以西结书 21 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

以西结书 21:1-32

耶和华审判的刀

1耶和华对我说: 2“人子啊,你要面向耶路撒冷,说预言斥责以色列和圣所, 3告诉以色列,耶和华这样说,‘我要与你为敌,我要拔刀将你那里的义人和恶人一同消灭, 4从南到北不留一人, 5使世人都知道我耶和华已拔刀出鞘,不再收回。’ 6人子啊,你要在他们面前哀叹,要伤心欲绝地哀叹。 7如果有人问你为什么哀叹,你就说有噩耗传来,听见的人都胆战心惊、两手发软、精神萎靡、膝弱如水。灾难必很快发生。这是主耶和华说的。”

8耶和华对我说: 9“人子啊,你要说预言,告诉他们,耶和华这样说,

“‘有一把刀,

有一把刀磨快擦亮了,

10磨得锋利,为要杀戮,

擦得亮如闪电。

我们岂能因我儿的权杖而快乐?这刀鄙视一切权杖。 11这刀已交给人去擦亮,好握在手中,这刀已磨快擦亮,预备交给屠杀的人。 12人子啊,号啕大哭吧,因为这刀要攻击我的子民和所有以色列的首领,他们都要死于刀下。所以你要捶胸顿足。 13这刀必试验他们,这刀所鄙视的权杖若不复存在,怎么办呢?这是主耶和华说的。’

14“人子啊,你要拍掌对他们说预言,你要拿刀挥舞两三次,预示这刀要从四面八方大肆杀戮, 15使他们吓得肝胆俱裂,许多人倒在家门口。我已赐下这亮如闪电的刀,用来杀戮。 16刀啊,你要左砍右劈,大肆杀戮。 17我要拍掌,我的烈怒要平息。这是我耶和华说的。”

18耶和华对我说: 19“人子啊,你要为巴比伦王的刀画出两条进攻之路,两条路要从一个地方出发,要在通往城邑的路口设路标。 20一条路通往亚扪拉巴城,一条路通往犹大的坚城耶路撒冷21巴比伦王将站在两路的岔口,摇签求问他的神像,察看祭牲的肝。 22他右手拿到的是攻打耶路撒冷的签,于是,他用撞城锤来攻耶路撒冷的城门,厮杀吶喊,建垒筑台围攻城池。 23犹大人必认为这是虚假的征兆。他们曾向巴比伦王发誓效忠,但巴比伦王要使他们想起自己的罪,并掳走他们。

24“主耶和华说,‘因为你们的过犯昭然若揭,你们的罪恶表露无遗,因此,你们必遭掳掠。 25你这邪恶败坏的以色列首领啊!你的结局到了,审判你的日子来了。’ 26主耶和华说,‘取下你的头巾,摘下你的冠冕吧,时局转变了。要提拔卑微的,贬抑高贵的。 27毁灭,毁灭,我要毁灭这国,使它荡然无存,直到那应得的人来到后,这国才能得到重建,我要把这国交给他。’

28“人子啊,你要说有关亚扪人及其耻辱的预言,告诉他们,主耶和华说,‘有刀,有刀已出鞘,为要杀戮;它亮如闪电,要行毁灭。 29有关你们的异象和占卜是虚假的,你们将与其他恶人一同被杀,因为你们的结局到了,审判你们的日子来了。 30你们要收刀入鞘,我要在你们的家乡,在你们的出生之地审判你们, 31我要把烈怒倒在你们身上,将我的怒火喷在你们身上,把你们交在嗜杀成性的恶徒手中, 32你们必被当作柴焚烧,你们的血必流在自己的土地上,无人再记得你们。因为这是我耶和华说的。’”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 21:1-32

Babeli idà Ọlọ́run fún ìdájọ́

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mi wá: 2“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí ìhà Jerusalẹmu, kí o sì wàásù lòdì sí ibi mímọ́. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ilẹ̀ Israẹli. 3Kí ó sì sọ fún un pe: ‘Èyí yìí ni Olúwa wí: Èmi lòdì sí ọ. Èmi yóò fa idà mi yọ kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀, Èmi yóò sì ké olódodo àti ènìyàn búburú kúrò ni àárín yín. 4Nítorí pé, èmi yóò ké olódodo àti olùṣe búburú kúrò, idà mi yóò jáde láti inú àkọ̀ rẹ̀ lòdì sí gbogbo ènìyàn láti gúúsù títí dé àríwá. 5Nígbà náà gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti yọ idà mi kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀; kì yóò sì padà sínú rẹ̀ mọ́.’

