撒迦利亚书 12 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

撒迦利亚书 12:1-14

耶路撒冷必蒙拯救

1以下是耶和华关于以色列的启示。

铺展穹苍、奠立大地的根基、塑造人灵魂的耶和华说: 2“看啊,我要使耶路撒冷成为令周围万民昏醉的酒杯。耶路撒冷被围困时,犹大也必受困。 3到那天,当地上的列国聚集起来攻击耶路撒冷的时候,我要使耶路撒冷成为一块沉重的石头。凡试图举起它的,必伤自己。 4到那天,我要使所有的战马惊恐,使马上的骑士癫狂。我必看顾犹大家,使列邦的马匹瞎眼。这是耶和华说的。 5那时,犹大的族长必心里说,‘耶路撒冷的居民从他们的上帝——万军之耶和华那里得到了力量。’

6“到那天,我必使犹大的族长像木柴中的火盆,像禾捆中的火把,吞噬左右四围的列邦,但耶路撒冷人必仍在原处——耶路撒冷安居。

7“耶和华必首先拯救犹大的帐篷,免得大卫家和耶路撒冷居民的荣耀超过犹大8到那天,耶和华必保护耶路撒冷的居民,使他们当中最软弱的像大卫一样刚强,使大卫家像上帝一样,像耶和华的天使一样带领他们。 9到那天,我必毁灭前来攻击耶路撒冷的列国。

10“我必将施恩和祷告的灵浇灌在大卫家和耶路撒冷的居民身上。他们必仰望我——他们所刺的那位,如丧独子一般为祂哀伤,如丧长子一般为祂痛哭。 11到那天,耶路撒冷必一片哀声,犹如米吉多平原的哈达临门的哀声。 12境内家家户户都必哀哭。大卫家的男子在一处,女子在一处;拿单家的男子在一处,女子在一处; 13利未家的男子在一处,女子在一处;示每家的男子在一处,女子在一处。 14其余各家也都哀哭,男女分开。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Sekariah 12:1-14

A o pa àwọn ọ̀tá Jerusalẹmu run

1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀: Ọ̀rọ̀ Olúwa fún Israẹli ni.

Olúwa wí, ẹni tí ó na àwọn ọ̀run, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ó sì da ẹ̀mí ènìyàn tí ń bẹ ni inú rẹ̀: 2“Kíyèsi í, èmi yóò sọ Jerusalẹmu dí àgọ́ ìwárìrì sí gbogbo ènìyàn yíká, nígbà tí wọn yóò dó ti Juda àti Jerusalẹmu. 3Ní ọjọ́ náà, nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé bá parapọ̀ sí i, ni èmi yóò sọ Jerusalẹmu di òkúta ti ko ṣe yí kúrò fún gbogbo ènìyàn: gbogbo àwọn tí ó bá sì fẹ́ yí i ni a ó gé sí wẹ́wẹ́, 4ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Ni èmi yóò fi ìdágìrì lu gbogbo ẹṣin, àti fi òmùgọ̀ kọlu ẹni tí ń gun un; èmi yóò sì ṣí ojú mi sí ilé Juda, èmi yóò sì bu ìfọ́jú lu gbogbo ẹṣin tí orílẹ̀-èdè. 5Àti àwọn baálẹ̀ Juda yóò sì wí ni ọkàn wọn pé, ‘Àwọn ara Jerusalẹmu ni agbára mi nípa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run wọn.’

6“Ní ọjọ́ náà, ni èmi yóò ṣe àwọn baálẹ̀ Juda bí ààrò iná kan láàrín igi, àti bi ẹ̀fúùfù iná láàrín ìtí; wọn yóò sì jẹ gbogbo àwọn ènìyàn run yíká lápá ọ̀tún àti lápá òsì: a ó sì tún máa gbé inú Jerusalẹmu ní ipò rẹ̀.

7Olúwa pẹ̀lú yóò kọ́ tètè gba àgọ́ Juda là ná, kí ògo ilé Dafidi àti ògo àwọn ara Jerusalẹmu má ba gbé ara wọn ga sí Juda. 8Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò dáàbò bò àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu; ẹni tí ó bá sì ṣe àìlera nínú wọn ní ọjọ́ náà, yóò dàbí Dafidi; ilé Dafidi yóò sì dàbí Ọlọ́run, bí angẹli Olúwa níwájú wọn. 9Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, èmi yóò wá láti pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run tí ó wá kọjú ìjà sí Jerusalẹmu.”

Ìṣọ̀fọ̀ fún ọba wọn tí wọn gún lọ́kọ̀

1012.10: Jh 19.37.“Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ sórí ilé Dafidi àti sórí Jerusalẹmu: wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń ṣọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀. 11Ní ọjọ́ náà ni ẹkún, ńláńlá yóò wà ni Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ọ̀fọ̀ Hadadi Rimoni ni Àfonífojì Megido. 12Ilẹ̀ náà yóò ṣọ̀fọ̀, ìdílé, kọ̀ọ̀kan fun ara rẹ, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dafidi lọ́tọ̀; àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Natani lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ́. 13Ìdílé Lefi lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Ṣimei lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀. 14Gbogbo àwọn ìdílé tí o kù, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.