出埃及记 14 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

出埃及记 14:1-31

过红海

1耶和华对摩西说: 2“你吩咐以色列人改变方向,在比·哈希录附近的海边扎营,在红海和密夺之间,对面是巴力·洗分3法老必定以为你们走迷了路,被困在旷野。 4我要使法老的心刚硬,使他派兵追赶你们。我要在法老和埃及军兵身上得到荣耀,好叫埃及人知道我是耶和华。”于是,以色列人依言而行。

5有人向埃及王报信,说以色列百姓逃走了。法老和他的臣仆便改变主意,说:“我们怎么可以让以色列人就这样离开我们,不再服侍我们呢?” 6法老便吩咐人预备战车,他亲自领军, 7率领埃及所有的战车,包括六百辆最精锐的战车,每辆车上都有战车长。 8耶和华使法老的心刚硬,法老就追赶毫无惧色地离开埃及以色列人。 9埃及大军的战车骑兵倾巢而出,沿着海边追赶,在巴力·洗分对面的比·哈希录附近追上了正在那里安营的以色列人。

10以色列人看见法老大军追了上来,非常害怕,便呼求耶和华。 11他们对摩西说:“难道埃及没有坟地,要你带我们出来死在旷野吗?为什么要带我们离开埃及呢? 12我们对你说过,别管我们,就让我们服侍埃及人吧。服侍埃及人总比死在旷野好啊!” 13摩西对百姓说:“你们不用害怕,站稳了,看耶和华用什么方法解救你们。你们再也看不到你们今天看到的埃及人了。 14耶和华必为你们争战,你们要保持镇静。” 15耶和华对摩西说:“为什么向我呼求呢?吩咐以色列人往前走吧。 16你举手向海伸出手杖,把海水分开,以色列人可以从中间的干地走过去。 17我要使埃及人的心刚硬,他们会紧追不舍,跟着你们走进海底。我要在法老及其大军、战车和骑兵身上得到荣耀。 18当我在法老及其战车和骑兵身上得到荣耀时,埃及人就知道我是耶和华。”

19这时,在以色列人前面领路的上帝的天使,转到百姓后面,云柱也随着移到后面立住。 20云柱停在埃及军队和以色列人的中间,埃及军队这边一片黑暗,以色列人那边却有光,双方整夜都无法接近对方。

21摩西向海伸出手,耶和华便整夜用强劲的东风吹退海水,将海底变成干地。海水分开后, 22以色列人踏着干地走入海中,海水如两道墙立在他们左右。 23法老的军兵车马紧追不舍,都跟着下到海中。 24到了破晓时分,耶和华从云柱火柱中俯视埃及军队,扰乱他们的队伍。 25祂使他们战车的轮子脱落,难以前行。于是,埃及人说:“我们逃命吧,因为耶和华在帮助以色列人对付我们!”

26耶和华对摩西说:“你向海伸出手,使海水回流,淹没埃及军队。” 27天刚亮的时候,摩西向海伸出手,海水便复原。埃及人纷纷向岸上逃命,耶和华却使大水把他们卷回海中。 28海水回流,法老的战车和人马都淹没在大海之中,全军覆没。 29全体以色列人却在干地上走过红海,海水在他们两边筑成水墙。 30那天,耶和华就这样从埃及人手中拯救了以色列人。后来,以色列人还看见埃及人的尸体横在海边。 31以色列百姓亲眼看见耶和华怎样以大能对付埃及人,他们就敬畏耶和华,又信服祂和祂的仆人摩西

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 14:1-31

1Olúwa sọ fún Mose pé 2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn padà sẹ́yìn, kí wọ́n sì pàgọ́ sí tòsí Pi-Hahirotu láàrín Migdoli òun Òkun, kí wọn kí ó pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun, ní òdìkejì Baali-Ṣefoni. 3Farao yóò ronú pé àwọn ọmọ Israẹli ń ráre káàkiri ní ìdààmú ni àti wí pé aginjù náà ti sé wọn mọ́. 4Èmi yóò sé ọkàn Farao le ti yóò fi lépa wọn. Ṣùgbọ́n èmi yóò gba ògo fún ará mi láti ìpàṣẹ Farao àti ogun rẹ̀, àti pé àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.” Àwọn Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀.

5Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba Ejibiti pé àwọn ènìyàn náà ti sálọ, ọkàn Farao àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yí padà sí àwọn ènìyàn, wọ́n sì wí pé, “Kí ni ohun tí àwa ṣe yìí? Àwa ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli kí ó lọ, a sì ti pàdánù ìsìnrú wọn.” 6Ó sì di kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀, ó sì kó àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, 7ó mú ẹgbẹ̀ta (600) ọmọ-ogun oníkẹ̀kẹ́ tí ó jáfáfá jùlọ àti gbogbo ọmọ-ogun oníkẹ̀kẹ́ mìíràn ní Ejibiti, olórí sì wà fún olúkúlùkù wọn. 814.8: Ap 13.17.Olúwa sé ọkàn Farao ọba Ejibiti le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Israẹli ti ń jáde lọ ní àìbẹ̀rù. 9Àwọn ará Ejibiti ń lépa wọn pẹ̀lú gbogbo ẹṣin kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, wọ́n sì lé wọn bá ni ibi tí wọ́n pa àgọ́ sí lẹ́bàá Òkun ní ìhà Pi-Hahirotu, ni òdìkejì Baali-Ṣefoni.