6“Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mí ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn. 7Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mí ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni Olúwa Olódùmarè wí.”

8Ọ̀rọ̀ Olúwa si tún tọ̀ mí wá pé: 9“Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ wí pé, Èyí yìí ní Olúwa wí pé:

“ ‘Idà kan, Idà kan,

tí a pọ́n, tí a sì dán pẹ̀lú,

10a pọ́n láti pa ènìyàn púpọ̀,

a dán an láti máa kọ mọ̀nà!

“ ‘Àwa o ha máa ṣe àríyá ọ̀gọ ọmọ mi? Idà gán gbogbo irú igi bẹ́ẹ̀.

11“ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n,

kí ó lè ṣe é gbámú;

a pọ́n ọn, a sì dán an,

ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani.

12Sọkún síta, kí ó sì pohùnréré ẹ̀kún, ọmọ ènìyàn,

nítorí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi;

yóò wá sórí gbogbo ọmọ-aládé Israẹli

ìbẹ̀rù ńlá yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi

nítorí idà náà;

nítorí náà lu oókan àyà rẹ.

13“ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Juda èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ̀síwájú mọ́ ńkọ́? Ni Olúwa Olódùmarè wí.’

14“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn,

sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́

Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì,

kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹta.

Ó jẹ́ idà fún ìpànìyàn

idà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀

Tí yóò sé wọn mọ́ níhìn-ín àti lọ́hùnnún.

15Kí ọkàn kí ó lè yọ́

kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀,

mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparun

Háà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná,

a gbá a mú fún ìparun.

16Ìwọ idà, jà sí ọ̀tún

kí o sì jà sí òsì

lọ ibikíbi tí ẹnu rẹ bá dojúkọ

17Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́

ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀

Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀.”

18Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mi wá: 19“Ọmọ ènìyàn la ọ̀nà méjì fún idà ọba Babeli láti gbà, kí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú kan náà. Ṣe ààmì sí ìkóríta ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú náà. 20La ọ̀nà kan fún idà láti wá kọlu Rabba ti àwọn ará Ammoni kí òmíràn kọlu Juda, kí ó sì kọlu Jerusalẹmu ìlú olódi. 21Nítorí ọba Babeli yóò dúró ni ìyànà ní ojú ọ̀nà, ní ìkóríta, láti máa lo àfọ̀ṣẹ: Yóò fi ọfà di ìbò, yóò béèrè lọ́wọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, òun yóò ṣe àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀. 22Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jerusalẹmu yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu-ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́. 23Àfọ̀ṣẹ náà yóò dàbí ààmì èké sí àwọn tí ó ti búra ìtẹríba fún un, ṣùgbọ́n òun yóò ran wọn létí ẹbí wọn yóò sì mú wọn lọ sí ìgbèkùn.

24“Nítorí náà èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí ti ẹ̀yin ti mú ẹ̀bi yín wá sí ìrántí nípa ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba, ní ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí, a yóò mú yín ní ìgbèkùn.

25“ ‘Ìwọ aláìmọ́ àti ẹni búburú ọmọ-aládé Israẹli, ẹni ti ọjọ́ rẹ̀ ti dé, ẹni tí àsìkò ìjìyà rẹ̀ ti dé góńgó, 26Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀: Ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀, 27Ìparun! Ìparun! Èmi yóò ṣé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò ṣe pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fi fún.’

2821.28-32: El 25.1-7; Jr 49.1-6; Am 1.13-15; Sf 2.8-11.“Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nípa àwọn ará Ammoni àti àbùkù wọn:

“ ‘Idà kan idà kan

tí á fa yọ fún ìpànìyàn

tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò

àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná!

29Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí èké nípa yín

àti àfọ̀ṣẹ èké nípa yín

a yóò gbé e lé àwọn ọrùn

ènìyàn búburú ti a ó pa,

àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé,

àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó.

30“ ‘Dá idà padà sínú àkọ̀ rẹ̀

Níbi tí a gbé ṣẹ̀dá yín,

ní ibi tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ wá.

31Níbẹ̀ ni èmi yóò ti ṣe ìdájọ́ yín,

èmi o sì fi èémí ìbínú gbígbóná

mi bá yín jà.

32Ẹ̀yin yóò jẹ́ èpò fún iná náà,

a yóò ta ẹ̀jẹ̀ yin sórí ilẹ̀ yín,

a kì yóò rántí yín mọ́;

nítorí èmi Olúwa ní ó ti wí bẹ́ẹ̀.’ ”