民数记 27 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

民数记 27:1-23

女儿的继承权

1西罗非哈约瑟之子玛拿西的玄孙、玛吉的曾孙、基列的孙子、希弗的儿子。他的女儿是玛拉挪阿曷拉密迦得撒。她们前来, 2站在会幕门口对摩西以利亚撒祭司、众首领和全体会众说: 3“我们的父亲死在旷野,他并没有跟可拉一伙一起反叛耶和华,而是因自己的罪而死,没有留下儿子。 4难道因为他没有儿子,他的名字就要从族中消失吗?请让我们在父亲的家族中分一份产业吧。” 5摩西就把她们的请求呈到耶和华面前。 6耶和华对摩西说: 7西罗非哈的女儿说得有理。你要从她们父亲的家族中分一份产业给她们,让她们继承父亲的产业。 8你要告诉以色列人,‘人死后如果没有儿子,就由女儿继承产业; 9如果没有女儿,就由其兄弟继承; 10如果没有兄弟,就由其父的兄弟继承; 11如果其父没有兄弟,就由其族中最近的亲属继承。’”这是耶和华吩咐摩西颁布给以色列人的律例。

约书亚接替摩西做首领

12耶和华对摩西说:“你上亚巴琳山去眺望我赐给以色列人的土地。 13看了以后,你就要像你哥哥亚伦一样去祖先那里了。 14因为会众在旷野反叛我的时候,你们二人没有按照我的指示取水,没有在他们面前尊我为圣。”耶和华指的是米利巴泉事件,发生在旷野的加低斯15摩西对耶和华说: 16“耶和华啊,你是赐人生命的上帝,求你立一个人做会众的首领, 17带领他们或进或退,免得你的会众像没有牧人的羊群。” 18耶和华对摩西说:“的儿子约书亚心里有圣灵,你把他召来,按手在他身上, 19让他站在以利亚撒祭司和全体会众面前,当着他们的面任命他做首领, 20把你的权柄赐给他,使以色列全体会众都听从他。 21遇到事情,他要去以利亚撒祭司那里,让祭司借着乌陵为他求问我。他和全体会众或进或出都要听从以利亚撒的指示。” 22摩西遵命而行,把约书亚召来,让他站在以利亚撒祭司和全体会众面前, 23然后照耶和华的吩咐按手在他的头上,任命他做首领。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 27:1-23

Ọmọbìnrin Ṣelofehadi

127.1-11: Nu 36.1-12.Ọmọbìnrin Ṣelofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri ọmọ Manase tó jẹ́ ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu wá. Orúkọ àwọn ọmọbìnrin náà ni Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa. 2Wọ́n súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé wọ́n sì dúró níwájú Mose, àti Eleasari àlùfáà, àti níwájú àwọn olórí àti ìjọ, wọ́n sì wí pé, 3“Baba wa kú sí aginjù. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa, Ṣùgbọ́n ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀. 4Kín ni ó dé tí orúkọ baba wa yóò parẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkùnrin? Fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrín àwọn arákùnrin baba wa.”

5Nígbà náà Mose mú ọ̀rọ̀ wọn wá síwájú Olúwa. 6Olúwa sì wí fún un pé, 7“Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi ń sọ tọ̀nà. Ogbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn.

8“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú tí kò sì fi ọmọkùnrin sáyé, ẹ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀. 9Tí kò bá ní ọmọbìnrin, fi ohun ìní rẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. 10Tí kò bá ní arákùnrin, fi ogún ìní rẹ̀ fún arákùnrin baba rẹ̀. 11Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀. Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.’ ”

Joṣua láti rọ́pò Mose

1227.12-14: De 3.23-27; 32.48-52.Nígbà náà Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sì orí òkè Abarimu yìí, kí o sì lọ wo ilẹ̀ tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli. 13Lẹ́yìn ìgbà tí o bá sì ti rí i, ìwọ náà yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bí Aaroni arákùnrin rẹ ṣe ṣe, 14nítorí nígbà tí ìlú ṣọ̀tẹ̀ níbi omi ní Aginjù Sini, tí gbogbo yín ṣe àìgbọ́ràn sí mi láti yà mí sí mímọ́ níwájú wọn.” (Èyí ni omi Meriba ní Kadeṣi ní aginjù Sini.)

15Mose sọ fún Olúwa wí pé, 16“Jẹ́ kí Olúwa, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, kí ó yan ọkùnrin kan sí orí ìjọ ènìyàn yìí 17Láti máa darí wọn, ẹni tí yóò mú wọn jáde, tí yóò sì mú wọn wọlé, gbogbo ènìyàn Olúwa kí yóò dàbí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.”

1827.18-23: De 3.28.Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú Joṣua ọmọ Nuni, ọkùnrin nínú ẹni tí èmi wà, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e. 19Jẹ́ kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti ojú gbogbo àwọn ìjọ ènìyàn Israẹli kí o sì fi àṣẹ fún un ní ojú wọn. 20Kí ìwọ kí ó sì fi nínú ọláńlá rẹ sí i lára, kí gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli kí ó lè gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu. 21Kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà, tí yóò gba ìpinnu fún láti béèrè Urimu níwájú Olúwa. Gẹ́gẹ́ bí òfin yìí ni òun pẹ̀lú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli yóò jáde lọ, pẹ̀lú òfin rẹ̀ sì ni wọn ó wọlé.”

22Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un. Ó mú Joṣua ó sì mú kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti níwájú gbogbo ìjọ. 2327.23: De 31.23.Nígbà náà ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, ó sì fi àṣẹ fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.