以赛亚书 61 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

以赛亚书 61:1-11

大喜的讯息

1主耶和华的灵在我身上,因为耶和华膏立了我,

让我传福音给贫穷的人,

差遣我医治伤心的人,

宣告被掳的人得释放、

被囚的人得自由;

2宣告我们上帝耶和华的恩年和祂报仇的日子,

安慰一切悲哀的人;

3以华冠取代锡安哀伤者头上的灰尘,

以喜乐的膏油取代他们的哀伤,

以颂赞的外袍取代他们的沮丧。

他们将被称为耶和华所栽种的公义橡树,

以彰显祂的荣耀。

4他们必重修古老的荒场,

在久已毁坏之地重建荒废的城邑。

5异乡人要为你们牧放羊群,

外族人要为你们耕种田地、

照料葡萄园。

6你们要被称为耶和华的祭司,

我们上帝的臣仆。

你们必享用各国的财宝,

夸耀自己拥有他们的财富。

7你们曾经蒙受耻辱,

如今将得到双倍的福分;

你们曾经遭受屈辱,

如今将因得到产业而快乐。

你们将在自己的土地上得到双倍的福分,

享受永远的快乐。

8“因为我耶和华喜爱公正,

憎恶抢劫之罪。

我必凭信实赏赐我的子民,

与他们立永远的约。

9他们的后代必享誉列国,

子孙必名闻万邦,

看见的人都承认他们是蒙上帝赐福之民。”

10我因耶和华而无比喜乐,

因我的上帝而心里快乐,

因为祂给我穿上救恩的衣服、

披上公义的袍子,

使我像戴上华冠的新郎,

又像戴上饰物的新娘。

11大地怎样使嫩苗长出,

园子怎样使种子发芽,

主耶和华必照样使公义与颂赞在万民中滋长。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 61:1-11

Ọdún ojúrere Olúwa

161.1-2: Mt 11.5; Lk 4.18-19; 7.22.Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi

nítorí Olúwa ti fi ààmì òróró yàn mí

láti wàásù ìhìnrere fún àwọn tálákà.

Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́

láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn

àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,

2Láti kéde ọdún ojúrere Olúwa

àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,

láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,

3àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni

láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,

òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,

àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.

A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,

irúgbìn Olúwa

láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

4Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́

wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò;

wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà

tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.

5Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ;

àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.

6A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa,

a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.

Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè

àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.

7Dípò àbùkù wọn

àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì,

àti dípò àbùkù wọn

wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn;

bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn,

ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn.

8“Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo;

mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀

Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọn

èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn.

9A ó mọ ìrandíran wọn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè

àti àwọn ìran wọn láàrín àwọn ènìyàn

Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé

wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún.”

10Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa;

ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.

Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà

ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo;

gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà,

àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.

11Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú irúgbìn jáde

àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà,

Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn

kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.