出埃及记 27 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

出埃及记 27:1-21

造燔祭坛的条例

1“要用皂荚木造一个四方形的祭坛,长宽各二点三米,高一点三米。 2要在坛的四角造四个角状物,与坛连成一体,坛外面要包上铜。 3用铜造盛坛灰的盆和其他祭坛用具,即铲、碗、肉叉、火鼎。 4要造一个铜网,在铜网的四角装置四个铜环。 5铜网在祭坛围边的下方,向下伸展到祭坛的腰部。 6要用皂荚木为祭坛造两根横杠,外面包上铜。 7要将两根横杠穿在祭坛两旁的铜环里,以便抬祭坛。 8整座坛都用木板制成,坛是中空的。一切都要照我在山上给你的指示去做。

圣幕院子的规划

9“要为圣幕围出一个院子。院子的南面要用细麻线做帷幔,长四十六米, 10帷幔有二十根柱子,二十个带凹槽的铜底座,柱子上的钩子和横杆都是银的。 11北面的帷幔也是长四十六米,柱子、铜底座、钩子、横杆的样式都与南面的一样。 12院子西面的帷幔宽二十三米,有十根柱子和十个带凹槽的底座。 13院子东面的帷幔也是宽二十三米。 14-15入口两边的帷幔都是宽六点九米,各有三根柱子和三个带凹槽的底座。 16院子的入口要有门帘,长九米,用细麻线和蓝色、紫色、朱红色的线织成,上面有精致的刺绣,还有四根柱子和四个带凹槽的底座。 17所有绕着院子的柱子都要用银制的横杆连接,所有的钩子都要用银制作,带凹槽的底座要用铜制作。 18整个院子长四十四米,宽二十二米,高二点三米,所有的帷幔都要用细麻线精工制作,带凹槽的底座要用铜制作。 19圣幕里其他一切器具以及圣幕、院子所用的橛子都要用铜制作。

20“你要吩咐以色列百姓,把榨出的纯橄榄油拿来做会幕内的灯油,使灯台上的灯经常亮着。 21亚伦和他的子孙要负责照看圣所内约柜前的幔子外的灯,使灯在耶和华面前日夜亮着。这是以色列百姓世世代代当守的条例。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 27:1-21

Pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun

127.1-8: Ek 38.1-7.“Ìwọ yóò sì kọ pẹpẹ igi kasia kan, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gígùn; Kí ìhà rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jẹ́ ìwọ̀n kan, ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní fífẹ̀. 2Ìwọ yóò ṣì ṣe ìwo orí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, kí àwọn ìwo náà àti pẹpẹ náà lè ṣe ọ̀kan, ìwọ yóò sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ. 3Ìwọ yóò sì ṣe abọ́ ìtẹ́dìí rẹ láti máa gba eérú rẹ̀, àti ọkọ̀ rẹ̀, àwokòtò rẹ̀, àti fọ́ọ̀kì ẹran rẹ̀, àti àwo iná rẹ̀, gbogbo ohun èlò rẹ̀ ni ìwọ yóò fi idẹ ṣe. 4Ìwọ yóò sí ṣe ni wẹ́wẹ́, iṣẹ́ àwọ̀n idẹ, kí o sì ṣe òrùka idẹ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin iṣẹ́ àwọ̀n náà. 5Gbé e sí abẹ́ igun pẹpẹ náà, kí ó lè dé ìdajì pẹpẹ náà. 6Ìwọ yóò sí ṣe òpó igi kasia fún pẹpẹ náà, kí o sì bò ó pẹ̀lú idẹ. 7A ó sì bọ àwọn òpó náà ní òrùka, wọn yóò sì wà ní ìhà méjèèjì pẹpẹ nígbà tí a bá rù ú. 8Ìwọ yóò sì ṣe pákó náà ni oníhò nínú. Ìwọ yóò sí ṣe wọ́n bí èyí tí a fihàn ọ́ ní orí òkè.

Àgbàlá

927.9-19: Ek 38.9-20.“Ìwọ yóò sì ṣe àgbàlá fún àgọ́ náà. Ní ìhà gúúsù gbọdọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta) ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́, 10pẹ̀lú ogún (20) òpó àti ogún (20) ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà, kí ó sì di àwọn òpó mú. 11Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun (20) òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú.

12“Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá. 13Ní ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, 14Aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga ní yóò wà ní ìhà ẹnu-ọ̀nà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta, 15Àti aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga yóò wá ní ìhà kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta.

16“Àti fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà, pèsè aṣọ títa, mítà mẹ́sàn-án ní gíga, ti aláró, elése àlùkò, ti òdòdó, àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe, pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin. 17Gbogbo òpó ti ó wà ní àyíká àgbàlá náà ni a ó fi fàdákà ṣo pọ̀ àti ìkọ́, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ. 18Àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ni gíga àti mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, pẹ̀lú aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn mítà méjì ní gíga, àti pẹ̀lú ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ. 19Gbogbo irú iṣẹ́ tí ó wà kí ó ṣe, papọ̀ pẹ̀lú gbogbo èèkàn àgọ́ náà àti fún tí àgbàlá náà, kí ó jẹ́ idẹ.

Òróró fún ọ̀pá fìtílà

2027.20-21: Le 24.1-4.“Ìwọ yóò sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn kí ó mú òróró olifi dáradára tí a gún fún ọ wá, fún ìmọ́lẹ̀, kí fìtílà lè máa tàn síbẹ̀. 21Ní àgọ́ àjọ, lẹ́yìn òde aṣọ ìkélé tí ó wá níwájú ẹ̀rí náà, Aaroni àti òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, ni yóò tọ́jú rẹ̀ láti alẹ́, títí di òwúrọ̀ níwájú Olúwa: yóò sì di ìlànà láéláé ni ìrandíran wọn lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli.