出埃及记 39 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

出埃及记 39:1-43

祭司的衣服

1比撒列按照耶和华对摩西的吩咐,用蓝色、紫色、朱红色的线精工制作在圣所供职时穿的礼服,又为亚伦制作圣衣。 2用金线和细麻线及蓝色、紫色、朱红色的线精工制作以弗得, 3把金子打成薄片,剪成细线,与细麻线和蓝色、紫色、朱红色的线巧妙地织在一起。 4他做了两条肩带,固定在以弗得两边,用来连接以弗得。 5又按耶和华对摩西的吩咐,照以弗得的做法用金线和细麻线及蓝色、紫色、朱红色的线精工制作腰带,缝在以弗得上。 6他选了两块红玛瑙,用刻图章的方法刻上以色列十二个儿子的名字,镶在两个金框里, 7再缝在以弗得的两条肩带上,作以色列人的纪念石。这些都是照耶和华对摩西的吩咐做的。

8他精工制作胸牌,与以弗得一样用金线和细麻线及蓝色、紫色、朱红色的线织成。 9胸牌呈正方形,叠成两层,长宽各二十二厘米。 10上面镶上四行宝石:第一行是红宝石、黄玉和翠玉; 11第二行是绿宝石、蓝宝石和金刚石; 12第三行是紫玛瑙、白玛瑙和紫晶; 13第四行是水苍玉、红玛瑙和碧玉。以上四行宝石都镶在胸牌的金框内。 14他用刻图章的方法,在十二颗宝石上刻上以色列儿子的名字,代表以色列的十二支派。

15他用纯金拧成两条像绳子一样的链子,连在胸牌上, 16又造两个金框和两个金环,把金环安在胸牌两端。 17把两条金链分别穿在两个金环里, 18又把两条金链的另一端分别连在以弗得前面肩带的两个金框上。 19在靠近以弗得内侧、胸牌下面的两端造了两个金环。 20在以弗得肩带下端、接近腰带的地方又造了两个金环。 21用一条蓝色的带子系住以弗得和胸牌上面的金环,使胸牌贴在精工织成的以弗得腰带上,不会从以弗得上松脱。这些都是照耶和华对摩西的吩咐做的。

22以弗得的外袍用纯蓝色的线织成, 23上面有领口,领口上织领边,像铠甲上的领口一样,免得领口破裂。 24外袍的底边用细麻线和蓝色、紫色、朱红色的线做成石榴状的饰物, 25又造纯金的铃铛挂在外袍底边的石榴间, 26一个石榴一个金铃铛,相间排列,围在外袍的底边。这件外袍是祭司供职时穿的,正如耶和华对摩西的吩咐。

27他用细麻布为亚伦父子们缝制内袍、 28礼冠、头巾和裤子, 29还用细麻线和蓝色、紫色、朱红色的线绣制腰带。这是照耶和华对摩西的吩咐做的。 30又用纯金造了牌子,就是圣冠,上面用刻图章的方法刻上“奉献给耶和华”的字样, 31然后用一条蓝色的带子把这个牌子系在礼冠上。这些都是照耶和华对摩西的吩咐做的。

圣幕完工

32圣幕,就是会幕的工作就这样全部完成了,都是以色列人照耶和华对摩西的吩咐做的。 33他们把圣幕和各样器具都送到摩西那里,即钩子、木板、横闩、柱子、带凹槽的底座; 34海狗皮顶盖、遮掩约柜的幔子、染成红色的公羊皮盖; 35约柜、抬约柜的横杠、施恩座; 36桌子、桌上的一切器具和供饼; 37纯金的灯台、灯盏、灯台的一切器具、灯油; 38金坛、膏油、芬芳的香;会幕的门帘; 39铜祭坛、祭坛的铜网、抬祭坛的横杠、祭坛用的一切器具、洗濯盆和盆座; 40院子的帷幔、柱子、带凹槽的底座、院子入口的门帘、绳子、橛子和会幕,即圣幕所需的一切器具; 41在圣所供职时穿的精制礼服、亚伦祭司的圣衣及其众子供祭司之职时穿的衣服。 42这一切都是以色列人照耶和华对摩西的吩咐做的。 43摩西察看这一切工作,见他们都是按照耶和华的吩咐做的,就给他们祝福。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 39:1-43

Aṣọ àlùfáà

1Nínú aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó ni wọ́n fi ṣe aṣọ híhun fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ibi mímọ́. Ó sì tún dá aṣọ mímọ́ fún Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Ẹ̀wù efodu

239.2-7: Ek 28.6-12.Ó ṣe ẹ̀wù efodu wúrà, ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. 3Ó sì lu wúrà náà di ewé fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì tún gé e láti fi ṣe iṣẹ́ sí aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó, àti sínú ọ̀gbọ̀ dáradára, iṣẹ́ ọlọ́nà. 4Ó ṣe aṣọ èjìká fún ẹ̀wù efodu náà, èyí tí ó so mọ igun rẹ̀ méjèèjì, nítorí kí ó lè so ó pọ̀. 5Ọnà ìgbànú híhun rẹ̀ rí bí i ti rẹ̀ ó rí bákan náà pẹ̀lú ẹ̀wù efodu ó sì sé e pẹ̀lú wúrà, àti pẹ̀lú aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

6Ó ṣiṣẹ́ òkúta óníkìsì tí a tò sí ojú ìdè wúrà, tí a sì fín wọn gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọ Israẹli. 7Ó sì so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù efodu náà bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Ìgbàyà

