列王纪下 7 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

列王纪下 7:1-20

1以利沙说:“你们要听耶和华的话,耶和华说,‘明天这个时候,在撒玛利亚城门口,三公斤细面粉只卖十一克银子,六公斤大麦也卖十一克银子。’” 2一个搀扶王的将领对上帝的仆人说:“即使耶和华打开天上的窗户,也不可能发生这样的事!”以利沙说:“你必亲眼看见,却吃不到。”

撒玛利亚城获救

3城门口有四个麻风病人,他们商量说:“我们为什么坐在这里等死呢? 4如果我们进城,城里正闹饥荒,我们会饿死;但我们坐在这里也是死,不如去投靠亚兰军。如果他们不杀我们,我们就能活命;如若不然,死就死吧!” 5傍晚时分,他们动身去亚兰人的营地,到了营地外边,却发现人影全无。 6原来,主使亚兰人听见大队人马和战车的声音。他们以为以色列王雇用了人的诸王和埃及人的诸王来攻营, 7便在傍晚时分撇下帐篷、马和驴,弃营而逃。 8那几个麻风病人到了营地,走进一个帐篷,又吃又喝,把那里的金银和衣服拿走收藏起来,再回来进入另一个帐篷,把财物拿走收藏起来。

9后来,他们彼此说:“我们这样做不对。今天是个报好消息的日子,我们却不作声。若等到天亮,我们会受惩罚的。走,我们给王报信去。” 10他们就去喊城门守卫,对他们说:“我们到了亚兰人的营中,里面不见人影也没有人声,只有拴着的马和驴,帐篷依然在那里。” 11城门守卫就高声宣告消息,有人去禀告王。 12王连夜起来,对臣仆说:“我告诉你们是怎么回事。亚兰人知道我们正闹饥荒,就故意离开军营,埋伏在田野,等我们以色列人出城后,好活捉我们,并攻入城中。”

13一个臣仆说:“不如派人骑着城中仅存的五匹马出去打探一下。反正他们和城中剩下的以色列人一样快要死了。” 14他们预备了两辆马车,王便命人出去追踪亚兰军、查明实情。 15探子一路追到约旦河,沿路看见到处都是亚兰军仓皇逃走时丢弃的衣服和装备,便回去禀告王。 16于是,民众出城抢掠亚兰人的营地。那时,三公斤细面粉只卖十一克银子,六公斤大麦也只卖十一克银子,正如耶和华所言。 17王派那位搀扶他的将领守在城门口维持秩序,那将领却被涌出的人群踩死,应验了上帝的仆人在王去见他时所说的话。 18上帝的仆人曾对王说:“明天这个时候,在撒玛利亚城门口,三公斤细面粉只卖十一克银子,六公斤大麦也只卖十一克银子。”

19但那将领对上帝的仆人说:“即使耶和华打开天上的窗户,也不可能发生这样的事!”上帝的仆人说:“你必亲眼看见,却吃不到。” 20这话果然应验在他身上,他被人群踩死在城门口。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 7:1-20

1Eliṣa wí pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: Ní àsìkò yìí ní ọ̀la, a ó ta òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun barle kíkúnná kan ní ṣékélì kan àti méjì òṣùwọ̀n ọkà barle fún ṣékélì kan ní ẹnu-bodè Samaria.”

2Ìjòyè kan ẹni tí ọwọ́ ọba ń fi ara tì dáhùn wí fún ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ẹ wò ó, tí Olúwa bá tilẹ̀ ṣí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, ṣé èyí lè rí bẹ́ẹ̀?”

“Ìwọ yóò rí i pẹ̀lú ojú rẹ,” Eliṣa dáhùn, “ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ nǹkan kan lára rẹ̀!”

Ìgbóguntì náà kúrò

3Nísinsin yìí àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan wà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀ ní ẹnu àbáwọlé ibodè ìlú. Wọ́n wí fún olúkúlùkù pé, “kí ni ó dé tí àwa yóò fi jókòó síbí títí àwa yóò fi kú? 4Tí àwa bá wí pé, ‘Àwa lọ sí ìlú, ìyàn wà níbẹ̀,’ àwa yóò sì kú. Tí àwa bá dúró níbí, a máa kú, ǹjẹ́ Nísinsin yìí ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibùdó ti àwọn ará Siria kí àwa kí ó sì tẹríba. Bí wọ́n bá dá wa sí, àwa yóò yè, tí wọ́n bá sì pa wá, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò kú.”

5Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n dìde wọ́n sì lọ sí ibùdó àwọn ará Siria. Nígbà tí wọ́n dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó náà, kò sí ọkùnrin kan níbẹ̀, 6nítorí tí Olúwa jẹ́ kí àwọn ará Siria gbọ́ ìró kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin àti ogun ńlá, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wò ó, ọba Israẹli ti bẹ ogun àwọn Hiti àti àwọn ọba Ejibiti láti dojúkọ wá!” 7Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì dìde wọ́n sì sálọ ní àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n sì fi àgọ́ wọn sílẹ̀ àti ẹṣin wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n sì fi ibùdó sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà, wọ́n sì sálọ fún ẹ̀mí wọn.

8Nígbà tí àwọn ọkùnrin tí ó ní ààrùn ẹ̀tẹ̀ dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó wọ́n sì wọ inú ọ̀kan nínú àgọ́ náà. Wọ́n jẹ wọ́n sì mu, wọ́n sì kó fàdákà, wúrà àti ẹ̀wù, wọ́n sì lọ. Wọ́n sì wọ àgọ́ mìíràn lọ, wọ́n kó àwọn nǹkan láti ibẹ̀ wọ́n sì kó wọn pamọ́ pẹ̀lú.

9Nígbà náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Àwa kò ṣe ohun rere. Òní yìí jẹ́ ọjọ́ ìròyìn rere àwa sì pa á mọ́ ara wa. Tí àwa bá dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́, ìjìyà yóò jẹ́ ti wa. Ẹ jẹ́ kí a lọ ní ẹ̀ẹ̀kan kí a lọ ròyìn èyí fún àwọn ilé ọba.”

10Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì lọ wọ́n sì pe àwọn asọ́bodè ìlú, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Àwa lọ sí ibùdó àwọn ará Siria kò sì sí ọkùnrin kankan níbẹ̀ tàbí ohùn ènìyàn kan àyàfi ẹṣin tí a so àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn àgọ́ náà sì wà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà.” 11Àwọn aṣọ́bodè náà pariwo ìròyìn náà, wọ́n sì sọ nínú ààfin ọba.

12Ọba sì dìde ní òru ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò sọ fún yín ohun tí àwọn ará Siria tí ṣe fún wa. Wọ́n mọ̀ wí pé ebi ń pa wá; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ti kúrò ni ibùdó láti sápamọ́ sí ẹ̀gbẹ́ ilé, wọ́n rò wí pé, ‘Wọn yóò jáde lóòtítọ́, nígbà náà àwa yóò mú wọn ní ààyè, àwa yóò sì wọ inú ìlú lọ.’ ”

13Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dáhùn pé, “Èmí o bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí àwa kí ó mú márùn-ún nínú àwọn ẹṣin tí ó kù, nínú àwọn tí ó kù ní ìlú—kíyèsí i, wọ́n sá dàbí gbogbo àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ Israẹli tí ó kù nínú rẹ̀, kíyèsí i, àní bí gbogbo ènìyàn Israẹli tí a run, sí jẹ́ kí a rán wọn lọ láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.”

14Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan kẹ̀kẹ́ méjì pẹ̀lú ẹṣin wọn, ọba sì ránṣẹ́ tọ ogun àwọn ará Siria lẹ́yìn ó pàṣẹ fún àwọn awakọ̀ pé, “Ẹ lọ kí ẹ lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.” 15Wọ́n sì tẹ̀lé wọn títí dé Jordani, wọ́n sì rí gbogbo ọ̀nà kún fún agbádá pẹ̀lú ohun èlò tí ará àwọn Siria gbé sọnù ní yàrá wọn. Ìránṣẹ́ náà padà ó sì wá sọ fún ọba. 16Nígbà náà àwọn ènìyàn jáde lọ ìkógun ní ibùdó àwọn ará Siria. Bẹ́ẹ̀ ni òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kan ni wọ́n tà fún ṣékélì kan, àti òṣùwọ̀n barle méjì ní ṣékélì kan, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.

17Nísinsin yìí ọba sì mú ìjòyè náà lórí ẹni tí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ tì ní ìkáwọ́ ẹnu ibodè, àwọn ènìyàn sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ẹnu ibodè. Ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọtẹ́lẹ̀ nígbà tí ọba sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀. 18Ó sì ti ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún ọba: “Ní àsìkò yìí ní ọ̀la, òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ni a ó ta nì ṣékélì kan àti òṣùwọ̀n méjì barle ní ṣékélì kan ní ẹnu-ọ̀nà ibodè Samaria.”

19Ìjòyè náà ti wí fún ènìyàn Ọlọ́run pé, “Wò ó, kódà ti Olúwa bá ṣí fèrèsé ní ọ̀run, ṣé èyí lè ṣẹlẹ̀?” Ènìyàn Ọlọ́run sì ti dáhùn pé, “kìkì ojú rẹ ni ìwọ yóò fi rí i, Ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ ọ̀kankan lára rẹ̀.” 20Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí fún un gẹ́lẹ́, nítorí tí àwọn ènìyàn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ẹnu ibodè, ó sì kú.