撒迦利亚书 14 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

撒迦利亚书 14:1-21

耶和华的日子

1看啊,耶和华的日子快到了,那时你那里的财物必被抢掠、瓜分。 2因为我必招聚万国去攻打耶路撒冷。那时,城必失守,房屋必被洗劫,妇女必被玷污。半城的人必被掳去,剩下的人必留在城中,不会被铲除。 3那时,耶和华必出来与列国争战,像从前争战的日子一样。 4到那天,祂的脚必踏在耶路撒冷东面的橄榄山上,这山必从东至西分成两半,一半向北移,一半向南移,中间形成极大的山谷。 5你们要从我的这山谷逃跑,因为山谷必延伸到亚萨。你们必像犹大乌西雅年间的人躲避大地震一样逃跑。我的上帝耶和华必带着所有的圣者降临。 6到那天,将没有光、严寒和冰霜。 7那将是奇特的日子,没有昼夜之分,晚上仍然有光,只有上帝知道那日何时来临。

8到那天,必有活水从耶路撒冷涌出,一半流向死海,一半流向地中海,冬夏不变。 9耶和华必做普世的王。到那天,必唯祂独尊,唯祂的名独尊。 10迦巴直到耶路撒冷南边的临门,整个地区都要变为平原。从便雅悯门到旧门,再到角门,从哈楠业楼到王的榨酒池——耶路撒冷必仍然矗立在原处。 11城内必有人居住,不再遭毁灭的咒诅。耶路撒冷必安享太平。

12耶和华必降瘟疫给攻打耶路撒冷的列邦,使他们活着的时候皮肉已经腐烂,眼睛在眼眶中腐烂,舌头在口中腐烂。 13到那天,耶和华必使他们慌乱不堪,彼此揪住,互相殴打。 14犹大也必在耶路撒冷争战,四围列国的财物——大量的金银和衣服必被收聚起来。 15同样的瘟疫也必降在马匹、骡子、骆驼、驴和营中的其他牲畜身上。

16前来攻打耶路撒冷的列国中的幸存者,必每年上来敬拜大君王——万军之耶和华,并且守住棚节。 17地上万族中若有人不上耶路撒冷敬拜大君王——万军之耶和华,他们必没有雨水。 18埃及人若不上来敬拜,也必没有雨水,耶和华必使他们和不上来守住棚节的列国一样遭受瘟疫。 19这将是埃及和不上来守住棚节的列国所得的惩罚。 20到那天,马铃上也必刻上“献给耶和华”的字样。耶和华殿内的锅必像祭坛前的碗一样圣洁。 21耶路撒冷犹大的锅都是万军之耶和华的圣物,来献祭的人都可以用这些锅煮祭肉。到那天,万军之耶和华的殿中必再也没有商人。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Sekariah 14:1-21

Olúwa Wa Jọba

1Kíyèsi i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀, a ó sì pín ìkógun rẹ̀ láàrín rẹ̀.

2Nítorí èmi ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí Jerusalẹmu fún ogun; a ó sì ko ìlú naà, a ó sì kó àwọn ilé, a ó sì ba àwọn obìnrin jẹ́, ààbọ̀ ìlú náà yóò lọ sí ìgbèkùn, a kì yóò sì gé ìyókù àwọn ènìyàn náà kúrò ni ìlú náà. 3Nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ, yóò sì bá àwọn orílẹ̀-èdè náà jà, gẹ́gẹ́ bí í ti ìjà ní ọjọ́ ogun. 4Ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Olifi, tí ó wà níwájú Jerusalẹmu ni ìlà-oòrùn, òkè Olifi yóò sì là á sí méjì, sí ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, Àfonífojì ńláńlá yóò wà: ìdajì òkè náà yóò sì ṣí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúúsù. 5Ẹ̀yin ó sì sá sí àfonífojì àwọn òkè mi: nítorí pé àfonífojì òkè náà yóò dé Aseli: nítòótọ́, ẹ̀yin ó sá bí ẹ tí sá fún ìmìmì-ilẹ̀ ni ọjọ́ Ussiah ọba Juda: Olúwa Ọlọ́run mi yóò sì wá, àti gbogbo àwọn Ẹni mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.

6Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìmọ́lẹ̀ kì yóò mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣókùnkùn. 7Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ ọjọ́ kan mímọ́ fún Olúwa, kì í ṣe ọ̀sán, kì í ṣe òru; ṣùgbọ́n yóò ṣe pé, ni àṣálẹ́ ìmọ́lẹ̀ yóò wà.

8Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jerusalẹmu sàn lọ; ìdajì wọn síhà Òkun ìlà-oòrùn, àti ìdajì wọn síhà okùn ẹ̀yìn: nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀.

9Olúwa yóò sì jẹ ọba lórí gbogbo ayé; ni ọjọ́ náà ni Olúwa kan yóò wa orúkọ rẹ̀ nìkan náà ni orúkọ.

10A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Geba dé Rimoni lápá gúúsù Jerusalẹmu: yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jerusalẹmu sókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Benjamini títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé ibi ìfúntí wáìnì ọba. 1114.11: If 22.3.Ènìyàn yóò sì máa gbé ibẹ̀, kì yóò sì sí ìparun mọ́; ṣùgbọ́n a ó máa gbé Jerusalẹmu láìléwu.

12Èyí ni yóò sì jẹ́ ààrùn tí Olúwa yóò fi kọlu gbogbo àwọn ènìyàn ti ó tí ba Jerusalẹmu jà; ẹran-ara wọn yóò rù nígbà tí wọn dúró ni ẹsẹ̀ wọn, ojú wọn yóò sì rà ni ihò wọn, ahọ́n wọn yóò sì bàjẹ́ ni ẹnu wọn. 13Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò wà láàrín wọn; wọn ó sì di ọwọ́ ara wọn mú, ọwọ́ èkínní yóò sì dìde sì ọwọ́ èkejì rẹ̀. 14Juda pẹ̀lú yóò sì jà ni Jerusalẹmu: ọrọ̀ gbogbo àwọn kèfèrí tí ó wà káàkiri ni a ó sì kójọ, wúrà àti fàdákà, àti aṣọ, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. 15Bẹ́ẹ̀ ni ààrùn ẹṣin, ìbáaka, ìbákasẹ, àti tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, yóò sì wà, àti gbogbo ẹranko tí ń bẹ nínú àgọ́.

16Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ẹni tí o kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dìde sí Jerusalẹmu yóò máa gòkè lọ lọ́dọọdún láti sìn ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà. 17Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí kì yóò gòkè wá nínú gbogbo ìdílé ayé sí Jerusalẹmu láti sín ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, òjò kì yóò rọ̀ fún wọn. 1814.18-19: Isa 19; Jr 46; El 29–32.Bí ìdílé Ejibiti kò bá sì gòkè lọ, tí wọn kò sì wá, fi ara wọn hàn tí wọn kò ní òjò; ààrùn náà yóò wà, tí Olúwa yóò fi kọlù àwọn kèfèrí tí kò gòkè wá láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà 19Èyí ni yóò sì jẹ́ ìyà Ejibiti, àti ìyà gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti pa àsè àgọ́ mọ́.

20Ní ọjọ́ náà ni “mímọ́ sí Olúwa” yóò wà lára ṣaworo ẹṣin: àti àwọn ìkòkò ni ilé Olúwa yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ. 21Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jerusalẹmu àti ni Juda yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun: àti gbogbo àwọn tí ń rú ẹbọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kenaani kò ní sí mọ́ ni ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun.