以赛亚书 1 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

以赛亚书 1:1-31

1犹大乌西雅约坦亚哈斯希西迦执政期间,亚摩斯的儿子以赛亚看到了以下有关犹大耶路撒冷的异象。

上帝责备叛逆的子民

2诸天啊,请听!

大地啊,要侧耳听!

耶和华说:

“我把孩子抚育成人,

他们竟然背叛我。

3牛认识主人,

驴也认得主人的槽,

以色列却不认识,

我的子民却不明白。”

4唉!你们这罪恶的民族,

恶贯满盈的百姓,

作恶的子孙,

败坏的儿女!

你们背弃耶和华,

藐视以色列的圣者,

与祂疏远。

5你们为什么一再叛逆?

你们还要受责打吗?

你们已经头破血流,

身心疲惫。

6你们已经体无完肤,

从头到脚伤痕累累,

伤口没有清洗,

没有包扎,也没有敷药。

7你们的土地荒凉,

城邑化为灰烬。

你们亲眼目睹自己的田园被外族人侵吞、毁坏、变成不毛之地。

8仅存的锡安1:8 锡安”又称“耶路撒冷”。城也像葡萄园里的草棚、

瓜田中的茅舍、

被困无援的孤城。

9若不是万军之耶和华让我们一些人存活,

我们早就像所多玛蛾摩拉一样灭亡了。

10你们这些“所多玛”的首领啊,

要聆听耶和华的话!

你们这些“蛾摩拉”的百姓啊,

要侧耳听我们上帝的训诲!

11耶和华说:

“你们献上许多祭物,对我有什么用呢?

我厌烦公绵羊的燔祭和肥畜的脂肪,

我不喜欢公牛、羊羔和公山羊的血。

12“你们来敬拜我的时候,

谁要求你们带着这些来践踏我的院宇呢?

13不要再带毫无意义的祭物了。

我憎恶你们烧的香,

厌恶你们的朔日1:13 朔日”即每月初一。、安息日和大会。

你们又作恶又举行庄严的聚会,

令我无法容忍。

14我憎恶你们的朔日及其他节期,

它们成了我的重担,

令我厌倦。

15你们举手祷告,我必掩面不理。

即使你们祷告再多,

我也不会听,

因为你们双手沾满鲜血。

16你们要洗净自己,

停止作恶,

不要让我再看见你们的恶行。

17你们要学习行善,

追求正义,

帮助受欺压的,

替孤儿辩护,

为寡妇申冤。”

18耶和华说:

“来吧,我们彼此理论!

你们的罪虽如猩红,

也必洁白如雪;

你们的罪虽如绯红,

也必白如羊毛。

19如果你们愿意听从,

就必享用这地方的美好出产。

20如果你们执意叛逆,

就必丧身刀下。”

这是耶和华亲口说的。

21耶路撒冷啊,

你这忠贞的妻子竟变成了妓女!

你从前充满公平,

是公义之家,

现在却住着凶手。

22你曾经像银子,现在却像渣滓;

曾经像美酒,现在却像搀了水的酒。

23你的首领是叛逆之徒,

与盗贼为伍,

个个收受贿赂,

贪图好处,

不为孤儿辩护,

不替寡妇申冤。

24所以,主——万军之耶和华,

以色列的大能者说:

“我要向我的敌人报仇雪恨。

25我必攻击你,

用碱炼净你的渣滓,

除尽你的杂质。

26我必像从前一样赐你审判官和谋士。

之后,你必被称为公义之城、

忠信之邑。”

27耶和华必因祂的公正救赎锡安

必因祂的公义拯救城中悔改的人。

28但叛逆之辈和犯罪之徒必遭毁灭,

背弃耶和华的人必灭亡。

29你们必因在橡树下,

在你们选择的园子里祭拜偶像而蒙羞。

30你们必像枯萎的橡树,

又如无水的园子。

31你们中间有权势的人必因他们的恶行而遭毁灭,

好像火花点燃枯木,无人能救。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 1:1-31

1Ìran sí Juda àti Jerusalẹmu èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí ní àsìkò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah àwọn ọba Juda.

Ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè kan

2Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé!

Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀:

“Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà,

Ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.

3Màlúù mọ olówó rẹ̀,

kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀,

ṣùgbọ́n Israẹli kò mọ̀,

òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”

4Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,

àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù,

Ìran àwọn aṣebi,

àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́!

Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀

wọn ti gan Ẹni Mímọ́ Israẹli,

wọn sì ti kẹ̀yìn sí i.

5Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́?

Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe?

Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́,

gbogbo ọkàn yín sì ti pòruurù.

6Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín dé àtàrí yín

kò sí àlàáfíà rárá,

àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa

àti ojú egbò,

tí a kò nù kúrò tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.

7Orílẹ̀-èdè yín dahoro,

a dáná sun àwọn ìlú yín,

oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ run

lójú ara yín náà,

ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tí

àwọn àjèjì borí rẹ̀.

8Ọmọbìnrin Sioni ni a fi sílẹ̀

gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà,

gẹ́gẹ́ bí abà nínú oko ẹ̀gúnsí,

àti bí ìlú tí a dó tì.

9Àyàfi bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun

bá ṣẹ́ díẹ̀ kù fún wà,

a ò bá ti rí bí Sodomu,

a ò bá sì ti dàbí Gomorra.

10Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,

ẹ̀yin aláṣẹ Sodomu,

tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa,

ẹ̀yin ènìyàn Gomorra!

11“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín

kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni Olúwa wí.

“Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun

ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa,

Èmi kò ní inú dídùn

nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn

àti ti òbúkọ.

12Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi,

ta ni ó béèrè èyí lọ́wọ́ yín,

Gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?

13Ẹ má mú ọrẹ asán wá mọ́!

Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi,

oṣù tuntun àti ọjọ́ ìsinmi àti àwọn àpéjọ,

Èmi kò lè faradà á, ẹ̀ṣẹ̀ ni àpéjọ yín wọ̀nyí.

14Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àjọ̀dún tí a yàn,

ni ọkàn mi kórìíra.

Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn,

Ó sú mi láti fi ara dà wọ́n.

15Nígbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sókè ni àdúrà,

Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín,

kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà,

Èmi kò ni tẹ́tí sí i.

“Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.

16“Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́.

Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi!

Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró,

17kọ́ láti ṣe rere!

Wá ìdájọ́ òtítọ́,

tu àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú.

Ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,

gbà ẹjọ́ opó rò.

18“Ẹ wá ní ìsinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàṣàrò,”

ni Olúwa wí.

“Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn,

wọn ó sì funfun bí i yìnyín,

bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀,

wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n òwú.

19Tí ẹ̀yin bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́rọ̀,

ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà.

20Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀,

idà ni a ó fi pa yín run.”

Nítorí ẹnu Olúwa la ti sọ ọ́.

21Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè!

Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí,

òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí,

ṣùgbọ́n báyìí àwọn apànìyàn!

22Fàdákà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́,

ààyò wáìnì rẹ la ti bu omi là.

23Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín,

akẹgbẹ́ àwọn olè,

gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀

wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.

Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,

ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn.

24Nítorí náà ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

alágbára kan ṣoṣo tí Israẹli sọ wí pé:

“Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi

n ó sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi.

25Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ,

èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù,

n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.

26Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀ sí ipò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́,

àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.

Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.”

27A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Sioni padà,

àti àwọn tí ó ronúpìwàdà pẹ̀lú òdodo.

28Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó parun.

Àwọn tí ó bá sì kọ Olúwa sílẹ̀ ni yóò ṣègbé.

29“Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́

èyí tí ẹ ní inú dídùn sí,

a ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìí

tí ẹ ti yàn fúnrayín.

30Ẹ ó sì dàbí igi óákù tí ewé rẹ̀ ti rọ,

bí ọgbà tí kò ní omi.

31Alágbára ọkùnrin náà yóò sì dàbí ohun ìdáná,

iṣẹ́ rẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ́-iná,

àwọn méjèèjì ni yóò jóná papọ̀,

láìsí ẹni tí yóò lè pa iná yìí.”