出埃及记 34 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

出埃及记 34:1-35

新的约版

1耶和华对摩西说:“你要凿出两块石版,跟你之前摔碎的两块一样,我要把前两块石版上的字刻在上面。 2你要预备好,明天清早你要上西奈山顶来见我。 3谁也不可与你同来,整座山上都不可有人,就是牛羊也不得在山前吃草。” 4于是,摩西凿出两块石版,跟先前的两块一样。他清早起来,照着耶和华的吩咐把石版带到西奈山上。 5耶和华在云中降临和摩西一同站在那里,宣告祂的名——耶和华。 6耶和华在摩西面前经过,并且宣告说:“我是耶和华,我是耶和华,是有怜悯和恩典的上帝,不轻易发怒,充满慈爱,无比信实, 7向千万人彰显慈爱,赦免罪恶和过犯,但决不免除罪责,必向子孙追讨父辈的罪债,直到三四代。” 8摩西急忙俯伏在地上敬拜, 9说:“主啊,如果我在你面前蒙了恩,求你与我们同行。虽然百姓顽固不化,求你赦免我们的过犯和罪恶,接纳我们做你的子民。”

10耶和华说:“我要与你立约,我要在你的同胞面前行奇事,是天下万国从未有过的奇事,你周围的外族人必看见我为你做的伟大而可畏的事。 11你要遵行我今天的吩咐。我必从你面前驱逐亚摩利人、迦南人、人、比利洗人、希未人和耶布斯人。 12你要谨慎,到了目的地后,不可与当地的居民立约,免得因此而陷入网罗。 13相反,要拆掉他们的祭坛,打碎他们的神柱,砍掉他们的亚舍拉神像。 14不可拜别的神明,因为耶和华是痛恨不贞的上帝,祂名为‘痛恨不贞’。

15“不可与当地的居民立约,免得他们与自己的神明苟合时邀请你,你就吃他们的祭物, 16给儿子娶他们的女儿为妻,以致她们与自己的神明苟合时诱使你的儿子犯同样的罪。

17“不可为自己铸造神像。

18“要守除酵节,照我的吩咐在亚笔月所定的时间吃七天的无酵饼,因为你是在亚笔月离开埃及的。

19“凡是头胎生的儿子都属于我,包括牲畜中一切头胎生的公牛和公羊。 20头胎生的驴要用羊赎回,如果不用羊赎回,就要打断它的脖子。凡头胎生的男婴,都要赎回他的性命。谁也不可空手来朝见我。

21“一周工作六天,第七天要休息,就是耕种和收割时也要休息。

22“在收割初熟麦子的时候,要守七七收割节,年底要守收藏节。 23所有的男子都要一年三次来朝见主耶和华——以色列的上帝。 24我要从你面前赶走外族人,扩张你的领土。你一年三次来朝见你的上帝耶和华时,必没有人贪恋你的土地。

25“不可把祭牲的血和有酵的饼一起献给我。逾越节的祭物也不可留到第二天早晨。

26“要把田中最好的初熟之物送到你们的上帝耶和华的殿中。

“不可用母山羊的奶煮它的小羊羔。”

27耶和华又对摩西说:“你要把我说的这些话记录下来,因为我要按这些话跟你和以色列人立约。” 28摩西在耶和华那里待了四十昼夜,没吃也没喝。耶和华把约的内容,就是十条诫命,写在石版上。

29摩西手里拿着两块约版下西奈山,他不知道自己因为曾与耶和华说话而脸上发光。 30亚伦和所有的以色列百姓看见摩西脸上发光,都不敢走近他。 31摩西召他们过来,亚伦和会众的首领便上前来。摩西与他们说话。 32之后,所有的以色列人都来到他面前,他就把耶和华在西奈山上的吩咐都告诉他们。 33说完之后,他就用帕子遮住自己的脸。 34每当进到会幕跟耶和华说话时,他就揭开帕子,出来后便把耶和华的吩咐告诉以色列百姓。 35百姓会看到他脸上发光,于是他再用帕子遮住脸,直到下次与耶和华说话的时候才揭开。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 34:1-35

Òkúta wàláà tuntun

1Olúwa sọ fún Mose pé, “E gé òkúta wàláà méjì jáde bí i ti àkọ́kọ́, èmi yóò sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé tó wà lára tí àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fọ́ sára wọn. 2Múra ní òwúrọ̀, kí o sì wá sórí òkè Sinai. Kí o fi ara rẹ hàn mí lórí òkè náà. 3Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá pẹ̀lú rẹ tàbí kí a rí wọn lórí òkè náà; bẹ́ẹ̀ ni agbo àgùntàn tàbí ọwọ́ ẹran kó má ṣe jẹ níwájú òkè náà.”

4Bẹ́ẹ̀ Mose sì gbẹ́ òkúta wàláà méjì bí ti àkọ́kọ́, ó sì gun orí òkè Sinai lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un; Ó sì gbé òkúta wàláà méjèèjì náà sí ọwọ́ rẹ̀. 5Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọsánmọ̀, ó sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pòkìkí orúkọ Olúwa. 634.6: Nu 14.18; Ne 9.17; Sm 86.15; 103.8; 145.8; Jn 4.2.Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “Olúwa, Olúwa, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́, 7Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1,000), ó sì ń dáríjì àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń ṣọ̀tẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.”

8Mose foríbalẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ó sì sìn. 9Ó wí pé, “Olúwa, bí èmi bá rí ojúrere rẹ, nígbà náà jẹ́ kí Olúwa lọ pẹ̀lú wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ènìyàn ọlọ́rùn líle ni wọn, dárí búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ.”

