以西结书 10 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

以西结书 10:1-22

耶和华的荣耀离开圣殿

1我观看,只见基路伯天使头顶上的穹苍之中好像有一个蓝宝石宝座。 2耶和华对那穿细麻衣的人说:“你到基路伯天使下边旋转的轮子中间,双手拿满火炭,撒在城上。”我见他进去了。

3当他进去的时候,基路伯天使站在殿的南边,内院充满了云彩。 4耶和华的荣耀从基路伯天使的上面升起,停在殿的门口,殿里充满了云彩,院子也充满了耶和华荣耀的光辉。 5基路伯天使展翅的响声好像全能上帝说话的声音,在外院也可以听见。

6祂对那穿细麻衣的人说:“你要从基路伯天使下面旋转的轮子中取火。”那人便进去,站在一个轮子旁边。 7有一个基路伯天使伸手到他们中间的火里,取了些火放在那人手里,那人就拿了出去。 8基路伯天使的翅膀下仿佛有人的手。

9我又看见四个基路伯天使旁各有一个闪耀如绿宝石的轮子。 10四个轮子结构一样,好像轮套轮。 11基路伯天使移动时,不必转身就可以向四方移动。前轮朝哪个方向移动,其他的轮子也朝哪个方向移动,不必转向。 12这四个基路伯天使的全身,包括他们的手、背、翅膀和轮子都布满了眼睛。 13我听见他们称这些轮子为“旋转轮”。 14每一个基路伯天使都有四张脸:第一张是基路伯天使的脸,第二张是人的脸,第三张是狮子的脸,第四张是鹰的脸。

15然后,这些基路伯天使都向上升去,他们就是我在迦巴鲁河边所见的活物。 16基路伯天使移动,轮子也随之移动;基路伯天使展翅飞离地面,轮子也随之离开地面; 17基路伯天使停住,轮子也随之停住;基路伯天使上升,轮子也随之上升。因为活物的灵在轮子中。

18那时,耶和华的荣耀离开了殿的门口,停在基路伯天使上面。 19我看见基路伯天使展翅飞离地面,轮子也随之飞离。他们停在耶和华殿的东门,以色列上帝的荣耀在他们上面。 20这些是我在迦巴鲁河边所看见的活物,他们在以色列上帝的下面。我知道他们是基路伯天使。 21他们各有四张脸,两对翅膀,翅膀下仿佛有人的手, 22他们的面貌和我在迦巴鲁河边所见的一样,每一个都向前直走。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 10:1-22

Ògo kúrò nínú tẹmpili

110.1: If 4.2.Mo sì wò ó, mo rí ohun kan tó dàbí òkúta safire nínú òfúrufú tó wà lókè orí kérúbù, ìrísí ohun yìí sì dàbí ìtẹ́. 210.2: If 8.5.Olúwa sì sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun pé, “Lọ sí àárín àwọn kẹ̀kẹ́ tó wà lábẹ́ kérúbù. Bu ẹyin iná tó kúnwọ́ rẹ láàrín kérúbù, kí o sì fọ́n sórí ìlú náà.” Ó sì lọ lójú mi.

3Àwọn kérúbù dúró sí apá gúúsù tẹmpili nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ìkùùkuu sì bo inú àgbàlá. 4Ògo Olúwa sì kúrò lórí àwọn kérúbù, ó bọ́ sí ibi ìloro tẹmpili. Ìkùùkuu sì bo inú tẹmpili, àgbàlá sì kún fún ìmọ́lẹ̀ àti ògo Olúwa. 5A sì gbọ́ ariwo ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí títí dé àgbàlá tó wà ní ìta gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run Olódùmarè (Eli-Ṣaddai) bá ń sọ̀rọ̀.

6Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún ọkùnrin aláṣọ funfun yìí pé, “Mú iná láàrín àwọn kẹ̀kẹ́, láàrín àwọn kérúbù,” ó sì lọ dúró ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ náà. 7Ọ̀kan nínú àwọn kérúbù sì nawọ́ sí ibi iná tó wà láàrín kérúbù yòókù. Ó mú lára rẹ, ó fi sínú ọwọ́ ọkùnrin aláṣọ funfun, òun náà gbà á, ó sì jáde lọ. 8(Ohun tó dàbí ọwọ́ ènìyàn wà lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí.)

9Nígbà tí mo sì wò, kíyèsí i, àwọn kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù yìí, kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kọ̀ọ̀kan; ìrí àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń tàn yanran bí àwọ̀ òkúta berili. 10Ní ti ìrísí wọn, gbogbo wọn jọra wọn; ọ̀kọ̀ọ̀kan rí bí ìgbà tí kẹ̀kẹ́ kan wà nínú kẹ̀kẹ́ mìíràn. 11Nígbà tí wọ́n ń lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀kan nínú ọ̀nà mẹ́rin tí àwọn kérúbù dojúkọ; àwọn kẹ̀kẹ́ náà kò yípadà bí àwọn kérúbù ti ń lọ. Àwọn kérúbù ń lọ sí ibi tí orí dojúkọ láì yà. 1210.12: El 1.18; If 4.8.Gbogbo ara wọn àti ẹ̀yìn, ọwọ́ wọn àti ìyẹ́ wọn, àti àwọn kẹ̀kẹ́ kún fún ojú yíkákiri kẹ̀kẹ́, tí àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní. 13Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ni “kẹ̀kẹ́ àjà.” 1410.14: El 1.10; If 4.7.Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kérúbù yìí ni ojú mẹ́rin: ojú èkínní jẹ́ ojú kérúbù, ojú kejì jẹ́ ti ènìyàn, ojú kẹta jẹ́ ti kìnnìún nígbà tí ojú kẹrin jẹ́ ti ẹyẹ idì.

15A gbé àwọn kérúbù sókè. Èyí ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí létí odò Kebari. 16Bí àwọn kérúbù yìí bá ń lọ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹgbẹ́ wọn náà yóò lọ; bẹ́ẹ̀ ni bí àwọn kérúbù bá tú ìyẹ́ wọn ká láti dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí kò ní kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. 17Bí àwọn kérúbù bá dúró díẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́; bí àwọn kérúbù bá dìde àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dìde, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú wọn.

18Ògo Olúwa kúrò níbi ìloro tẹmpili, ó sì dúró sórí àwọn kérúbù. 19Àwọn kérúbù gbé ìyẹ́ wọn sókè, wọ́n sì fò kúrò nílẹ̀ lójú mi, wọ́n sì lọ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n dúró níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ilé Olúwa, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lórí wọn.

20Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọ́run Israẹli létí odò Kebari, mo sì mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n. 21Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ mẹ́rin, lábẹ́ ìyẹ́ wọn ni ohun tó jọ ọwọ́ ènìyàn wà. 22Àfiwé ojú àti ìrísí wọn rí bákan náà pẹ̀lú àwọn tí mo rí létí odò Kebari. Olúkúlùkù wọn sì ń lọ sí ọ̀kánkán tààrà.