希伯来书 8 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

希伯来书 8:1-13

更美之约的大祭司

1我们所讲的要点是:我们有这样一位大祭司,祂现在已经坐在天上至高上帝的宝座右边, 2并在圣所里供职。这圣所就是真正的圣幕,不是人建立的,而是主亲手建立的。 3所有的大祭司都是为了向上帝献礼物和祭物而设立的,因此我们这位大祭司也必须有所献上。 4祂如果是在地上,根本不会做祭司,因为地上已经有照律法向上帝献礼物的祭司了。 5这些祭司的事奉都是仿效和反映天上的事,正如摩西建圣幕的时候,上帝指示他说:

“你务要照着在山上指示你的样式造各样的器具。”

6但如今,基督得到了一个更超越的职任,正如祂担任了更美之约的中保,这约是根据更美的应许所立的。 7因为如果第一个约没有缺点,就不必另立新约了。 8然而,上帝指责祂的百姓,说:

“看啊,时候将到,

我要与以色列家和犹大家另立新约,

9这约不同于我与他们祖先所立的约,

就是我牵着他们祖先的手领他们离开埃及时所立的。

因为他们不持守我的约,

所以我不再理会他们。

这是主说的。

10主又说,那些日子以后,

我将与以色列家立这样的约,

我要把我的律法放在他们脑中,

写在他们心上。

我要做他们的上帝,

他们要做我的子民。

11谁都无需再教导自己的邻居和弟兄,

说,‘你要认识主。’

因为他们无论尊卑都必认识我。

12我要赦免他们的过犯,

忘掉他们的罪恶。”

13上帝既然说要立新约,就是把以前的约当作旧的了,那渐渐过时、陈旧的东西很快就会消失。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Heberu 8:1-13

Olórí àlùfáà ti májẹ̀mú tuntun

18.1: Sm 110.1.Nísinsin yìí, kókó ohun tí à ń sọ nìyí: Àwa ní irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀, tí ó jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọláńlá nínú àwọn ọ̀run: 2ìránṣẹ́ ibi mímọ́, àti ti àgọ́ tòótọ́, tí Olúwa pa, kì í ṣe ènìyàn.

3Nítorí a fi olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan jẹ láti máa mú ẹ̀bùn wá láti máa rú ẹbọ: Nítorí náà ó ṣe pàtàkì fún eléyìí náà láti ní nǹkan tí ó máa fi sílẹ̀. 4Tí ó bá jẹ́ pé ó wà ní ayé ni, òun kì bá ti jẹ́ àlùfáà, nítorí pé àwọn ọkùnrin tí ó ń fi ẹ̀bùn sílẹ̀ ti wà bí òfin ṣe là á sílẹ̀. 58.5: Ek 25.40.Àwọn ẹni tí ń jọ́sìn nínú pẹpẹ kan tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ àti òjìji ohun tí ń bẹ ní ọ̀run. Ìdí abájọ nìyí tí a fi kìlọ̀ fún Mose nígbà tí ó fẹ́ kọ́ àgọ́: Nítorí ó wí pé, “Kíyèsí i, kí ìwọ kí ó ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ wọn, ti a fi hàn ọ́ ni orí òkè.” 6Ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó ni ọlá jù, níwọ̀n bí o ti jẹ pé alárinà májẹ̀mú tí o dára jù ní i ṣe, èyí tí a fi ṣe òfin lórí ìlérí tí o sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ.

7Nítorí ìbá ṣe pé májẹ̀mú ìṣáájú nì kò ní àbùkù, ǹjẹ́ a kì bá ti wá ààyè fún èkejì. 88.8-12: Jr 31.31-34.Nítorí tí ó rí àbùkù lára wọn, ó wí pé,

“Ìgbà kan ń bọ̀, ni Olúwa wí,

tí Èmi yóò bá ilé Israẹli

àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun.

9Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú

tí mo ti bá àwọn baba baba wọn dá,

nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ láti mú wọn jáde

kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, nítorí wọn kò jẹ́ olóòtítọ́ sí májẹ̀mú mi

èmi kò sì ta wọ́n nu, ni Olúwa wí

10Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli

dá lẹ́yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí.

Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn,

èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn,

èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn,

wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi.

11Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀,

tàbí olúkúlùkù arákùnrin rẹ̀, pé, ‘mọ Olúwa,’

Nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí,

láti kékeré dé àgbà.

12Nítorí pé èmi ó ṣàánú fún àìṣòdodo wọn,

àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn lèmi ki yóò sì rántí mọ́.”

13Ní èyí tí ó wí pé, májẹ̀mú títún ó ti sọ ti ìṣáájú di ti láéláé. Ṣùgbọ́n èyí tí ó ń di i ti láéláé tí ó sì ń gbó, o múra àti di asán.