以西结书 22 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

以西结书 22:1-31

耶路撒冷的罪恶

1耶和华对我说: 2“人子啊,你要审判耶路撒冷这杀人流血的城。你要审判她,使她知道自己一切可憎的行为。 3你要向她宣告主耶和华的话,说,‘唉,你这杀人流血、制造偶像玷污自己的城啊,你的末日到了。 4你既犯罪杀人、制造偶像玷污自己、自招审判,我要使你成为列国列邦侮辱和讥讽的对象。 5你这声名狼藉、混乱不堪的城将要受到远近各国的耻笑。

6“‘看啊,在你城中的以色列首领各逞权势,杀人流血。 7他们轻慢父母,压迫寄居者,欺负孤儿寡妇。 8他们藐视我的圣物,亵渎我的安息日。 9在你这城中,有人好诽谤、杀人流血,有人在山上吃祭物,有人淫乱, 10有人与继母通奸,羞辱父亲,有人奸污经期不洁的妇女, 11有人与邻居的妻子干出可憎之事,有人玷污自己的儿媳妇,有人奸污自己的同父姊妹。 12在你这城中,他们受贿杀人,放债取利,压榨邻居,早把我忘了。这是主耶和华说的。

13“‘我见你谋财害命,就击掌叹息。 14在我惩罚你的日子,你还有勇气和力量吗?我耶和华言出必行, 15我要把你驱散到列国,分散到列邦,我要除掉你的污秽。 16你必在列国面前受凌辱,你便知道我是耶和华。’”

17耶和华对我说: 18“人子啊,在我看来,以色列人已经变成了渣滓。他们是炉中的铜、锡、铁、铅,都是银渣滓。 19所以主耶和华说,‘你们既是渣滓,我要把你们聚集在耶路撒冷城。 20我要在烈怒中把你们聚集在城里熔化,就像人把银、铜、铁、铅、锡聚在高温的炉中熔化一样。 21我要聚集你们,把我的怒火倒在你们身上,熔化你们。 22你们要在城中熔化,就像银在炼炉中熔化。你们就知道我耶和华已将我的烈怒倾倒在你们身上。’”

23耶和华对我说: 24“人子啊,你要对以色列说,‘在我发怒的日子,将没有雨水滋润你这不洁之地。 25你的首领图谋恶事,好像咆哮着撕碎猎物的狮子,他们草菅人命,抢夺财宝,使多人变成寡妇。 26你的祭司强解我的律法,亵渎我的圣物。他们圣俗不分,也不教导人分辨洁净的和污秽的。他们藐视我的安息日,亵渎我。 27你的首领好像撕碎猎物的豺狼,杀人流血,谋取不义之财。 28你的先知对他们说虚假的异象和占卜,像用白灰刷墙一样掩盖他们的罪恶,说,耶和华这样说,其实耶和华没有说。 29你的居民强取豪夺,欺压贫困的,虐待寄居的,无法无天。 30我想在他们中间寻找一位重修城墙的人,站在我面前为这地方堵住缺口,免得我毁灭这里。可是,我一个也找不到。 31因此,我要向他们倾倒我的烈怒,用怒火灭尽他们,照他们的所作所为报应他们。这是主耶和华说的。’”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 22:1-31

Àwọn ẹsẹ̀ Jerusalẹmu

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

2“Ọmọ ènìyàn ǹjẹ́ ìwọ yóò ha ṣe ìdájọ́ rẹ̀? Ǹjẹ́ ìwọ ha ṣe ìdájọ́ ìlú atàjẹ̀sílẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀ dojúkọ wọn pẹ̀lú gbogbo ìwà ìríra wọn. 3Kí ó sì wí pé: ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwọ ìlú ńlá tí ó mú ìparun wá sórí ara rẹ nípa títàjẹ̀sílẹ̀ ní àárín rẹ, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nípa ṣíṣe àwọn ère, 4Ìwọ ti jẹ̀bi nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀, àti pé àwọn ère tí ó ṣe tí bà ọ́ jẹ́. Ìwọ tí mú ọjọ́ rẹ súnmọ́ tòsí, ìparí àwọn ọdún rẹ sì ti dé. Nítorí náà èmi yóò fi ọ ṣe ohun ẹ̀gàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè àti ohun ẹ̀sín lójú gbogbo ìlú. 5Àwọn tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó jìnnà sí ọ, yóò fi ọ ṣe ẹlẹ́yà, ìwọ ìlú ẹlẹ́gàn, tí ó kún fún làálàá.