839.8-21: Ek 28.15-28.Ó ṣe iṣẹ́ ọnà sí ìgbàyà náà iṣẹ́ ọgbọ́n ọlọ́nà. Ó ṣe é bí ẹ̀wù efodu: ti wúrà ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. 9Igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé ìwọ̀n ìka kan ní ìnà rẹ̀, ìwọ̀n ìka kan ní ìbú rẹ̀, ó sì jẹ́ ìṣẹ́po méjì. 10Ó sì to ipele òkúta oníyebíye mẹ́rin sí i. Ní ipele kìn-ín-ní ní rúbì wà, topasi àti bereli; 11ní ipele kejì, turikuoṣe, safire, emeradi àti diamọndi; 12ní ipele kẹta, jasiniti, agate àti ametisiti; 13ní ipele kẹrin, karisoliti, óníkìsì, àti jasperi. Ó sì tò wọ́n ní ojú ìdè wúrà ní títò wọn. 14Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá, ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá.

15Fún ìgbàyà náà, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n iṣẹ́ kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bi okùn. 16Wọ́n sì ṣe ojú ìdè wúrà méjì àti òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so àwọn òkúta náà mọ́ igun méjèèjì ìgbàyà náà. 17Wọ́n sì so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì náà mọ́ àwọn òrùka náà ni igun ìgbàyà náà, 18àti ní àwọn òpin ẹ̀wọ̀n tókù ni wọ́n fi mọ ojú ìdè méjèèjì, wọ́n so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù efodu náà ní iwájú. 19Wọ́n ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so wọ́n mọ́ igun méjèèjì ìgbàyà náà ní etí tí ó wà ní inú lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀wù efodu náà. 20Wọ́n sì túnṣe òrùka wúrà méjì sí i, wọ́n sì so wọ́n mọ́ ìdí aṣọ èjìká ní iwájú ẹ̀wù efodu náà tí ó súnmọ́ ibi tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ní òkè ìgbànú ẹ̀wù efodu náà. 21Wọn so àwọn òrùka ìgbàyà mọ́ àwọn òrùka ẹ̀wù efodu ọ̀já aṣọ aláró, kí a pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, nítorí kí ìgbàyà náà má ṣe tú kúrò lára ẹ̀wù efodu náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Àwọn aṣọ àlùfáà mìíràn

2239.22-26: Ek 28.31-34.Ó sì ṣe ọ̀já àmùrè ẹ̀wù efodu gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ aláró iṣẹ́ aláṣọ híhun 23Pẹ̀lú ihò ní àárín ọ̀já àmùrè náà gẹ́gẹ́ bí i ojú kọ́là, àti ìgbànú yí ihò yìí ká, nítorí kí ó má ba à ya. 24Ó sì ṣe pomegiranate ti aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára yí ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká. 25Ó sì ṣe agogo kìkì wúrà, ó sì so wọ́n mọ́ àyíká ìṣẹ́tí àárín pomegiranate náà. 26Ago àti pomegiranate kọjú sí àyíká ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè láti máa wọ̀ ọ́ fún iṣẹ́ àlùfáà, bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

2739.27-29: Ek 28.39,40,42.Fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ, wọ́n ṣe àwọ̀tẹ́lẹ̀ ti ọ̀gbọ̀ dáradára tí iṣẹ́ aláṣọ híhun. 28Àti fìlà ọ̀gbọ̀ dáradára, ìgbàrí ọ̀gbọ̀ àti aṣọ abẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. 29Ọ̀já náà jẹ́ ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, aṣọ aláró, elése àlùkò àti òdòdó tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

3039.30-31: Ek 28.36,37.Ó ṣe àwo, adé mímọ́, láti ara kìkì wúrà, wọ́n sì kọ̀wé sí i, gẹ́gẹ́ bí i ìkọ̀wé lórí èdìdì:

mímọ́ sí Olúwa.

31Wọ́n sì so ọ̀já aláró mọ́ ọn láti ṣo ó mọ́ fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Mose bẹ àgọ́ náà wò

32Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ti àgọ́ àjọ parí. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 33Wọ́n sì mú tabanaku náà tọ Mose wá:

àgọ́ náà àti gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ìkọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, òpó rẹ̀ àti àwọn ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;

34ìbòrí awọ àgbò tí a kùn ní pupa, ìbòrí awọ àti ìji aṣọ títa;

35àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti ìbòrí àánú;

3639.36: Ek 25.30; 40.23; Le 24.5-9.tábìlì pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn;

37ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà pẹ̀lú ipele fìtílà rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti òróró fún títanná rẹ̀;

38pẹpẹ wúrà àti òróró ìtasórí, tùràrí dídùn, àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà.

39Pẹpẹ idẹ pẹ̀lú idẹ ọlọ, àwọn òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀;

agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀;

40aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti àgbàlá, àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá;

ọ̀já àmùrè àti èèkàn àgọ́ fún àgbàlá náà;

gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ fún àgọ́, àgọ́ àjọ náà;

41aṣọ híhun tí wọ́n ń wọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ àlùfáà.

42Àwọn ọmọ Israẹli ti ṣe gbogbo iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 43Mose bẹ iṣẹ́ náà wò, ó sì rí i wí pé wọ́n ti ṣe é gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ. Nítorí náà Mose sì bùkún fún wọn.