撒母耳记上 19 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

撒母耳记上 19:1-24

扫罗试图杀大卫

1扫罗吩咐他儿子约拿单和众臣仆去杀掉大卫。但约拿单非常喜爱大卫2便告诉他,说:“我父亲要杀你,明天早上你要小心,找个僻静的地方躲起来。 3我会出去和父亲站在你藏身的田间,跟他提你的事,然后把消息告诉你。” 4约拿单就在父亲面前替大卫说好话,他说:“王不要伤害大卫,他从来没有对不起王,他所做的使王大受益处。 5他冒着生命危险去杀非利士人,耶和华使以色列人大获全胜,当时你看见了,非常欢喜,现在为什么要犯罪,枉杀无辜的大卫呢?” 6扫罗听了约拿单的话,就凭永活的耶和华起誓说:“我不杀大卫。” 7约拿单叫来大卫,把经过告诉他,带他去见扫罗大卫又像以前一样伺候扫罗

8后来,战事再度爆发,大卫领兵与非利士人交战,大败敌人,杀得他们四散溃逃。 9一天,扫罗手里拿着矛正坐在家中,从耶和华那里来的邪灵降临在扫罗身上。大卫正在弹琴, 10扫罗想用矛把大卫刺透,钉在墙上,大卫躲开了,矛插在了墙上。大卫当晚逃走了。

11扫罗派人监视大卫的家,要在早上杀死他。大卫的妻子米甲警告他说:“如果你今晚不逃命,明早必死无疑。” 12于是,她从窗口把大卫缒下去,让他逃走了。 13然后她把家中的神像放在床上,头枕在山羊毛的枕头上,盖上被子。 14扫罗派人来捉拿大卫的时候,米甲说他病了。 15扫罗又派人去见大卫,并吩咐说:“把他连床一起抬来,我好杀他。” 16众人进去发现躺在床上的是一个神像,头枕在山羊毛的枕头上。 17扫罗米甲:“你为什么欺骗我,让我的敌人逃走?”米甲答道:“他说如果我不让他逃走,就杀了我。”

18大卫逃到住在拉玛撒母耳那里,把扫罗的所作所为告诉他。后来,他和撒母耳拿约住了下来。 19扫罗听说大卫拉玛拿约20就派人去捉拿他。扫罗的人看到一群先知在说预言,撒母耳在当中带领他们。上帝的灵也临到扫罗的人,他们也说起预言来。 21扫罗听说后又派人去,派去的人也说起预言来。扫罗第三次派人去,派去的人同样说起预言来。 22最后扫罗亲自前往拉玛,走到西沽的大井,问撒母耳大卫在哪里,有人说在拉玛拿约23扫罗便去拉玛拿约。上帝的灵临到扫罗,他就一边走一边说起预言来,一直到拉玛拿约24他脱下自己的衣服,在撒母耳面前说起预言来。他赤身躺了一天一夜。因此有句俗语说:“扫罗也在先知当中吗?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Samuẹli 19:1-24

Saulu gbìyànjú láti pa Dafidi

1Saulu sọ fún Jonatani ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dafidi. Ṣùgbọ́n Jonatani fẹ́ràn Dafidi púpọ̀ 2Jonatani sì kìlọ̀ fún Dafidi pé, “Baba mi Saulu wá ọ̀nà láti pa ọ́, kíyèsi ara rẹ di òwúrọ̀ ọ̀la; lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀, kí o sì sápamọ́ sí ibẹ̀. 3Èmi yóò jáde lọ láti dúró ní ọ̀dọ̀ baba mi ní orí pápá níbi tí ó wà. Èmi yóò sọ̀rọ̀ fún un nípa à rẹ, èmi yóò sì sọ ohun tí òun bá wí fún ọ.”

4Jonatani sọ̀rọ̀ rere nípa Dafidi fún Saulu baba rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọba kí ó ṣe ohun tí kò dára fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀; nítorí tí kò ṣẹ̀ ọ́, ohun tí ó sì ṣe pé ọ púpọ̀. 5Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu nígbà tí ó pa Filistini. Olúwa ṣẹ́ ogun ńlá fún gbogbo Israẹli, ìwọ rí i inú rẹ dùn. Ǹjẹ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe dẹ́ṣẹ̀ sí Dafidi aláìṣẹ̀, tí ìwọ yóò fi pa á láìnídìí?”

6Saulu fetísí Jonatani, ó sì búra báyìí, “Níwọ́n ìgbà tí Olúwa bá ti ń bẹ láààyè, a kì yóò pa Dafidi.”

