但以理书 12 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

但以理书 12:1-13

末日

1“那时,守护你本国人民的天使长米迦勒必出现。将有一段灾难时期,是开国以来从未有过的。那时,你同胞中凡名字记在册子上的,必得拯救。 2许多长眠地下的人必醒过来,有些得到永生,有些蒙受羞辱,永远被憎恶。 3智者必发出光辉,如耀眼的穹苍;引导多人归向公义的人必如闪烁的星辰,直到永永远远。 4但以理啊,这些话要保密,要把这书封起来,直到末了。许多人必四处探究,因而知识必增多。”

5但以理观看,见另有两个人分别站在河的两岸。 6其中一人问身穿细麻衣、站在河水之上的人:“这奇异的事何时才应验呢?” 7我听见身穿细麻衣、站在河水之上的人向天举起双手,凭永活者起誓说:“再过三年半,等摧毁圣民的权势结束时,这一切事都要成就。” 8我听见这话,却不明白,就问他:“我主啊,这些事的结局会怎样呢?” 9他说:“但以理啊,你走吧,因为这些事要保密,要被封起来,一直到末了。 10许多人必被净化、洗涤、炼净。但恶人必依旧作恶,他们无人明白,只有智者能明白。 11从废除日常献的祭、设立带来毁灭的可憎之物算起,必经过一千二百九十天。 12能等候一千三百三十五天的人有福了! 13你要坚持到底。你必得到安息,到了末后的日子,你必起来承受你的产业。”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Daniẹli 12:1-13

Ìgbà ìkẹyìn

112.1: Mt 24.21; Mk 13.19; If 12.7; 16.18.“Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà. 212.2: Mt 25.46.Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí: àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun. 312.3: Mt 13.43.Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé. 412.4: If 22.10.Ṣùgbọ́n ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.”

5Nígbà náà, ni èmi Daniẹli, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá òdìkejì ọ̀hún etí i bèbè. 6Ọ̀kan lára wọn sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò pé, “Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn nǹkan ìyanu wọ̀nyí tó wá sí ìmúṣẹ?”

712.7: If 4.9; 10.5; 12.14.Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátápátá, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.”

8Èmi gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi. Nígbà náà ni mo béèrè pé, “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ àbábọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?”

9Ó sì dáhùn pé, “Máa lọ ní ọ̀nà rẹ, Daniẹli nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dì í di ìgbà ìkẹyìn. 10Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láìlábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búburú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n.

1112.11: Da 9.27; 11.31; Mt 24.15; Mk 13.14.“Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290). 12Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró, ti ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì ọjọ́ (1,335).

13“Ṣùgbọ́n ìwọ, máa lọ ní ọ̀nà rẹ, títí di òpin. Ìwọ yóò sinmi, àti ní òpin ọjọ́ ìwọ yóò dìde láti gba èrè rẹ.”