民数记 9 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

民数记 9:1-23

逾越节

1以色列人离开埃及后第二年的一月,耶和华在西奈旷野对摩西说: 2以色列人要在指定的时间守逾越节, 3就是在一月十四日黄昏按照有关的律例和典章守逾越节。” 4于是,摩西吩咐以色列人守逾越节。 5一月十四日黄昏,以色列人照耶和华对摩西的吩咐,在西奈山守逾越节。

6可是,有几个人因碰到死尸而不洁净,不能在那天守逾越节,他们就来见摩西亚伦7说:“我们不过因碰到死尸而不洁净,为什么不准我们跟其他以色列人一起在指定的时间向耶和华献供物?” 8摩西说:“你们等一下,我要去听听耶和华对这事有什么吩咐。”

9耶和华对摩西说: 10“你把以下条例告诉以色列人。

“如果你们或你们的子孙中有人因为碰了死尸而不洁净,或是出了远门,可以改期为耶和华守逾越节。 11他们可以在二月十四日黄昏守逾越节,要配无酵饼和苦菜一起吃逾越节的羊羔。 12食物不可留到天明,也不可折断羊羔的一根骨头。要遵守逾越节的一切律例。 13如果有人是洁净的,又没有出远门,却不守逾越节,要将他从民中铲除。他不在指定的时间向耶和华献供物,就必须自负罪责。 14如果寄居在你们中间的外族人也想为耶和华守逾越节,他们也要遵守这些律例和典章。不论是外族人还是以色列人,都要遵守同样的律例。”

云彩遮盖会幕

15安放约柜的圣幕支起来那天,云彩遮盖了它。当晚,云彩整夜像火焰一般。 16之后,每天如此:白天云彩遮盖圣幕,晚上云彩像火。 17云彩什么时候从圣幕上升起,以色列人就启行;云彩在哪里停下来,以色列人就在哪里安营。 18他们无论启行还是安营,都遵照耶和华的吩咐。云彩在圣幕上停留多久,他们就安营多久。 19有时云彩在圣幕上停留多日,他们就遵照耶和华的吩咐安营多日。 20有时云彩在圣幕上只停留几天,他们就遵照耶和华的吩咐只安营几天。随后再照耶和华的吩咐启行。 21有时云彩整夜停留在圣幕上,到早晨才升起,他们就早晨才启行。不管白天黑夜,云彩一升起,他们就启行。 22不管是两天、一个月或是一年,只要云彩停留在圣幕上,以色列人就安营不动;云彩一升起,他们就启行。 23他们遵照耶和华的吩咐安营,也遵照耶和华的吩咐启行。他们遵行耶和华借摩西吩咐的话。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 9:1-23

Àsè ìrékọjá

19.1-5: El 12.1-14,21-28.Olúwa sọ fún Mose nínú aginjù Sinai ní oṣù kìn-ín-ní ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wí pé; 2“Mú kí àwọn ọmọ Israẹli máa pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní àsìkò rẹ̀. 3Ẹ ṣe é ní àsìkò rẹ̀ gan an ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀.”

4Mose sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n máa pa àjọ ìrékọjá mọ́. 5Wọ́n sì ṣe àjọ ìrékọjá ní aginjù Sinai ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

6Àwọn díẹ̀ nínú wọn kò lè ṣe àjọ Ìrékọjá lọ́jọ́ náà nítorí pé wọ́n di aláìmọ́ nítorí òkú ènìyàn. Nítorí èyí wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose àti Aaroni lọ́jọ́ náà. 7Wọ́n sọ fún Mose pé, “A di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ló dé tí a kò fi ní í le è fi ọrẹ wa fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ará Israẹli yòókù ní àsìkò tí a ti yàn.”

8Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró kí n ba lè mọ ohun tí Olúwa yóò pàṣẹ nípa yín.”

9Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, 10“Sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘Bí ẹnìkan nínú yín tàbí nínú ìran yín bá di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn tàbí bí ó bá lọ sí ìrìnàjò síbẹ̀ yóò pa àjọ Ìrékọjá Olúwa mọ́. 11Wọn yóò ṣe tiwọn ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì. Wọn yóò jẹ ẹran náà, pẹ̀lú àkàrà aláìwú àti ewúro. 129.12: Ek 12.46; Jh 19.36.Wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀, wọn kò sì gbọdọ̀ ṣẹ́ eegun rẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé gbogbo ìlànà fún ṣíṣe àjọ Ìrékọjá. 13Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan tó wà ní mímọ́ tí kò sì lọ sí ìrìnàjò bá kọ̀ láti pa àjọ Ìrékọjá mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí pé kò mú ọrẹ Olúwa wá ní àsìkò tí ó yẹ. Ẹni náà yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

14“ ‘Bí àlejò tí ń gbé láàrín yín bá fẹ́ ṣe Àjọ Ìrékọjá Olúwa, ó gbọdọ̀ pa á mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin rẹ̀. Ìlànà kan náà ni kí ẹ ní fún àlejò àti àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ yín.’ ”

Ìkùùkuu lórí àgọ́

159.15-23: El 40.36-38.Ní ọjọ́ tí wọ́n gbé àgọ́ ró, èyí tí í ṣe àgọ́ ẹ̀rí, dúró, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ bò ó mọ́lẹ̀. Ìkùùkuu náà sì dàbí iná ní orí àgọ́ láti ìrọ̀lẹ́ títí di òwúrọ̀. 16Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí nígbà gbogbo; ìkùùkuu bò ó, àti pé ní alẹ́ ìrísí rẹ̀ sì dàbí iná. 17Nígbàkígbà tí ìkùùkuu yìí bá ká sókè kúrò lórí àgọ́ ni àwọn ọmọ Israẹli yóò dìde láti máa lọ; ibikíbi tí ìkùùkuu náà bá dúró sí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò pa ibùdó wọn sí. 18Nípa àṣẹ Olúwa ni àwọn ọmọ Israẹli ń jáde lọ, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń pa ibùdó wọn. Nígbà tí ìkùùkuu bá dúró sórí àgọ́, àwọn náà yóò dúró sí ibùdó. 19Nígbà tí ìkùùkuu bá dúró sórí àgọ́ fún ìgbà pípẹ́, síbẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa wọn kò sì ní gbéra láti lọ. 20Ìgbà mìíràn ìkùùkuu lè wà lórí àgọ́ fún ọjọ́ díẹ̀; síbẹ̀ ní àṣẹ Olúwa, wọn yóò dúró ní ibùdó, bí ó sì tún yá, ní àṣẹ rẹ̀ náà ni wọn yóò gbéra. 21Ìgbà mìíràn ìkùùkuu lè dúró láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀, nígbà tó bá ṣí kúrò ní àárọ̀, wọn ó gbéra. Ìbá à ṣe ní ọ̀sán tàbí òru, ìgbàkígbà tí ìkùùkuu bá tó kúrò náà ni wọn ó tó gbéra. 22Ìbá à ṣe fún ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí ọdún kan ni ìkùùkuu fi dúró sórí àgọ́, àwọn ọmọ Israẹli yóò dúró ní ibùdó wọn, wọn kò ní gbéra; ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá lọ sókè ni wọn ó tó o gbéra. 23Nípa àṣẹ Olúwa ni wọ́n ń pa ibùdó wọn, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń gbéra. Wọ́n gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.