6“ ‘Wo bí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin ọba Israẹli tí ó wà nínú yín ti ń lo agbára rẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀. 7Nínú rẹ wọn ti hùwà sí baba àti ìyá pẹ̀lú ìfojú tínrín; nínú rẹ wọn ti ni àwọn àlejò lára, wọn sì hùwàkiwà sí aláìní baba àti opó. 8Ìwọ tí kọ àwọn ohun mímọ́ mi sílẹ̀, ìwọ sì ti lo ọjọ́ ìsinmi mi ní ìlòkulò. 9Nínú rẹ ni àwọn ayannijẹ ènìyàn pinnu láti tàjẹ̀ sílẹ̀; nínú rẹ ní àwọn tí ó ń jẹun ní orí òkè ojúbọ òrìṣà, wọn sì hùwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. 10Nínú rẹ ní àwọn ti kò bu ọlá fún àwọn àkéte baba wọn; nínú rẹ ni àwọn tí o ń bá àwọn obìnrin lò nígbà tí wọ́n ń ṣe àkókò lọ́wọ́, ní àsìkò tí a ka wọn sì aláìmọ́. 11Nínú rẹ ọkùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìríra pẹ̀lú aya aládùúgbò rẹ̀, òmíràn bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ jẹ́, òmíràn sì bá arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀ èyí tí í ṣe ọbàkan rẹ̀. 1222.12: Ek 23.8; De 16.19; Ek 22.25; Le 25.36,37; De 23.19.Nínú rẹ àwọn ènìyàn gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀; ìwọ gba èlé lọ́pọ̀pọpọ̀ láti mú aláìṣòótọ́ jèrè láti ara aládùúgbò rẹ nípa ìrẹ́jẹ. Ìwọ sì ti gbàgbé èmi; ni Olúwa Olódùmarè wí.

13“ ‘Èmi yóò kúkú pàtẹ́wọ́ lórí èrè àìmọ̀ tí ìwọ ti jẹ, àti lórí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀ ní àárín yín. 14Ọkàn rẹ le gbà á, tàbí ọwọ́ rẹ lè le, ní ọjọ́ tí èmi yóò bá ọ ṣé? Èmi Olúwa ó ti sọ̀rọ̀, Èmi yóò sì ṣe é. 15Èmi yóò tú yin ká ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò fọ́n ọ ká sí àwọn ìlú; èmi yóò sì fi òpin sí àìmọ́ rẹ. 16Nígbà tí a ó bà ọ́ jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

17Nígbà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 18“Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ti di ìdàrọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, idẹ, irin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà. 19Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí tí ìwọ ti di ìdàrọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jerusalẹmu. 20Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti idẹ jọ sínú iná ìléru láti fi iná yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárín ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ. Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́. 21Èmi yóò kó yín jọ, èmi o sì fín iná ìbínú mi si yin lára, ẹ o si di yíyọ́ láàrín rẹ̀. 22Bí a ti ń yọ́ fàdákà nínú iná ìléru bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ìwọ yóò ṣe yọ́ nínú rẹ̀, ìwọ yóò sì mọ̀ wí pé èmi Olúwa ti tú ìbínú mi sórí rẹ.’ ”

23Lẹ́ẹ̀kan sí i ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé, 24“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ilẹ̀ náà, ‘Ìwọ ní ilẹ̀ tí kò gbá mọ́, ti kò sì rọ òjò tàbí ìrì ní àkókò ìbínú.’ 25Ìdìtẹ̀ sì wà láàrín àwọn ọmọ-aládé inú rẹ̀, tó dàbí bíbú kìnnìún tó ń fà ẹran ya, wọ́n ń ba àwọn ènìyàn jẹ́, wọ́n ń kó ìṣúra àti àwọn ohun iyebíye wọ́n sì ń sọ púpọ̀ di opó nínú rẹ̀. 26Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti rú òfin mi, wọn si ti sọ ohun mímọ́ mi di àìlọ́wọ̀: wọn kò fi ìyàtọ̀ sáàrín ohun mímọ́ àti àìlọ́wọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi ìyàtọ̀ hàn láàrín ohun àìmọ́, àti mímọ́, wọn sì ti fi ojú wọn pamọ́ kúrò ní ọjọ́ ìsinmi mi, mó sì dí ẹni àìlọ́wọ̀ láàrín wọn. 27Àwọn ọmọ-aládé àárín rẹ̀ dàbí ìkookò ti ń ṣọdẹ, láti tàjẹ̀ sílẹ̀, láti pa ọkàn run, láti jèrè àìṣòótọ́. 28Àti àwọn wòlíì rẹ́ ti ṣẹ̀tàn sí wọn, wọn ń rì ìran asán, wọn sì ń fọ àfọ̀ṣẹ èké sí wọn, wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí,’ nígbà tí ó ṣépè Olúwa kò sọ̀rọ̀. 29Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí lo ìwà ìninilára, wọn sì já olè, wọn sì ni àwọn tálákà àti aláìní lára; nítòótọ́, wọn tí ní àlejò lára láìnídìí. Kò sì ṣí ìdájọ́ òdodo.

30“Èmi si wá ẹnìkan láàrín wọn, tí ìbá tún odi náà mọ́, tí ìbá dúró ní ibi tí ó ya náà níwájú mi fún ilẹ̀ náà, kí èmi má bá à parun: ṣùgbọ́n èmi kò rí ẹnìkan. 31Nítorí náà ni mo ṣe da ìbínú mi sí wọn lórí, mo ti fi iná ìbínú mi run wọn, mo si ti fi ọ̀nà wọn gbẹ̀san lórí ara wọn, ní Olúwa Olódùmarè wí.”