọ tí ń rìn nínú òtítọ́. 4Èmi ni ayọ̀ tí ó tayọ, láti máa gbọ́ pé, àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.

5Olùfẹ́, ìwọ ń ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún àwọn tí ń ṣe ará, àti pàápàá fún àwọn tí ń ṣe àlejò. 6Tí wọn ń jẹ́rìí sí ìfẹ́ rẹ̀ níwájú ìjọ: bí ìwọ bá ń pèsè fún wọn ní ọ̀nà àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó tí yẹ nínú Ọlọ́run. 7Nítorí pé, nítorí iṣẹ́ Kristi ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgba ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn aláìkọlà. 8Nítorí náà, ó yẹ kí àwa fi inú rere gba irú àwọn wọ̀nyí, kí àwa lè jẹ́ alábáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.

9Èmi kọ̀wé sí ìjọ: ṣùgbọ́n Diotirefe, ẹni tí ó fẹ́ láti jẹ́ ẹni pàtàkì jùlọ, kò gbà wá. 10Nítorí náà bí mo bá dé, èmi yóò mú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ṣe wá sì ìrántí rẹ, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ búburú àti ìsọkúsọ sí wa: èyí kò sì tún tẹ́ ẹ lọ́rùn, síbẹ̀ òun fúnrarẹ̀ kọ̀ láti gba àwọn ará, àwọn tí ó sì ń fẹ́ gbà wọ́n, ó ń dá wọn lẹ́kun, ó sì ń lé wọn kúrò nínú ìjọ.

11Olùfẹ́, má ṣe ṣe àfarawé ohun tí í ṣe ibi bí kò ṣe ohun tí ṣe rere. Ẹni tí ó bá ń ṣe rere ti Ọlọ́run ni; ẹni tí ó ba ń ṣe búburú kò rí Ọlọ́run. 1212: Jh 21.24.Demetriusi ní ẹ̀rí rere lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn àti ní ti òtítọ́ fúnrarẹ̀ pẹ̀lú; nítòótọ́, àwa pẹ̀lú sì gba ẹ̀rí rẹ̀ jẹ́; ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí wa.

1313: 2Jh 12.Èmí ní ohun púpọ̀ láti kọ sínú ìwé sí ọ, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ fi kálàmù àti tawada kọ wọ́n sínú ìwé. 14Mo ni ìrètí láti rí ọ láìpẹ́, tí àwa yóò sì sọ̀rọ̀ lójúkojú.

15Àlàáfíà fún ọ.

Àwọn ọ̀rẹ́ wa tó wà níbí kí ọ. Kí àwọn ọ̀rẹ́ wa tó wà lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.