10Bí Farao ti súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú wọn sókè, wọn sì rí àwọn ará Ejibiti tó súnmọ́ wọn. Ẹ̀rù ńlá sì bá àwọn ará Israẹli, wọ́n kígbe sókè sí Olúwa. 11Wọ́n sọ fún Mose pé, “Ṣe nítorí pé kò sí ibojì ni Ejibiti ní ìwọ ṣe mú wa wá láti kú sínú aginjù? Kí ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa ti ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti wá? 1214.12: Ek 16.3; 17.3.Ǹjẹ́ èyí kọ́ ni àwa sọ fún ọ ni Ejibiti, ‘Fi wá sílẹ̀, jẹ́ kí àwa máa sin ará Ejibiti’? Nítorí kò bá sàn fún wa kí a sin àwọn ará Ejibiti ju kí a kú sínú aginjù yìí lọ!”

13Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì rí ìdáǹdè tí Olúwa yóò fi fún un yín lónìí; Àwọn ará Ejibiti ti ẹ̀yin rí lónìí ni ẹ kò ni tún padà rí wọn mọ́. 14Olúwa yóò jà fún un yín; kí ẹ̀yin kí ó sá à mu sùúrù.”

15Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń ké pè mí? Sọ fún àwọn ará Israẹli kí wọn máa tẹ̀síwájú. 16Ṣùgbọ́n, gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè, kí o sì na ọwọ́ rẹ sí orí omi Òkun, kí ó lè pín ní yà kí àwọn ọmọ Israẹli lè la Òkun kọjá ni orí ìyàngbẹ ilẹ̀. 17Nígbà náà ni èmi yóò sé ọkàn àwọn ará Ejibiti le, wọn yóò sì máa lépa wọn; Èmi yóò gba ògo fún ara mi lórí Farao; lórí gbogbo ogun rẹ̀, lórí kẹ̀kẹ́ ogun àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. 18Àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa nígbà ti èmi bá gba ògo fún ara mi lórí Farao: lórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.”

19Nígbà náà ni angẹli Ọlọ́run tó ti ń ṣáájú ogun Israẹli lọ, padà o sì rìn ni ẹ̀yìn wọn; Òpó ìkùùkuu tí ń rìn ni iwájú wọn sì padà sí í rìn ni ẹ̀yìn wọn. 20Ó sì wà láàrín àwọn ọmọ-ogun Ejibiti àti Israẹli. Ìkùùkuu sì ṣú òkùnkùn sí àwọn ará Ejibiti ni òru náà. Ṣùgbọ́n ó tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn Israẹli ni òru náà; Ọ̀kan kò sì súnmọ́ èkejì ni gbogbo òru náà.

21Nígbà náà ni Mose na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, ni gbogbo òru náà ni Olúwa fi lé Òkun sẹ́yìn pẹ̀lú ìjì líle láti ìlà-oòrùn wá, ó sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀. Omi Òkun sì pínyà, 2214.22: 1Kọ 10.1,2; Hb 11.29.àwọn ọmọ Israẹli sì la ìyàngbẹ ilẹ̀ kọjá nínú Òkun pẹ̀lú ògiri omi ní ọ̀tún àti òsì.

23Àwọn ará Ejibiti sì ń lépa wọn, gbogbo ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ́ tọ̀ wọ́n lọ sínú Òkun. 24Ní ìṣọ́ òwúrọ̀ Olúwa bojú wo ogun àwọn ará Ejibiti láàrín ọ̀wọ̀n iná àti ìkùùkuu, ó sì kó ìpayà bá àwọn ọmọ-ogun Ejibiti. 25Ó sì yọ àgbá ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn kí ó bá à le ṣòro fún wọn láti fi kẹ̀kẹ́ ogun náà rìn. Àwọn ará Ejibiti wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá àsálà kúrò ní iwájú àwọn ará Israẹli nítorí Olúwa ń bá wa jà nítorí wọn.”

26Olúwa sì wí fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sí orí Òkun kí omi Òkun lè ya padà sórí àwọn ará Ejibiti, kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti sórí ẹlẹ́ṣin wọn.” 27Mose sì na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, Òkun sì padà bọ́ sí ipò rẹ̀ nígbà ti ilẹ̀ mọ́. Àwọn ará Ejibiti ń sá fún omi Òkun, Olúwa sì gbá wọn sínú Òkun. 28Omi Òkun sì ya padà, ó sì bo kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin: àní, gbogbo ọmọ-ogun Farao tiwọn wọ inú Òkun tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yè.

29Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli la Òkun kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ pẹ̀lú ògiri omi ni ọ̀tún àti òsì wọn. 30Ni ọjọ́ yìí ni Olúwa gba Israẹli là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti; Israẹli sì rí òkú àwọn ará Ejibiti ni etí Òkun. 31Nígbà ti àwọn ọmọ Israẹli rí iṣẹ́ ìyanu ńlá ti Olúwa ṣe fún wọn lára àwọn ará Ejibiti, àwọn ènìyàn bẹ̀rù Olúwa, wọ́n sì gba Olúwa àti Mose ìránṣẹ́ rẹ gbọ́.