10Nígbà náà ni Olúwa wí pé: “Èmi dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú yín. Níwájú gbogbo ènìyàn rẹ èmi yóò ṣe ìyanu, tí a kò tí ì ṣe ní orílẹ̀-èdè ní gbogbo ayé rí. Àwọn ènìyàn tí ìwọ ń gbé láàrín wọn yóò rí i bí iṣẹ́ tí èmi Olúwa yóò ṣe fún ọ ti ní ẹ̀rù tó 11Ṣe ohun tí èmi pàṣẹ fún ọ lónìí. Èmi lé àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde níwájú rẹ. 12Máa ṣọ́ra kí o má ba à bá àwọn ti ó n gbé ilẹ̀ náà tí ìwọ ń lọ dá májẹ̀mú, nítorí wọn yóò jẹ́ ìdẹwò láàrín rẹ. 13Wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, fọ́ òkúta mímọ́ wọn, kí o sì gé òpó Aṣerah wọn. (Ère òrìṣà wọn). 1434.14: Ek 20.5; 34.7; De 4.24; 5.9.Ẹ má ṣe sin ọlọ́run mìíràn, nítorí Olúwa, orúkọ ẹni ti ń jẹ́ Òjòwú, Ọlọ́run owú ni.

15“Máa ṣọ́ra kí ẹ má ṣe bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú; nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àgbèrè tọ òrìṣà wọn, tí wọ́n sì rú ẹbọ sí wọn, wọn yóò pè yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ ẹbọ wọn. 16Nígbà tí ìwọ bá yàn nínú àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ ní ìyàwó, àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí yóò ṣe àgbèrè tọ òrìṣà wọn, wọn yóò sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín náà ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.

1734.17: Ek 20.4.“Ìwọ kò gbọdọ̀ dá ère òrìṣàkórìṣà fún ara rẹ.

1834.18: Ek 12.15-20.“Àjọ àkàrà àìwú ni kí ìwọ máa pamọ́. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò jẹ àkàrà aláìwú, gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa á láṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní ìgbà tí a yàn nínú oṣù Abibu, nítorí ní oṣù náà ni ẹ jáde láti Ejibiti wá.

1934.19-20: Ek 13.2,11-16.“Gbogbo àkọ́bí inú kọ̀ọ̀kan tèmi ní i ṣe, pẹ̀lú àkọ́bí gbogbo ohun ọ̀sìn rẹ, bóyá ti màlúù tàbí ti àgùntàn. 20Àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni kí ìwọ kí ó fi ọ̀dọ́-àgùntàn rà padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, dá ọrùn rẹ̀. Ra gbogbo àkọ́bí ọkùnrin rẹ padà.

“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá síwájú mi ní ọwọ́ òfo.

2134.21: Ek 20.8-10; 23.12; 31.12-17; 35.2; De 5.12-15.“Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje ìwọ yóò sinmi; kódà ní àkókò ìfúnrúgbìn àti ní àkókò ìkórè ìwọ gbọdọ̀ sinmi.

2234.22-24: Ek 23.14-17; Le 23.1-44; De 16.1-17.“Ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àkọ́so èso alikama àti àjọ ìkórè ní òpin ọdún. 23Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún, gbogbo àwọn ọkùnrin ni kí ó farahàn níwájú Olúwa Olódùmarè, Ọlọ́run Israẹli. 24Èmi yóò lé orílẹ̀-èdè jáde níwájú rẹ, èmi yóò sì mú kí ìpín rẹ fẹ̀, ẹnikẹ́ni kì yóò gba ilẹ̀ rẹ nígbà tí ìwọ bá gòkè lọ ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún kọ̀ọ̀kan láti farahàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

2534.25: Ek 23.18; Le 2.11; Ek 12.10.“Má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sí mi pẹ̀lú ohunkóhun tí ó bá ní ìwúkàrà, kí o má sì ṣe jẹ́ kí ẹbọ ìrékọjá kù títí di òwúrọ̀.

2634.26: Ek 23.19; De 14.21; 26.2-11.“Mú àkọ́ká èso ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ.

“Ìwọ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ewúrẹ́ nínú omi ọmú ìyá rẹ̀.”

27Olúwa sì wí fún Mose pé, “Kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, nítorí nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni èmi bá ìwọ àti Israẹli dá májẹ̀mú.” 28Mose wà níbẹ̀ pẹ̀lú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru (40) láìjẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà òfin mẹ́wàá sára wàláà.

Dídán ojú Mose

2934.29-35: 2Kọ 3.7-16.Nígbà tí Mose sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Sinai pẹ̀lú wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀, òun kò mọ̀ pé ojú òun ń dán nítorí ó bá Olúwa sọ̀rọ̀. 30Nígbà tí Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí Mose, ojú rẹ̀ ń dán, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti súnmọ́ ọn. 31Ṣùgbọ́n Mose pè wọn; Aaroni àti gbogbo àwọn olórí àjọ padà wá bá a, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀. 32Lẹ́yìn èyí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli súnmọ́ ọn, ó sì fún wọn ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún un lórí òkè Sinai.

33Nígbà tí Mose parí ọ̀rọ̀ sísọ fún wọn. Ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀. 34Ṣùgbọ́n nígbàkígbà tí Mose bá wà níwájú Olúwa láti bá a sọ̀rọ̀, á ṣí ìbòjú náà títí yóò fi jáde. Nígbà tí ó bá sì jáde, á sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli ohun tí a ti pàṣẹ fún un, 35Àwọn ọmọ Israẹli sì rí i pé ojú rẹ̀ ń dán. Mose á sì tún fi ìbòjú bo ojú rẹ̀ títí á fi lọ bá Olúwa sọ̀rọ̀.