历代志下 1 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

历代志下 1:1-17

所罗门王求智慧

1大卫的儿子所罗门巩固了自己的王位。因为他的上帝耶和华与他同在,使他极其伟大。

2所罗门召集所有以色列人,包括千夫长、百夫长、审判官、首领和族长, 3与他们一起去基遍的丘坛,因为那里有上帝的会幕,是耶和华的仆人摩西在旷野制造的。 4大卫已经把上帝的约柜从基列·耶琳搬到耶路撒冷,因为他在那里为约柜搭了一个帐篷。 5户珥的孙子、乌利的儿子比撒列造的铜坛在基遍耶和华的会幕前,所罗门和会众就在那里求问耶和华。 6所罗门上到耶和华会幕前的铜坛那里,献上一千头祭牲作为燔祭。

7当天晚上,上帝向所罗门显现,问他:“你要我给你什么?只管求吧。” 8所罗门回答说:“你厚待我父大卫,并让我继位。 9耶和华上帝啊,求你成就你给我父大卫的应许。你立我为王,使我统治这多如地上尘土的百姓。 10现在,求你赐我智慧和知识以带领他们。不然,谁能治理这么多的百姓呢?” 11上帝对所罗门说:“你既然有此心愿,不为自己求富贵、资财、尊荣、长寿,也没有求灭绝你的敌人,只求智慧和知识以治理我的子民——我交在你王权之下的百姓, 12我必赐你智慧和知识,并且我还要赐你空前绝后的富贵、资财和尊荣。”

13于是,所罗门基遍丘坛的会幕前回到耶路撒冷治理以色列

所罗门王的兵力和财富

14所罗门组建了战车和骑兵,有一千四百辆战车、一万二千名骑兵,驻扎在屯车城和他所在的耶路撒冷15王使耶路撒冷的金银多如石头,使香柏木多如丘陵的无花果树。 16所罗门的马匹都是由王室商队从埃及古厄按定价买来的。 17他们从埃及买来的车马,每辆车六百块银子,每匹马一百五十块银子,他们也把车马卖给人诸王和亚兰诸王。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 1:1-17

Solomoni béèrè fún ọgbọ́n

1Solomoni ọmọ Dafidi fìdí ara rẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lórí ìjọba rẹ̀. Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú u rẹ̀, ó sì jẹ́ kí ó ga lọ́pọ̀lọpọ̀.

2Nígbà náà, Solomoni bá gbogbo Israẹli sọ̀rọ̀ sí àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, sí àwọn adájọ́ àti sí gbogbo àwọn olórí Israẹli, àwọn olórí ìdílé 31.3-13: 1Ọb 3.4-15.Pẹ̀lú Solomoni, àti gbogbo àpéjọ lọ sí ibi gíga ní Gibeoni, nítorí àgọ́ Ọlọ́run fún pípàdé wà níbẹ̀, tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pa ní aginjù. 4Nísinsin yìí, Dafidi ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wá láti Kiriati-Jearimu sí ibi tí ó ti pèsè fún un, nítorí ó ti kọ́ àgọ́ fún un ni Jerusalẹmu. 5Ṣùgbọ́n pẹpẹ idẹ tí Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ṣe wà ní Gibeoni níwájú àgọ́ Olúwa: Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni àti gbogbo àpéjọ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ níbẹ̀. 6Solomoni gòkè lọ sí ibi pẹpẹ idẹ níwájú Olúwa ní ibi àgọ́ ìpàdé, ó sì rú ẹgbẹ̀rún ẹbọ sísun lórí rẹ̀.

7Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọ́run farahàn Solomoni, ó sì wí fún un pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ kí n fún ọ.”

8Solomoni dá Ọlọ́run lóhùn pé, “Ìwọ ti fi àánú ńlá han Dafidi baba mi, ìwọ sì ti fi mí jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 9Nísinsin yìí Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ìlérí rẹ sí baba à mi Dafidi wá sí ìmúṣẹ, nítorí ìwọ ti fi mí jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀. 10Fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀, kí èmi kí ó lè máa wọ ilé kí ń sì máa jáde níwájú ènìyàn wọ̀nyí, nítorí ta ni ó le è ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ tí ó pọ̀ yanturu wọ̀nyí?”

11Ọlọ́run wí fún Solomoni pé, “Níwọ́n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìfẹ́ ọkàn rẹ nìyí, tí ìwọ kò sì béèrè, fún ọrọ̀, ọlá tàbí ọ̀wọ̀, tàbí fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, àti nígbà tí ìwọ kò ti béèrè fún ẹ̀mí gígùn, ṣùgbọ́n tí ìwọ béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti ṣàkóso àwọn ènìyàn mi tí èmi fi ọ́ jẹ ọba lé lórí, 12Nítorí náà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ọrọ̀, ọlá àti ọ̀wọ̀, irú èyí tí ọba ti ó wà ṣáájú rẹ kò ní, tí àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ kò sì ní ní irú rẹ̀.”

13Nígbà náà ni Solomoni sì ti ibi gíga Gibeoni lọ sí Jerusalẹmu láti iwájú àgọ́ ìpàdé. Ó sì jẹ ọba lórí Israẹli.

141.14-17: 1Ọb 10.26-29.Solomoni kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ, ó sì ní ẹgbàáje kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàafà ẹlẹ́ṣin, tí ó kó pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ ogun àti pẹ̀lú rẹ̀ ni Jerusalẹmu 15Ọba náà ṣe fàdákà àti wúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti wọ́pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti kedari ó pọ̀ bí igi sikamore ní àwọn ẹsẹ̀ òkè. 16Àwọn ẹṣin Solomoni ní a gbà láti ìlú òkèrè Ejibiti àti láti kún ọ̀gbọ̀ oníṣòwò ti ọba ni gba okun náà ní iye kan. 17Wọ́n ra kẹ̀kẹ́ kan láti Ejibiti. Fún ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ṣékélì (6,000) fàdákà àti ẹṣin kan fún ọgọ́rin-méjì ó-dínláàdọ́ta. Wọ́n ko wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba mìíràn ti Hiti àti ti àwọn ará Aramu.