7Nítorí náà Jonatani pe Dafidi, ó sì sọ gbogbo àjọsọ wọn fún un. Ó sì mú un wá fún Saulu, Dafidi sì wà lọ́dọ̀ Saulu gẹ́gẹ́ bí i ti tẹ́lẹ̀.

8Lẹ́ẹ̀kan an sí i ogun tún wá, Dafidi sì jáde lọ, ó sì bá àwọn ara Filistini jà. Ó sì pa wọn pẹ̀lú agbára, wọ́n sì sálọ níwájú u rẹ̀.

9Ṣùgbọ́n ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí orí Saulu bí ó ti jókòó ní ilé e rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Bí Dafidi sì ti fọn ohun èlò orin olókùn, 10Saulu sì wá ọ̀nà láti gún un mọ́ ògiri pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Dafidi yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Saulu ti ju ọ̀kọ̀ náà mọ́ ara ògiri. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Dafidi sì fi ara pamọ́ dáradára.

11Saulu rán ènìyàn sí ilé Dafidi láti ṣọ́ ọ kí wọ́n sì pa á ní òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n Mikali, ìyàwó Dafidi kìlọ̀ fún un pé, “Tí o kò bá sá fún ẹ̀mí rẹ ní alẹ́ yìí, ní ọ̀la ni a yóò pa ọ́.” 12Nígbà náà Mikali sì gbé Dafidi sọ̀kalẹ̀ ó sì fi aṣọ bò ó. 13Mikali gbé ère ó sì tẹ́ e lórí ibùsùn, ó sì fi irun ewúrẹ́ sí ibi orí rẹ̀.

14Nígbà ti Saulu rán ènìyàn láti lọ fi agbára mú Dafidi, Mikali wí pé, “Ó rẹ̀ ẹ́.”

15Nígbà náà ni Saulu rán ọkùnrin náà padà láti lọ wo Dafidi ó sì sọ fún wọn pé, “Mú wa fún mi láti orí ibùsùn rẹ̀ kí èmi kí ó le pa á.” 16Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ère ni ó bá lórí ibùsùn àti irun ewúrẹ́ ní orí ère náà.

17Saulu wí fún Mikali pé, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí báyìí tí o sì jẹ́ kí ọ̀tá mi sálọ tí ó sì bọ́?”

Mikali sọ fún un pé, “Ó wí fún mi, ‘Jẹ́ kí èmi ó lọ. Èéṣe tí èmi yóò fi pa ọ́?’ ”

18Nígbà tí Dafidi ti sálọ tí ó sì ti bọ́, ó sì lọ sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama ó sì sọ gbogbo ohun tí Saulu ti ṣe fún un. Òun àti Samuẹli lọ sí Naioti láti dúró níbẹ̀. 19Ọ̀rọ̀ sì tọ Saulu wá pé, “Dafidi wà ní Naioti ní Rama,” 20Saulu sì rán àwọn ènìyàn láti fi agbára mú Dafidi wá ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Samuẹli dúró níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí, ẹ̀mí Ọlọ́run sì wá sórí àwọn arákùnrin Saulu àwọn náà sì ń sọtẹ́lẹ̀. 21Wọ́n sì sọ fún Saulu nípa rẹ̀, ó sì rán ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn lọ àwọn náà sì ń sọtẹ́lẹ̀. Saulu tún rán oníṣẹ́ lọ ní ìgbà kẹta, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní sọtẹ́lẹ̀. 22Nígbẹ̀yìn, òun fúnrarẹ̀ sì lọ sí Rama ó sì dé ibi àmù ńlá kan ní Seku. Ó sì béèrè, “Níbo ni Samuẹli àti Dafidi wà?”

Wọ́n wí pé, “Wọ́n wà ní ìrékọjá ní Naioti ní Rama.”

2319.23,24: 1Sa 10.11,12.Saulu sì lọ sí Naioti ni Rama. Ṣùgbọ́n, ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e lórí ó sì ń lọ lọ́nà, ó sì ń sọtẹ́lẹ̀ títí tí ó fi dé Naioti. 2419.24: 1Sa 10.11,12.Ó sì bọ́ aṣọ rẹ̀, òun pẹ̀lú sì ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú Samuẹli. Ó sì dùbúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà àti ní òru. Ìdí nìyìí tí àwọn ènìyàn fi wí pé, “Ṣé Saulu náà wà lára àwọn wòlíì ni?”